Ẹ̀bà àti ẹ̀fọ́ rírò
Type | Dish |
---|---|
Place of origin | Yorubaland (Western Nigeria) |
Region or state | Nigeria |
Main ingredients | stockfish, Scotch bonnets (atarado), tatashe (red bell pepper), onions crayfish, water, palm oil, red onion, leaf vegetables, other vegetables, seasonings, meat |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
Ẹ̀bà àti ẹ̀fọ́ rírò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ tí àwọn ọmọ Yorùbá máa ń ṣe.[1][2] Oúnjẹ méjì ló sodo sínú èyí, ìyẹn ẹ̀bá àti ọbẹ̀ ẹ̀fọ́.
Èbà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé láti ara ẹ̀gẹ́ tàbí Gbágùúdáni a ti máa ń rí gààrí.[3][4][5] Yíyan sì ni a máa ń yan gààrí. Àwọn mìíràn a máa mú gààrì, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mìíràn máa ń fi gààrì tẹ̀bà. Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé oúnjẹ afáralókun ni ẹ̀bà jẹ́. Tí a bá fẹ́ tẹ ẹ̀bà, àwọn ìgbésẹ̀ tí a máa tẹ̀lé nìwọ̀nyí :
Ìgbésẹ̀ láti fi tẹ ẹ̀bà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]ÌGBÉSẸ̀ ÀKỌ́KỌ́ :Á ò gbé omi kaná
ÌGBÉSẸ̀ KEJÌ: Tí omi náà bá ti hó, á ò da gààrí sínú rẹ̀, á ò sì fi orógùn rò ó papọ̀ lórí iná díẹ̀ kí á tó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kí ó ba à lè jinná dáadáa.
ÀKÍYÈSÍ :Àwọn mìíràn kì í pè é ní “ro ẹ̀bà”, ohun tí wọ́n máa ń pè é ni “tẹ ẹ̀bà “.
ÌGBÉSẸ̀ KẸ̀TA :A kò le fi sílẹ̀ nínú ìkòkò tí a ti tẹ̀ ẹ́. Láyé àtijọ́, inú ewé ni àwọn baba ńlá wa máa ń kọ oúnjẹ sí ṣùgbọ́n láyé òde òní nǹkan ti yípadà. Aṣọ ìgbà là ń dá fún ìgbà, bẹ́ẹ̀ sì ni bí ìgbà ti ń yí ló yẹ kí á máa bá ìgbà yí. A lè kọ ọ́ sínú ọ̀rá tàbí kí á kọ ọ́ sínú abọ́ onídèérí.[6][7]
Ẹfọ́ rírò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé orísìírísìí ẹ̀fọ́ ló wà. Lára wọn ni ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, ẹ̀fọ́ gbàgbá, ẹ̀fọ́ òdú, ẹ̀fọ́ gúre,ẹ̀fọ́ sọkọ, ẹ̀fọ́ wọ̀rọ̀wọ́, ẹ̀fọ́ amúnútutù abbl.[8] [9][10][11] Tí ó bá jẹ́ ẹ̀fọ́ ẹlẹ́mìí méje ni a fẹ́ sè, àwọn èròjà tàbí ohun èlò tí ó máa wà nínú ẹ̀fọ́ náà nìyí :ata rodo, ata tìmátì, àlùbọ́sà, irú woro, magí, epo, iyọ̀, ẹja, ẹran, ìgbín, pọ̀nmọ́, edé abbl. Tí a bá wo àwọn ohun èlò tí mo kà sókè wọ̀nyí, á ò ri pé ìsọ̀rí méjì ni a lè pín in sí, àwọn náà ni:Ìsọ̀rí àwọn oúnjẹ sẹ̀míró àti ìsọ̀rí àwọn oúnjẹ ọlọ́ràá.
Àwọn oúnjẹ tí ó wà ní abẹ́ ìsọ̀rí sẹ̀míró ni :ata rodo, ata tìmátì, àlùbọ́sà àti ẹ̀fọ́
Àwọn oúnjẹ tí ó wà ní abẹ́ ìsọ̀rí ọlọ́ràá ni :ẹja, pọ̀nmó, ẹran, ìgbín, edé. Àwọn ìgbésẹ̀ tí a máa tẹ̀lé nìwọ̀nyí bí a bá fẹ́ ṣe ẹ̀fọ́ rírò:
ÀKÍYÈSÍ :Kò sí ẹ̀fọ́ tí a kò le lò, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí á sàmúlò ẹ̀fọ́ gbàgbá níbí.
