Jump to content

Ẹ̀yà Bishari

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Bishari
MPP-Hm1.jpg
Àpapọ̀ iye oníbùgbé
42,000
Regions with significant populations
 Sudan

,  Egypt

Èdè

Beja (Bidhaawyeet), Arabic

Ẹ̀sìn

Islam

Ẹ̀yà abínibí bíbátan

other Beja

Àwọn Bishari (Lárúbáwá: البشارية‎, tàbí البشاريين, romanized: al-Bishāriyyīn; Beja: Oobshaari) jẹ́ ẹ̀yà kan tí ó gbé ní apá Àríwá ìlà oòrùn Áfríkà. Wọ́n wà lára àwọn ènìyàn Beja. Yàtò sí èdè Arabic tí wọ́n ń sọ, àwọn ènìyàn Bishari tún ń sọ Beja language, èdè tí ó jẹ́ ara àwọn ìdílé Afroasiatic.

Àwòrán àwọn ará Bishari tí G. Lekegian, c. yà ní ọdún 1895

Ibi tí wọ́n gbé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ẹ̀yà Bishari gbé ní Asálẹ̀ NubianSudan àti apá Gúúsù Egypt. Wọ́n gbé ní Atabai (tàbí Atbai) láàrin Odò Nile àti Red Sea, àríwá Amarar àti gúúsù ibi tí àwọn ènìyàn Ababda wà, láàrin asálẹ̀ Nubian àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Nile, ibẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkúta àti àpáta.[1]

Iye àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà náà tó ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì (42,000).

Èdè abínibí awọn ẹ̀yà Bishari ni èdè Beja. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè ní ìdílé Afroasiatic.[2] Àwọn Beja tí ó tún ń gbé ní orílẹ̀ èdè Sudan ń sọ èdè Sudanese Arabic.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Starky, Janet. "Perceptions of the Ababda and Bisharin in the Atbai". University of Durham. Archived from the original on 10 March 2006. Retrieved 23 November 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. 2.0 2.1 "Bedawiyet". Ethnologue. Retrieved 22 November 2017.