Ẹ̀sìn àgbọn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Papoda ẹ̀sìn àgbọn tí ó léfó sí ojú omi, wọ́n ya àwòrán yìí ní ọdún 1969

Ẹ̀sìn àgbọn (Tinh Do Cu Si)[1] jẹ́ ẹ̀sìn tí wọ́n ti fòpin sí, tí ó sì jẹ́ ẹ̀sìn kan tí wọ́n ń sìn ní "Ilú àgbọn" ti Gúúsù Vietman níbi tí wọ́n ti dáa sílẹ̀ ní ọdún 1963. Ẹ̀sìn yìí dá lórí ẹ̀sìn Búdà àti ẹ̀sìn ìgbàgbọ́, pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ nípa olùdásílẹ̀ Nguyễn Thành Nam, tí ó jẹ́ onímọ̀ ará Vietman. Àwọn aláṣẹ Vietman fi opin sí ẹ̀sìn yìí ní  ọdún 1975. Kí wọ́n tó fi òpin síi, ó ní àwọn ọmọlẹ́yìn bí ẹgbẹ̀rú mẹ́rin.

Àsà wọn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀sìn àgbọn maa ń jẹ àgbọn pẹ̀lú omi inú ẹ̀ nìkán.[2] Wọ́n gba àwọn alàgbà wọn láyè láti fẹ́ ìyàwó mẹ́sàn.[3]

Ìtàn nípa rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìgbésí ayé àwọn alàgbà ẹ̀sin àgbọn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nguyễn Thành Nam, tí ó jẹ́ onímọ̀ ará Vitman dá ẹ̀sìn àgbọn yìí sílẹ̀ ní ọdún 1963[2]  tí wọ́n tún mọ̀ sí alàgbọn,[4][5] Ìmọ̀ Àgbọn rẹ,[6] Wòlí Ìṣọ̀kan,[6] àti Arákùnrin Hai[6] (1909 – 1990[1]). Nam, tí ó lọ sí Yunifásítì Faransé,[2] paoda tí ó léfó sí ojú omi sílẹ̀[6] ní "Ilú àgbọn" ti Gúúsù Vietman , ní agbèègbè Bến Tre.[2] Wọ́n sọ wípé àgbọn ni Nam jẹ fún odindin ọdún mẹ́ta;[1] ní àwọn àkókò yìí ó tún maa ń dá sọrọ̀ ní orí òkúta kékeré.[3] Nam díje fún ipò Àrẹ Gúúsù nínú ètò ìdìbò ti ọdún 1971.[2] Pẹ̀lú àwọn ìhùwàsí ẹ̀ tí kò fi taratara bójú mu, ijọba maa ń fún ní ọ̀wọ̀, tí wọ́n sì maa ń pèé ní "ọkùnrin ẹlẹ́sìn".[7] Ó maa ń fi okùn kọ́rùn tí ó sì maa ń múra bí àwọn ẹlẹ́sìn Búdà.[8]

Iye àwọn ẹlẹ́sìn àti ìtẹ̀síwájú rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀sìn yìí tó bí ẹgbẹ̀rú mẹ́rin káàkiri àgbàyé. Gbajúmọ̀ kan tí ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn ẹ̀sìn yìí ni ọmọ akọ̀wé àkàkọ́gbọ́n ará America, John Steinbeck.[2] Wọ́n pe ẹ̀sìn yìí ní "ẹgbẹ́ òkùnkùn" tí àwọn aláṣẹ Vitname sì fi òpin síi ní ọdún 1975.[2]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 Dodd, Jan (2003).
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 "Coconut religion".
  3. 3.0 3.1 Hoskin, John; Howland, Carol (2006).
  4. Pillow, Tracy (2004).
  5. Ehrhart, William Daniel (1987).
  6. 6.0 6.1 6.2 6.3 Vu Trinh (1974).
  7. Ellithorpe, Harold (1970).
  8. "THE OTHER SIDE OF EDEN: LIFE WITH JOHN STEINBECK".