Ọba Ògbómọ̀ṣọ́
ORÍKÌ OBA ÒGBÓMÒSÓ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]LÁTI ENU ALÀGBÀ OYÈKALÈ ÀLÀDÉ
(Omo Isé Fóyámu)
Ògbómòsó òle ò gbé
Ògbómòsó òle ò gbé, eni ó bá lágbárá ni gbébe
1 Lóótó ni béèni Òdodo ni
Ògbómòsó ‘mo ajekà ká tó mùko yangan
Ògbómòsó ‘mo a jòrépo-tú-yì
Àlà e wà bí o ?
Inú ilé gbogbo kàà sì n kan an ní tíwa.
Ògúnlola lorúko sòún àkókó je
Soun kéìtán iwin lábérinjo
Àísá Òkin onígùru-gùrù kéta
Adàdá mówù moja àpà
Oba tóbá onígògòngò jagun àlùsì àpà
Eléyun ni ni oòòò
Òun loba tó kókó tèlú ògbómòsó òòòòòò
Un lókó tèlú Ògbómòsó dó
Lóòtó ni, béèni òdodo ni kì gbogbo Oba kí won ó tó mó on je
N gbà tí ò dè si eléyun nì mó o
Ògbómòsá òle ò gbé eni ó lágbára ní gbébe
Temi bá n lo sónà ibè mo monú ilée wa
Èyi loríkì ti ògbómòsó ajílété
Béè náà ni Oba ajísegírí niilé wa
E dáké Ògbómòsó òle ò gbé
Eni ó lagbara ni gbebe.
Ògbómòsó, Ogbomojúgun
Temi bá n lo sónà ibè mo monú ilé wa
Báàbá bára wa tan, a fògbó kògbó nnú lé
Àlà e wà bí ò ò ò
2. Inú ilé gbogbo kàà sí n kan ní ti waaa
kótó wá kàjàyí-Olú-Ògídí oníkànga àjí pon
Aíléwólá agidingbi lójú Ogun
Àtilé atona ni baba mi Àrèmi fi sá nka ìjà á sí
Béènáàni Aíléwólá agidingbi lójú ogun
O lájá ti n be nínú ilé méì wulè gboni,
Ènìyàn Àjàyí té e rí ò gbodò ya só o mó lásán
Béè náà ni omo aráyé nì n kóba lóro
Ìgbà ti ò dè si eléyùn nì mó o
N ló wa kan Oba Ajagunbádé
Témi bá n lo sónà ibè mo mo on mi ilé wa
Ìbísùnmí, Lákanngbò, oko aràgan
Ajagungbádé Onídugbe
Àráráriri, Gbángbóyè ìrèlè baba òkè
Kójú ó torì, kóràn ó dòrìsà
Òrìsà mo kaàbá
Bábà bá yè Ajagungbádé
Jánjanjan ní mo ón dunni
Ajírèrín Òkeke
Àdàgbàlagbà Sinyan àgbìgbò nìwòn
Ìbísùnmí ní n tósàgbònìwòn té e dékun èrín rín
Tobá segúnnugún a kowo móri eyin
Nnkan to sàjààsá té e délé ìbàdàn
Tóbá solówó erú ni, à bá ti rérú è mó pátápátá
3 Atìbàdàn wá joyè bí omo jógíoró
Okùnrin pon pon pon bí ìbon ògodo
Gbongbòn janran baba mi ìbisùnmí tó wúwo bí àte àdí
Aja-n-gba-da-gírì-jagi
Ò-jebòlò jegi ìdi rè
Sara-sara làá kina bolé
Òjò pàà pàà ti tújà
