Ọ̀rọ̀-Orúkọ (Èdè Yorùbá)
Ìrísí
Ọ̀rọ̀ orúko ni ọ̀rọ̀kọrọ̀ nínú gbólóhùn èdè Yorùbá tí ó jẹ́ orúkọ tàbí tí ó ń tọ́ka sí orúkọ ènìyàn, ẹranko, ìlu, nǹkan (ẹlẹ́mìí tàbí aláìlẹ́mìí, nǹkan afòyemọ̀, nǹkan aṣeékà, aláiseéka ) ọ̀rọ̀ orúkọ ni olùwà fún àbọ̀ .[1] [2]
Àwọn Àpẹẹrẹ Ọ̀rọ̀-Orúkọ afoyemo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]*Bọ́lá, Shadè, Adé wálé - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Ènìyàn *Ewúrẹ́, Ajá, - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Ẹranko *Òkúta, Tábìlì, ìwé,- Ọ̀rọ̀-Orúkọ Nǹkan Aláìlẹ́mìí *ènìyàn, ẹranko - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Nǹkan Ẹlẹ́mìí *Ìfẹ́,ìbànújẹ́ - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Afòyemọ̀ *Èkùrọ́ tábìlì - Ọ̀rọ̀-Orúkọ aṣeékà *Omi, ìrẹsì - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Àìṣeékà. [3]
Àpẹẹrẹ lílò:
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bọ́lá wọ aṣọ.
Ewúré ni mo pa.
Ìpò tí Ọ̀rọ̀-Orúkọ máa ń wà nínú gbólóhùn èdè Yorùbá
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ipò méjì pàtàkì ni ọ̀rọ̀ orúkọ lè wà lédè Yorùbá. Ó lè wà nípò olùwà tàbí nípò àbọ̀.
Ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá lè wà ní ipò olùwà. Bí àpẹẹrẹ; Bọ́lá lọ jẹun.
Ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá lè wà nípò àbọ̀. Bí àpẹẹrẹ; Ṣadé ra bàtà.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Adewole, Lawrence (2016-02-27). "February 2016 – Yoruba for Academic Purpose". Yoruba for Academic Purpose (in Èdè Latini). Archived from the original on 2019-11-28. Retrieved 2019-11-28.
- ↑ "#1 Grammar and Spell checker". What is a Noun? Examples & Exercises-Ginger Software. 2019-11-28. Retrieved 2019-11-28.
- ↑ "What is a Noun? - Grammar". EnglishClub. Retrieved 2019-11-28.
- ↑ Stevenson, Jack. "noun--function of in english grammar". Directory. Retrieved 2019-11-28.