Ọ̀rọ̀ oníṣe:Osenibabalola0

Page contents not supported in other languages.
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ẹpẹ̀lẹ́ o, Osenibabalola0,ẹkáàbọ̀ sí Yòrùbá Wikipedia!! Adúpẹ́ fún àfikún yín. Mo lérò wípé ẹ nífẹ́ sí kí ẹ wà níbí. Ẹwo àwọn oun tí a ṣètò sí ìsàlẹ̀ yìí bóyá ó lè wúlò fun yín:

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí fi òǹtẹ̀ tẹ oun tí ẹ bá kọ sí ọ̀rọ̀ ojú ewé pẹ̀lú igun mẹ́rin (~~~~); èyí máa gbé orúkọ yín àti déètì jáde. Bí ẹ bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ [[user talk:Em-mustapha User | talk 07:52, 1 Oṣù Kọkànlá 2020 (UTC)|ẹ kàn sí mi]], +/-, mo sì máa ràn yín lọ́wọ́, ẹkáàbọ̀![ìdáhùn]

M-Mustapha ẹ ṣe gan ti ẹ kan si mi, emi o maa lepa yin ti mo ba n fẹ iranlọwọ Osenibabalola0 (ọ̀rọ̀) 10:11, 1 Oṣù Kọkànlá 2020 (UTC)[ìdáhùn]

You are invited to join the contest #decolonisetheinternet #Decolonisetheinternet Nigeria

Em-mustapha User | talk 07:52, 1 Oṣù Kọkànlá 2020 (UTC)[ìdáhùn]

Àkíyèsí àti Ìkìlọ[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ n lẹ́ Osenibabalola a dúpẹ́ fún ìfẹ́ tí ẹ ní láti mú ìdàgbà-sókè bá Iwé Ìmọ̀-Ọ̀fẹ́ èdè Yorùbá. Inú wa sì dùn fún akitiyan yín láti jẹ́ kí ó dàgbà-sókè síwájú si. Àmọ́, a ní láti jẹ́bkí ẹ mọ̀ ohun tí Ìwé Ìmọ̀-Ọ̀fẹ́ yí fẹ́ yàtòọ̀ sí ohin tí kò fè rárá. A ṣàkíyèsí wípé àwọn àyọkà tí ẹ ti dá sí orí ìkànì Yorùbá Wikipedia láti ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan kó bójú mu, bẹ́ẹ̀ ni wọn tako ìlàn àlàkalẹ̀ àti òfin tí a fi gbé Wikipedia Yorùbá kalẹ̀. Ìdí ni wípé àwọn àyọkà tí ẹ ti ṣẹ̀dá wọn jẹ́ ògbufọ̀ tààrà láti ọwọ́ irinṣẹ́ Google tí ẹ kò sì ṣe àyípadà rẹ̀ kan kan bí ó ti wulẹ̀ kí mọ. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ oníṣẹ́ yín ti ṣe jẹ́ kí á mọ́ wípé ọmọ Yorùbá niyín, àmọ́ iṣẹ́ yín kò ṣaàfihàn yín gẹ́gẹ́ bí ọmọ Yorùbá nípa ìkọsílẹ̀ yín. A fẹ́ kí ẹ mọ̀ wípé irúfẹ́ iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe yí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ogunlọ́gọ̀ ìwà ìba iṣè jẹ́ rí a ń pè ní (Vandalism) tí ó sì lè mú kí àwọn ònkàwé pàá pàá jùlọ Yorùbá Wikipedia ó má sá láti fẹ́ yẹ àwọn iṣẹ́ ribiribi tí àwọn oníṣẹ́ gidi ń ṣe sí orí ìkanì yí, látàrí wípé ohun tí wọ́n ń kà lédè abínibí wọn kò yé wọn.

Mo ń fi àsìkò yí sọ fún yín kí ẹ dáwọ́ ìdá àwọn àyọkà yín dúró, kí ẹ sì gbìyànjú láti tún àwọn èyí tí ẹ ti ṣe tẹ́lẹ̀ ṣe kí ó dùn ún wò , kí ó dùn ún kà fún awọn ònkàwé lórí Ìkanì Yorùbá Wikipedia. Mo tún ń fi àsìkò yí pe alámòójú tó àgbà @T Cells: sí àkíyèsí lórí àwọn iṣẹ́ yín gbogbo.

A kìí ṣe é mọ̀ bí ẹ bá bá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ìlànà àti ìṣọwọ́ kọ àyọkà lọ́nà tí ó peregedé, ẹ wo àyọkà yí https://yo.wikipedia.org/wiki/Mercy_Akide gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ.

