Ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn ní Somaliland

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Òfin tí ó ń dáàbò bo Ẹ̀tọ́ àwọn ènìyànSomaliland wà ní orí kínní, ẹsẹ kẹta ìwé òfin wọn Somaliland. Somaliland jẹ́ ìpínlẹ̀ Olómìnira ní Ìho Áfríkà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjọ àgbáyé[1][2] kà wọ́n gẹ́gẹ́ bi ara orílẹ̀ èdè Somalia.

Amnesty International tí sọ lòdì lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà sí dídá ọjọ́ ikú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ti àwọn ènìyàn mọ́ ẹ̀wọ̀n tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní Somaliland.[3]

Ní Oṣù Kínní ọdún 2007, ìjọba kó àwọn akọ̀wé àti oníròyìn ìwé ìròyìn Haatuf kan nítorí pé wọ́n "ba orúkọ ìdílé ààrẹ jẹ́" nítorí pé wọn kọ nípa ìwà jẹ gúdú jerá wọn nínú ìròyìn. Lẹ́yìn ìgbà tí ọ̀pọ̀lopọ̀ àwọn ọmọ ìlú dá sí ọ̀rọ̀ náà, ìjọba Somaliland fi àwọn oníròyìn náà kalẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà lé lọ́gọ́rin ní ẹ̀wọ̀n. [4]

Ní ọdún 2009, Freedom House ṣe àbájáde àwọn àwọn ǹkan àìtó tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní Somaliland: ìwà jẹ gúdú jerá, ìwà àìtó sí àwọn oníròyìn, fifi òfin de ìwàásù tí ki ń ṣe nípa Islam, àti fífi òfin de ìwóde.[5]

Òfin[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó ṣe lòdì sí òfin Somaliland láti fowó sí sísọ Somaliland di ara Somalia,[6] tàbí láti wọ Àsìá ilẹ̀ Sòmálí,[7] Ìwé òfin Somaliland ọdún 2001, sọ wípé Somaliland tí gba òmìnira lọ́wọ́ Somalia.[8]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Issue 270". Archived from the original on 21 March 2016. Retrieved 28 March 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "The Transitional Federal Charter of the Somali Republic" (PDF). University of Pretoria. 1 February 2004. Archived from the original (PDF) on 25 March 2009. Retrieved 2 February 2010.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "2006 Annual Report – Somalia" (in German). Amnesty International. Archived from the original on 25 August 2016. Retrieved 13 August 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Somaliland journalists freed after 86 days". afrol News. Archived from the original on 29 July 2021. Retrieved 13 August 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "Freedom in the World 2010 - Somaliland". Freedom House. Archived from the original on 18 November 2011. Retrieved 13 August 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "Somaliland: Prosecutions Threaten Free Expression". Human Rights Watch. 8 May 2018. Archived from the original on 29 July 2021. Retrieved 13 August 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. "Somaliland's Horn Stars band arrested over Somali flag". BBC News. 28 September 2015. https://www.bbc.com/news/world-africa-34378350. 
  8. "Elections in Somaliland". africanelections.tripod.com. Retrieved 2020-06-20.