Abomo on mú sànpònná kàrà-kàrà nìgbà osàn
Ó yi éyìn osè, o pomo òsú lékún
O sìkà osumí ògódó ó kanga oní kanga
Báni bù ú wò omo òkèèbàdàn
Àlá ó ba bùú, ó ní iyán lémo
Témi bá n lo sónà ibè mo mo on nú ilé waaa
Ìgbà tí ò dè sí eléyun nì mo òòòò
N ló wá kàlàbí Òyéwùmí
Oyèwùmí Ládiméjì, Ládèjo
Afolábí omo Tinúuwin
Ajíkobi Dèjì omo iwin ìgbàlè
Dèjì omo Àsààkún eni tó bá wolodumare ní dá lólá
Òkìkí ò posù, ariwo ò ní pojó
4 òkìkí ò nó somo onílè ni n kankan
Ojo ò tòòjó, ojó ò tojò
Ojó táwon kenimoni gbórí àbíkú kale lójàajagun
Eni tó kúrú n wón n tiro
Ènìyàn tó gùn n bèrè
Àlàbí ò gùn béè ni ò kúrú
Ó dúró gbangba, óbálábòsí wijo
Níwájú òyìnbó ajélèèèè o jàree abínú eni
Orí ewúré sunwòn itú ló bí
Tàgùtàn sin àn ó bí yàgbò
Ìpàdéolá abesin gbórùlé jìgbàró
Orí baba Láléye sin àn tó bárá Ìbàdàn tan
A rí bí won tí n sojú oko Olúgbódi
Àrán inú àpóti oko Efúntádé
Àrìnjó káàkótó oko ògboyà
Méèle nìkàn sùn, méèle nìkàn dájí
Nílé làlàbí òkín lóti málàké ròòde
Témi bá n ko sónà ‘bè mo monú ilé wa
Agbe tori omo rè dáró
Àlùpò dùdù tori omo rè kosùn
Lèkélèké gbàràndá ó torí omo rè déwù aso funfun
5 Torí Àbáké lo fi ránmo láyédé
Torí Àbáké lo fi lo o kóògùn aremo
Àsoba sàrìnjó tí n gbonílù tí fi gbèwù àrán
Oyèwùmí Àlàbí n ní gbomo Ológbàó tí fí wé gèlè genga
Eléyelé ìyàwó, oko jólásún
Ará ilé Àdùnní, OLókan aya bale ajísomo Dèjì
Àlàbí oko látúndùn
Oyèwùmí Àlàbí ló fi Ládùnní rópò ara rè tó dip ó térí gbaso
Témi bá n lo sónà ibè mo mo on nú ilé waaa
Òun loládùnnúnní Àkànó Oba tí n be lógbomòsó òòòò
Oba ògbómòsó tí n be lórí oyè ní ìsinsin in
Témi bá n lo sónà ibè mo on lé wa
Ìbà baba mi Àkànó Oládùnúnní òòò
Oládùnúnní Oba tó rojó ilè tó jàreee
Bémi bá n lo sónà ibè mo monú ílé waaa
O jàre gbogbo àwon ìjòyè tí n be lórí ilè náà
Àlàa`fíà ke wà bí o
Témi bá n lo sónà bè mo molé wa
Eléyelé ìyàwó òko Lárónké òòò
Ará ilé Àbìó ò ò ò
Oyèwùmí Àlààbí
6 Oyèwùmí Àlàbí Oládùnní Ajagungbádé kan
Olá òkan ò jòkan aya
Bale ajísomo Dèjì Àlàbí Oko Túndùn
Témi bá n lo sónà bè mo monú ilé won
