Ẹ̀tẹ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Ẹ̀tẹ̀
Ẹ̀tẹ̀Arákunrin ọmọ ọdún 24 láti Norway, tí ó ní ẹ̀tẹ̀, 1886.
Arákunrin ọmọ ọdún 24 láti Norway, tí ó ní ẹ̀tẹ̀, 1886.
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10A30. A30.
ICD/CIM-9030 030
OMIM246300
DiseasesDB8478
MedlinePlus001347

Ẹ̀tẹ̀, tí a tún mọ̀sí Àrùn Hansen (HD), jẹ́́ bárakú àkóràn ti kòkòrò àrùn Mycobacterium leprae[1] àti Mycobacterium lepromatosis.[2] Lákọkọ́, àwọn àkóràn kòní àwọn aamì wọ́n sì wà báyì fún ọdún 5 lọsí 20 ọdún.[1] Àwọn aamì tí o ń farahàn ni granuloma ti àwọn isan imọ̀ibi atẹ́gùn ìmí ńgbà, àwọ̀ ara, àti àwọn ojú.[1] Èyí lè fa ìrora àti ìpàdánù àwọn ẹ̀yà ìkángun nítorí ìfarapa léraléra.[3] Àìlera àti àìríran dáradára lè wáyé.[3]

Orísi àwọn arùn dálé iye irúfẹ́ kòkòrò tí ó wà níbẹ̀: paucibacillary àti multibacillary.[3] Àwọn irúfẹ́ méjì yíì yàtọ̀ nípa iye àwọn ohun ayí àwọ̀ padà tí kò dára, àwọn bálabála àwọn ara, pẹ̀lú tí o ní márùn tàbí díẹ̀ àti multibacillary tí o ní ju márùn.[3] A sàwarí ìwádìí àìsàn yíì nípa wíwá acid-fast bacilli ní àyẹ̀wò ìsú-ara ti awọ̀ ara tàbí nípa ṣísàwarí DNA nípa polymerase àbájáde ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀létẹ̀lé.[3] Ó sábà maa ń ṣsẹlẹ̀ láàrin àwọn tí o ń gbé nínu òsì a sì gbàgbọ́ pé o maa ń ràn nípa àwọn mímí tí o ń wáyé.[3] O ní àrànmọ́ tí ó ga.[3]

A maa ń wo ẹ̀tẹ̀ sàn nípa ìtọjú.[1] Ìtọjú fún ẹ̀tẹ̀ paucibacillary ní àwọn egbògi dapsone àti rifampicin fún osù 6.[3] Ìtọjú fún ẹ̀tẹ̀ multibacillary ni rifampicindapsone, àti clofazimine fún osù méjìlá.[3] Àwọn ìtọjú yíì jẹ́ ọ̀fẹ́ láti ọwọ́ Àjọ Ìlera Àgbayé.[1] Ọ̀pọ̀ egbògi aṣòdìsí ni a tún lè lò.[3] Lágbayé ní 2012, iye ìṣẹlẹ̀ lílé ti ẹ̀tẹ̀ jẹ́ 189,000 àti iye ìṣẹlẹ̀ titun jẹ́ 230,000.[1] Iye ìṣẹlẹ̀ líle ti dínkù láti 5.2 mílíọ́nù ní àwọn ọdún 1980.[1][4][5] Ọ̀pọ̀ àwọn ìsẹlẹ̀ titun wáyé ní orílẹ̀-èdè 16, tí Índíánì sí jẹ̀ bíi ìdajì.[1][3] Ní àwọn 20 ọdún sẹ́yìn, 16 mílíọ́nù àwọn ènìyàn lágbayé ni o ti rí ìwosàn lọ́wọ ẹ̀tẹ̀.[1]

Ẹ̀tẹ̀ ti ń ran àwọn ènìyàn fún àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.[3] Àrùn yí gba orúkọ rẹ láti Látínì ọ̀rọ̀ lepra, tí ó túnmọ̀ sí "scaly", nígbà tí ọ̀rọ̀ "Àrùn Hansen" wá láti orúkọ oníṣègùn Gerhard Armauer Hansen.[3] Yíya àwọn èniyàn sọ́tọ̀ ní awọn ìletò adẹ́tẹ̀ ṣsì ń wáyé ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Índíánì, pẹ̀lú iye ju ẹgbẹ̀gbẹ̀rún lọ;[6] Ṣáínà, pẹ̀lú iye ní ọgọgọ́rùn;[7] àti ní Áfíríkà.[8] Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ìletò kòsí mọ́.[8] Ẹ̀tẹ̀ ni ó rọ̀mọ́ àbùkù ìbálópọ̀ fún ọ̀pọ̀ ìtàn,[1] tí ó jẹ́ ìdènà fún ìfi-ara-ẹni sùn àti ìtọjú lọ́gán. Ọjọ́ Ẹ̀tẹ̀ Àgbayé bẹ̀rẹ̀ ní 1954 láti mú mímọ̀ nípa wá fún àwọn tí o ní ẹ̀tẹ̀.[9]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 1.7 1.8 1.9 "Leprosy Fact sheet N°101". World Health Organization. Jan 2014. 
  2. ScienceDaily .  Unknown parameter | title= ignored (help); Unknown parameter | accessdate= ignored (help); Unknown parameter | date= ignored (help); Unknown parameter | url= ignored (help); Missing or empty |title= (help);
  3. 3.00 3.01 3.02 3.03 3.04 3.05 3.06 3.07 3.08 3.09 3.10 3.11 3.12 . 
  4. . 
  5. . 
  6. "The hidden suffering of India's lepers ". BBC News . 2007-03-31. 
  7. Lyn TE  (2006-09-13 ). "Ignorance breeds leper colonies in China ". Independat News & Media . http://www.iol.co.za/index.php?set_id=1&click_id=117&art_id=qw1158139440409B243. Retrieved 2010-01-31. 
  8. 8.0 8.1 Byrne, Joseph P. (2008). Encyclopedia of pestilence, pandemics, and plagues. Westport, Conn.[u.a.]: Greenwood Press. p. 351. ISBN 9780313341021. http://books.google.ca/books?id=5Pvi-ksuKFIC&pg=PA351. 
  9. McMenamin, Dorothy (2011). Leprosy and stigma in the South Pacific : a region-by-region history with first person accounts. Jefferson, N.C.: McFarland. p. 17. ISBN 9780786463237. http://books.google.ca/books?id=lZPvQTJ8SE0C&pg=PA17.