Ẹ ṣeun Agbalagba (ọ̀rọ̀) 14:02, 2 Oṣù Kọkànlá 2020 (UTC)[ìdáhùn]

Ẹ́ ṣeun púpọ̀ fún ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí mi. Inú mí dùn , ayọ̀ mí kún jọjọ fún èsì ọ̀rọ̀ yín. Ó wá dá mi lójú wípé ẹ gbọ́ èdè Yorùbá, bẹẹ́ẹ̀ ni ẹ sì mọ̀ọ́ kọ pẹ̀lú. Àmọ́ kọ́kọ́rọ́ kan tí ó beyín ajá jẹ́ náà ni àìṣàmúlò àwọn àmì ohùn. Bí ẹ bá fẹ́ ma lo àwọn àmì ohùn sí orí àwọn àyọkà yín gbogbo, ẹ lè kan sí mi lórí ìlà ìpè mi kí n fọ́wọ́ rẹ̀ hàn yín. Síbẹ̀, màá ní kí ẹ dáwọ́ àwọn dídá àwọn àyọkà tuntun dúró ná fúngbà díẹ̀, kí ẹ lè ráyè ṣe àtúnṣe tó yẹ sí àwọn tí ẹ ti dá sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ìdí ni wípé ogunlọ́gọ̀ irúfẹ́ àwọn iṣẹ́ bàyí ni a ń ṣe àtúnṣe rẹ̀ láti nkan bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, látàrí àwọn tí wọn kò gbọ́ tàbí nímọ̀ nípa èdè Yorùbá tí wọ́n ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìdá àyọkà sí orí ìkanì yí kí àwa tó dé. Púpọ̀ nínú àwọn oníṣẹ́ wa gbogbo ni wọn kò sì fi bẹ́ẹ̀ ráyé àti màa ṣiṣẹ́ bí alárà mọ́, èyí jẹ́ kí àwọn iṣẹ́ náà ó wọ̀ wá lọ́rùn gidi. Alábójútó àgbà @T Cells: naa lè jẹ́rí sí ìpèníjà yí. Fúndí èyí, a kò fẹ́ kí irúfẹ́ àwọn àjàgà yí ó tún máa ṣẹ́yọ mọ́ bí a kò bá lè ṣàtúnṣe àwọn tilẹ, ìdí nìyí tí a fi tètè ma ń dá àwọn ènìyàn lọ́wọ́ kọ́ bí a bá ti kẹ́fín ìṣọwọ́ kọ̀wé wọn. Láfikún, àwọn ènìyàn ma ń sọ wípé àwọn alábójútó àwọn Wikipedia Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn wikipedia míràn tí wọ́n ti gòkè àgbà lágbàáyé ma ń kanra, wọn kò sì fàyè gba ìwà òbàyéjẹ́ lórí iṣẹ́ àkànṣe wọn, ìdí ni wípé kìí rọrùn láti tètè rí àtúnṣe sí iṣẹ́ ìbájẹ́nàwọn ènìyàn pàá pàá jùlọ nígbà tí ọ̀pọ̀ èrò bá ń ṣiṣẹ́ lásìkò kan náà. Àwọn ohun tí ó ti bàjẹ́ tẹ́lẹ̀ ni àwa ṣìí ń rán lọ́wọ́ fún àìmọye ọdún, ìdí nìyí tí ìdàgbà-sókè wa ṣe wọ́lẹ̀ díẹ̀. Àwọn tí wọ́ nímọ̀ nípa kíkọ èdè Yorùbá ni a fẹ́ , kìí ṣe irú wá ògìrì wá tí yóò dojú ayò dé.

Lẹ́ẹ̀kan si, ẹ ṣeun fún akitiyan yín gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ rere. A lérò wípé gbogbo àlàyé wa ló yé yín yéké? Agbalagba (ọ̀rọ̀) 17:10, 2 Oṣù Kọkànlá 2020 (UTC)[ìdáhùn]

Ẹ ṣeun Agbalagba, gbogbo alaye yin lo ye mi. Maa ṣi ri wipe mo ṣe amulo gbogbo imọran yin. Osenibabalola0 (ọ̀rọ̀) 22:41, 2 Oṣù Kọkànlá 2020 (UTC)[ìdáhùn]

Ìkìlọ̀[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ kú iṣẹ́ o Oníṣe:Osenibabalola0, a ń rí ọwọ́ yín lẹ́nu ijọ́mẹ́ta yí, ẹ kú iṣẹ́. A fẹ́ sọ fún yín wípé iṣẹ́ ti yàtò, a kò sì fi àyè gba Àwọn àyọkà tí kò lẹ́sẹ̀ nlẹ̀ ní orí pèpéle wa mọ́. Fúndí èyí, máa rọ̀ yín kí ẹ lọ fi àwọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ itọ́ka sí sí àwọn àyọkà tí ẹ da sílẹ̀ láìpẹ́ yí kí ó tó di wípé a dárúkọ wọn fún píparẹ́. Ẹ ṣeunAgbalagba (ọ̀rọ̀) 07:26, 9 Oṣù Keje 2021 (UTC)[ìdáhùn]

Ẹ ṣeun Agbalagba fún àkíyèsí yìí. Màá ri dájú wípé mo ṣe oun tótọ́ sí àwọn àyọkà náà. Osenibabalola0 (ọ̀rọ̀) 16:16, 11 Oṣù Keje 2021 (UTC)[ìdáhùn]