*Àwon lomo Ìbàrùbá niwón elégùn esè
Ìbàrùbá niwon elégùn esè Olàyankú omo ode bárán eti oya
Omo Abérisé
Omo Agbònkájù
Omo Ajijoperin
Ìbàrùbá omo olójà n lìkì
Ìbàrùbá mojà lójà
Ilé yìí, ilé àwon baba mi
Mo bá e dó kááda oníkáadé
Oníkáda won ò sì ní gbèsab àwò ò ní tánmo lórùn n lìkì
Omo pákí nimi, mé je sìgo
Omo nàmù-námú, erú ò joòrì
Omo kékeré Ìbàrìbá téerì ò gbodo jáwé apá sié lánlán
Ìbàrùbá Olákòndórò, Oláyínnkú, omo ode bare eti oya
Omo abérinsé, omo agbònkájù, omo ajíjóperin
Looto ni béèni òdodo ni
Ìbàrùbá won èé sunlé àjà
Won a ní e bámi wéké yógùn nanana ki ni róhun kólé
7 Ìbàrùbá onílè lìkì
Ìbàrùbá won è é pèkùlù
Won a ní e kálo o lé lóhunún ká lo rèé kédò erin
Ìbàrùbá Olákòndórò Oláyankú
Omo amérin wá á mòlú, omo aréfòndiyàyà
Àrá abowó òjà lálálá
Baba mi ògìdán tí fowó ìjà ralè
Óní bí elérèé ò bá réni
Tí ìjèsà ò bá tajà láwìn
A kòí molésà lásán
Òyíìrí lápó
Oládòkun èjè ti ti ti lénu esin
Tayérunwón, Tègbésòrun
Agbesin lówó Olúpaje
Aare akòta sùsùsù ofà
Sòún abiléfà n wájú Kéètán abilé ofà léyìn
Dáùsí abilé ofà láàrin
Baba wa ló soró kan bí agogo
A fìbènbé ooró kù bi òjò
Eléyun ni nú ò ò ò
Àwon Oba tó tògbómòsó o
Jógioró akandehunso, àpáti Olúmokò tí kogun lójú tòsán tòòru
8 léfá wolé, lóòsà wolè
kò jé ki elénpe bòdé mó
o gbesin lówó Olúgbaja, ààre a-ko-ta-sù sù ofà
témi bá n lo sónà bè mo monú ilé wa
Ìgbà ti ò dè sí eléyùn nì mó ò ò ò ti jógioró kú ò
Eranko orí ráre tii dún mònnàhun-mònnàhun
Témi bá n lo sónà bè mo mole wa
N ló wá kan Ik’’umóyèdé Àjàsá alátò oyè lábé
Oba lábé bánbóba bánbóba
Oba tóláya márùn-ún táwon márààrún ti an bímo oyè
Wórókòòkan Oba ni wón je
Témi bá n ló sónà ibè mo mo on nú ilé wa
Eléyun nì óòòò`
Taa lóbí, taa lóbí òòò?
Òun ni baba Àjàjí Olú ògidí òòò Olúwùsì Àjàyí
Lóòtó ni béè ni òdodo ni
Olúwùsì Àjàyí
Onísòro sègì òpónrororo, baba mi akòtòpò iyùn
Òbá jègbè ìlèkè Àjàyí ebí láàrin lòbá mó on gbé
Ailéwólá o yanjú Olá gandangbon
Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó ò ò ò
Taa lóbí, ta a lóbí ò ò ò ?