Ìgbésẹ̀ láti fi ṣe ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ rírò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]ÌGBÉSẸ̀ ÀKỌ́KỌ́ :Á ò gbé omi kaná
ÌGBÉSẸ̀ KEJÌ :Á ò da ẹ̀fọ́ náà sínú omi tí ó bá ti hó láti bọ̀ ọ́ láti lè jẹ́ kí ẹ̀fọ́ náà rọ̀.
ÀKÍYÈSÍ :Àwọn mìíràn máa ń fi bàìkábọ́néètì(tí ó rọ́pò kánún) bọ ẹ̀fọ́ láti lè jẹ́ kí ẹ̀fọ́ náà bọ̀ dáadáa, kí àwọ̀ aláwọ̀ ewé rẹ̀ sì lè jáde dáadáa. Ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ̀nsì sì ti jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé kò dára láti máa fi bàìkábọ́néètì bọ ẹ̀fọ́ nítorí gbogbo ohun tó ń ṣe ara lóóore lára ẹ̀fọ́ náà ni yóò ti fọ dànù. Dípò tí a fi máa ma lo bàìkábọ́néètì, kí a máa lo iyọ̀.
ÌGBÉSẸ̀ KẸ̀TA :Tí ẹ̀fọ́ yìí bá ti rọ̀, á ò fi alásẹ́ wà á sínú omi tútù.
ÌGBÉSẸ̀ KẸ̀RIN :Á ò gbé omi kaná.
ÀKÍYÈSÍ :Ata yóò ti wà ní lílọ̀ sílẹ̀.
ÌGBÉSẸ̀ KÀRÚN:Bí epo bá ti gbóná dáadáa tàbí gbá, á ò da ata síi, á ò fi irú, magí, ìyọ̀, ìgbín, ẹran, ẹja, edé àti pọ̀ mọ́ si.
ÌGBÉSẸ̀ KẸFÀ :Tí ata náà bá ti jinná, á ò da ẹ̀fọ́ si. Á ò sì fi í lára balẹ̀ fún ìṣẹ́jú díẹ̀ kí ẹ̀fọ́ náà fi jinná mọ́ ata. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, a máa sọ̀ ọ́ kalẹ̀. Ó ti di jíjẹ nìyẹn.
Àwọn ìgbésẹ̀ tí a tò sókè yìí ni a máa tẹ̀lé bí a bá fẹ́ ṣe ẹ̀fọ́ rírò ẹlẹ́mìí méje pẹ̀lú ẹ̀bà. Àpapọ̀ ìsọ̀rí oúnjẹ mẹ́tẹ́ẹ̀ta ni a lè rí nínú oúnjẹ yìí. Àwọn ìsọ̀rí mẹ́tẹ́ẹ̀ta náà ni: Oúnjẹ afáralókun, oúnjẹ sẹ̀míró àti oúnjẹ ọlọ́ràá.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "A Quick Guide to Fufu, Africa's Staple Food". OkayAfrica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-11-28. Retrieved 2022-05-03.
- ↑ "Tomi's Kitchen". Bolt Food (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-23.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "What is Eba | How to Prepare Garri". allnigerianfoods.com. 29 December 2016. Retrieved 2018-11-14.
- ↑ "Nigerian Eba". Serious Eats (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-23.
- ↑ Amaechi, Din (2022-03-17). "What Does Eba Mean In Nigeria?" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-23.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Ayambem, Eya (2019-03-29). "How to make eba without lumps". Wives Connection (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-23.
- ↑ "Nigerian Eba (How To Make Eba)". My Active Kitchen (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-10-31. Retrieved 2022-05-23.
- ↑ "The many benefits of celosia argentea, celosia trigyna". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-21. Retrieved 2022-12-21.
- ↑ Peter, Kavita; Gandhi, Puneet (2017-09-01). "Rediscovering the therapeutic potential of Amaranthus species: A review" (in en). Egyptian Journal of Basic and Applied Sciences 4 (3): 196–205. doi:10.1016/j.ejbas.2017.05.001. ISSN 2314-808X. https://www.sciencedirect.com/science/article/pii/S2314808X17302166.
- ↑ Iswat Badiru; Deji Badiru (19 February 2013). Isi Cookbook:Collection of Easy Nigerian Recipes. iUniverse, 2013. ISBN 9781475976717. https://books.google.com/books?id=pDj5SB3KF8UC&dq=Efo+riro&pg=PA35. Retrieved July 7, 2015.
- ↑ The Recipes of Africa. Dyfed Lloyd Evans. p. 112. https://books.google.com/books?id=FJxlWwrVcKcC&dq=Efo+riro&pg=PA112. Retrieved July 7, 2015.