Ọ̀rọ̀ oníṣe:Jessephu
Àkíyèsí pàtàkì
[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Mo kíi yín oníṣẹ́ Jessephu, a dúpẹ́ púpọ̀ fún akitiyan yín láti ma ṣe àfikún sí Wikipedia èdè Yorùbá. Yorùbá Wikipedia jẹ́ pẹpẹ ìmọ̀ tí a ń fi ògidì èdè Yorùbá gbé kalẹ̀ fún gbogbo mùtúmùwà kí èdè wa ó lè ma ga si jákè-jádò agbáyé. Mo ṣe àkíyèsí wípé àwọn àfikún yín pàá pàá àwọn àyọkà yín tí ẹ ti ṣẹ̀dá sí orí Wikipedia yí kò ní àwọn àmúyẹ ìsàlẹ̀ wọ̀nyí:
- Àwọn àyọkà yín kò bá ìlànà akọtọ́ èdè Yorùbá mu.
- Àwọn alábòójútó Wikipedia èdè Yorùbá kò fàyè gba lílo irinṣẹ́ Google translator.
- Kíkọ Wikipedia èdè Yorùbá kò sí fún oníṣẹ́ tí kò bá mọ èdè Yorùbá kọ sílẹ̀ dára dára.
- A kò fàyè gba lílo Wikipedia èdè Yorùbá fún ìdánra èdè wò bí ó ti wulẹ̀ kí ó mọ.
Ẹ wo àwọn àyọkà yín yii : *Yobe State University, *Ekei Essien Oku, *Chinwe Nwogo Ezeani àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ẹ bá wo àwọn àyọkà wọ̀nyí, ẹ ó ri wípé wọn kò dùn únkà rárá pàá.
Fúndí, èyí, mo ma rọ̀ yín kí ẹ lọ tún àwọn àyọkà náà ṣe kí wọ́n lè gún régé ju báyìí lọ. Mo sì rọ̀ yín kí ẹ lọ ṣe àwọn atúnṣe náà ní wéré. Bí ọjọ́ mẹ́ta bá kọjá lẹ́yìn àkíyèsí yí tí ẹ kò fèsì tàbí ṣe atúnṣe kankan sí awọn ayọkà yín ọ̀hún, ó ṣe é ṣe kí n dárúkọ wọn fún píparẹ́.
Bí ẹ bá ní ìbéèrè tabi ohun mìíràn, ẹ kàn sí mi níbí. Ẹ ṣeun púpọ̀ fún ìmúṣẹ yín.Agbalagba (ọ̀rọ̀) 20:38, 7 Oṣù Kàrún 2024 (UTC)