N lókàndòwú bólántà a wùwón
9 ìdòwú Bólántà a wuwòn on bólá bá dojúdé a súwon súwon
Àkèyìn sí olá kì í rò
Ìdòwú Olóde Àgbánká
Fárónbi abesi kan kúro lójú ogun
Gúdúgúdú abojú légbèé
Àlùkojú órun àpinti
Adáso mó fágírí, oko ògúnyìnmí
Agbinni mó gbinsè, oko Ajíbólá
Ògòngò gongo nírìhànló Oko òjíbù ti jájolá
Ayìndòwú nibon kò kú, a tomo jógíoro lóra o mú gbogbo e je
Ògbó dì ofà tii semú wìlìkí
O ní kòsí oya òòòò
Ogun a kólé e rá òòò
Bí ò sí olùfòn ogun a jà lérìn
Tí ò bá síi lákidófà Ìdòwú Ogun ni jòsogbo
Ó gòkè òrá, o seré nà fún gàmbàrí
Ò se rebee níjó dósogbo
Ògbèkè n gbekè, rábesè gbékèlé
Ó fàtògòrò, ó súwon lóòrógàn títí
Ó gbójúlé lé jagun níjó ogun níjó ode
Èdù òkin ti fóhnn sà
Témi bá n lo sónà bè molé wa
Ìgbà tí ò dè si eléyun nì mó ò ò ò
10 lówá kan Akíntúndé òwè ìsòlá
Tí jówólè Oòni
Akíntúndé Apébu
Apéébu wóló, atìdí yògòlò
Amúlé gbolófófó
Àwa la múlé gbelé aseni
Ilé aseni won ò jìnnà ó jà
Àbá molé olórò ni, a ò sì molé aseni
Àbá mole aseni, òràn won a tètè tán
N lèmi pogunlabí
Òwè ò jejò kínní o feran ejò se lénu
Yàkàtà yakata kò jé a rí ìdí ìsápá
Ìbíkúnlé ìbàdàn, won ò je á sodún arò ní nkankan
Ìgbì tí n gbìkúnlé
A jade tòun tòbùrù gege bi elégbára ègbè léyìn gbogbo àgbà Bàdàn.
Òháhá ilé lógundégèlé ò eruku esin lofi légún Déyemo
Awon ará Òòyì, àwon n won ò gbón
Àwon n won ò mònràn
Won ò mò pérúukú lòwò o báwí
11 Ogunlabí kójúmó tó mo lo kó gbogbo won lóóde
Òlémo gbó Àsàmú baba Àb áàsì
Ìgbà ti ò dè sí eleyun nì ìn mó òòòò`
N mí Oba márun òòòò
Lóòtó ni béè ni òdodo ni in
Temi bá n lo sónà bè mo monlé wa
Ó wa kàbàrí Olúòyó, ebìíyà
Àbàrí OlúÒyó, Oyèédòjun, Látiri abólugun-Oba
Oba táaké ké ti ò juke
Oba táa gègè tí ò jugè
Òrìsà tí ò jugè, ojú pópó ní gbé
Dúdú fílàní n lomo lákan lé fi modi
Pupa re ní sàatà, ìdùkúrùkú
Témi bá n lo sónà bè, mo monú ilé won
Ìgbà tí ò dè sí eléyun nì mó ò
Témi bá n lo sónà ibè mo mo on lé e wa a
In ló wá kàlàó, Onísòrosègi
Àlàó témi bá n lo sona
Òun ni baba Àtàndá Ògúnwèndé òòò
Àlàó táa wí yìí, òun ni baba Àtàndá Ògúnwèmdé òòò
Òun ni baba Láoyè tíí jórumogegege
12 Apásánlá abaralómú, lómú omo kélébe
Ààre asòkò senbe àbàjà
Sòún dáìsí Oláoyè ni baba ònpetu
Bàbá lelébùrú àásáká
Oláoyè abìlé gbogbo lóógunlóógun
Odán nigi àwúre
Òpè nigi ìràdà
Àgbà ti n féni láfèé lólé
Iwo nlá ni fólúwa re je
Té lésin, bàà lésin
Òkètè n ketè, a mò ón gùn jomo àgbè
Àtùké bóun àsá baba lágbéndé pinpin pin lórí esin
Òpòló tóo yírò òo se é to Oláoyè okólé baba re lóbá kan kórí
Alùfáà a pàkòi,
Oúnlé orí omo kélebe
Témi bá n lo sónà be momolée wa
Ìgbà ti ò dè si eléyun nì ìn mó o
N ló wá kàntá Olóndé omo Omídélé òòò
Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa
Bá à kègbón taní kàbúrò
Mo kókó fe e lo sílé baba itabiyi
Témi bá kó n lo sónà bè mole wa
13 òjó aburúmoku ò ò ò ò
Témi ba n lo sónà bè mo monlé wa
Kékeré àsá omo ajùújù bala
Àgbàlagbà àsá omo ajùújù bala
Kékeré làdàbà subu táwon tí n je láàrin òtá
Olóumí kékée lo ti n soko won nílé
Kekere lo ti n soko won lóki
Kékeé lòjó ti n soko won lóna ijù
Oníyòówón, Inásírù, Ibasòrun Kínyodé
Iba tíí begun wolé e rémo lo
Iba tí n bá n bò, a kòdi órun
Òfesè mejeèjì gungi òbobò
Eléyun nì ní ò ò ò
Òun ni baba ìtá Olóndé omo Omídélé ò ò ò
Òré ò sí, Olórun Oba dada
Ináwolé baba kóta
Ó ní Ifá firipò nínú igbó
Òpèlè firipò laàtàn
Òrìsà ké kè firipò lágbède agodi
Ináwolé baba kóta
14 Témi bá n lo sónà bè nmo monlé wa
Tí ún bá n lo sónà tòkun, òkun lolórí omi
Ìgbà ti ò dè si eléyun nì mó ò ò ò ò
N lówá koláyodé ò ò ò
Adékúnkèé, Adégòkè oko pàte
Oláyodé omo egúngún oko
Àrà n baba mi Àatàndá
Adégòkè omo iwin ìgàlè
Lékèélékèé eléwù akese
Ahan ran mòjàngbòn, eléwù pànpànkusà
Ògbómòsó ní wón gbé, won ó mo lòó sàyonuso, sí
Láyodé omo egúngún oko
Ò-déyìn-ìlèkùn-di-baba-àgbàlagbà
Òmìmyín-mìnyín té e rí ò le è meyín erin
Èfúùfùlèlè n won ò leè mi òkun
Won ò sì leè mi òsà
Ìse tí èfúùfùlèlè táwon n se sókè lorùn Àtàndá Òkín Olóun Oba nu ò joke ó wó
Àsá n ta, kò leè tagba raso Àwòdì wón n rà, won ò le e rewin ìgbàlè
Títí tí àwòdì òkè tée gbélé ò ile mò pé ojú eye oko a mó on ri íri-íri
Ìse ègbón, n wón n pe àbúrò
Àbúrò ìba sègbónm ojú won n pón
15 Àbúrò ìba sègbón, ojú won a pón kankan bí oju alala, orùn won a wò pèrè-pèrè bí èwù àgbàlagbà
Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó o
Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa
Ó wa kan Ajíbnólá, Adogun Eléèpo àrán
Ajíbólá Oba to kobi sóyi Témi bá n lo sónà ibè mo monú ilé wa
Ajíbólá Oba tó kobi sóyi sógun
Àlà e wà bí, gbénkan dùgbè-dùgbè
Un ní pé Olóun Oba gbàmi
Oba séríkí, in ní gbani lóhun tótóbi ní nla tóbi
Sòkòtò èfà mi ò òn balè
Adìgún ni kásá paà lówó lówó
Táa bá ti lówó lówó gbogbo e níí tóní
Àlà e wà bí ò, inú ilé gbogbo kàà si nkan nítiwa.
Agbà ti ò dè sí eléyun nì mó o
Ó wa kòkò lánipèkun
16 Témi bá n lò sónà an bè, mo mo on nú ilé wa aa
Àlàáfìà ke wà bí o ?
Òkè Olánipèkun?
Òkè kéé kèè ké, mó on jólè rè sánpónná
Kóniyangí kó mó on jélégbáa
Òkè tó lo sóòwu òbò
Eléèé tó lo sóowu ò dé
Adéowó dáké mo joke kóòwu jojololá omo Bádéjéorúko
Òkè ni ò ri powó awon èlèdà Àlà e wà bi, inú ilé gbogbo kàà si n kan nít iwa
Ìgbà ti ò dè si eléyun nì mó o
In ló wa kan Olátúnjí Eléèpo àrán
Olátúnji omo gbángbéfun
Àrágada sí bààmú lójú oko Oyèládùn
Kòlù-kòlù mó kolùmi Olátúnji ò ò ò
Eni Olátúnjí Àlàó Àlàó bá kolù yó febo jura
Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó o
N ló wá kolágidé, Olágíde Àjàgbé òkin baba Lúfójè
Témi bá n lo sónà bè mo monú ilé waaa
17 Òyìnbó funfun ò doable fóba láàfin sòún ri o
Níjó títáláyé ti dáyé ò ò ò
Béè náà ni, níwájú omo Odérónké ti n wó tuuru
Níjó tó fòyìnbó párì joyè
Àlà e wà bí inú gbogbo kàà si n kan ni tiwa a
Àjàgbé Òkin baba ìlúróyè
Tí ùn n bá tún lo sónà bè mo mo mole wa
Ìgbà tí ò dè si eléyin ni mó ò
Ó wá korímádégún àjààgbé Òkin,
Tí ùn bá n lo sónà an be mo nú ilé wa
Salami Àjàgbé, omo ìtá Olónjó, omo Omídélé
Òré Òsú, Olóun Oba dàda
Ináwole baba kóta
Gbogbo won pata-pátá táa wí yí òòò
Orílè ti wón ti wá
Gbogbo won lomo ìbààrú onílè lìkì
Oláyankú omo ode báré etí oya
Ìbàrùbá won è é sunlé àlà
Won a ni e bami wéké yógùn nanana kí n róhun kole adodo
18 ìbàrùbá oonílè lìkì
Ìbàrùbá niwon eledin ese, omo ode báré eti oya
Òun ni baba tó se gbogbo wón lè pátápátá pogodo
Nílé è bààrú onílèe lìkì.
ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KÓKÓ NÍNÚ ORÍKÌ OBA ÒGBÓMÒSO
1. Ìran ìbàrùbá ni sòún ògúnlolá, ode ni ó se dé ibi ti a mò só Ògbómosò lónìí yìí. Sòún Ògúnlolá àwon kan pàdé nínú igbo, gégé bí ìtàn ti so, èéfìn iná ni wón fi mò pé àwon kan tún wà nínú igbó nàá.
Lára àwon kan tún Ògúnlolá bá pàdé ni Aálè èyí tí ó jé bale Òkèelérin, òbé ti ó jé bale Ìjérù, ìran Ègbá ni Òbé jé, nígbà tí Aálè jé ìran Tápà, gbogbo won jo n se ìpàdé ní òdò Sòún Ògúnlola, wón sì fi se alága.
2 Ìtumò Ògbó mòsó: Ìyàwó Sòún Ògúnlólá jé eni tí n pon Otí tà,
orúkootí náà ni oti ewe. Ìyàwó Ògúnlolá je bábá ìjèsà kan ní
Owo,
nibi ti wón ti jo n sòrò lówó ni Sòún Ògúnlolá wolé, èdè àìyedè
dé
láàrin Ògúnlolá àti baba náà, Sòún si lu bàbá náà pa.
wón fún Sòún Ògúnlolá ni àrokò pé kí ó lo fun Aláàrin, bí ó ti
débè, ó so fún Oba pé òun yóò bá won ségun elémòsó ti n pa
ará
Òyó. Ògúnlolá bá elémòsó jà ó sì paá ni ó bá gé ori rè, o sì gbe
fún
Aláàfin. Ògbórí elémòsó ni o di gbomoso.
Akínkanjú ti Ògúnlolá jé yìí ni o jé kí ó jé Olórí fún àwon Oba
aládé tí ó wà ní agbègbè Ògbómòsó.
Lára àwon Oba aládé náà ni Oba Arèsà, Oba Ònpetu abbl.
3 Ìtumò Otí ewe: Otí erèé ni à n pè ní otí ewé .