Jump to content

Ọdún gologo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ọdún Gologo, tí a tún mọ̀ sí ọdún Golib, máa ń di ṣíṣe àjọyọ̀ nínú oṣù kẹta ní ìparí àkókò ọ̀gbẹlẹ̀ síwájú kíkórè ọkà bàbà (Ansah, 1997; Allman & Parker, 2005).[1] Ọdún Gologo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọdún tó ṣe gbòógì [2]Ghana ó sì máa ń di ṣíṣe àjọ̀dún rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn olóyè àti àwọn ènìyàn Talensi, Tong-Zuf, ní Upper East Region àgbè ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà,[3] tí ó ń dúró fún "láti ró ìgbàgbọ́ àwùjọ lágbára ní ojúbọ Nnoo tàbí òrìṣà Golib",[4] òrìṣà tí ó ń sàmójútó ìgbésí ayé ohun ọ̀gbìn Talensi.[5] Ó jẹ́ ọdún tí wọ́n máa ń ṣe síwájú ìkórè nínú oṣù kẹta àti kẹrin, pẹ̀lú ìpèsè sí àwọn ònilẹ̀ fún ìdáábòbò àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò àti ìkórè gidi ní àkókò tó ń bọ̀.[2] Ọdún náà ní ètò ọlọ́jọ́ mẹ́ta ní abúlé mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Abala àkọ́kọ́ máa ń wáyé ní Gorogo, èkejì ní Yinduri, nígbà tí ìkẹyìn tí ó sì máa ń tóbi jù máa ń wáyé ní Teng-Zug (Tong-Zuf). Ọtí máa ń di dídà sílẹ̀ ní ojúbọ Teng-Zug láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ònilẹ̀ fún àṣeyọrí ayẹyẹ náà.[3] Ti oṣù kẹta ni wọ́n ń pè ní Gol-diema, tí ó túmọ̀ sí ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Ọdún Gologo gangan máa ń di ṣíṣe ní ọ̀sẹ̀ kejì ní oṣù kẹrin. Orin ìbílẹ̀ máa ń di ṣíṣe àgbékalẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbà tí agbègbè kọ̀ọ̀kan fún ayẹyẹ náà àwọn ènìyàn sì máa ń jó sí orin náà. Ní àkókò yìí, ariwo pípa di ṣíṣe léèwọ̀, ẹnikẹ́ni kì í sì í sunkún òkú wọn. Ọdún Gologo tí a tún mọ̀ sí ọdún Golib máa ń di ṣíṣe àjọyọ̀ ní oṣù kẹta ní ìparí àkókò ọ̀gbẹlẹ̀ síwájú kí ìkórè ọkà bàbà tó bẹ̀rẹ̀ (Ansah, 1997; Allman & Parker, 2005). Tengzug, Santeng, Wakii, Gbeogo, Yinduri/Zandoya, Shia, Gorogo àti Spart ni àwọn àwùjọ tí ó máa ń ṣe àjọyọ̀ ọdún náà. Ọ̀nà ìmúra wà níbí tí àwọn ọkùnrin ti máa wọ ṣòkòtò kékeré àti ìró ní igbá àyà wọn. Àwọn obìnrin máa ró ìró tó gùn láti igbá àyà wọn títí dé ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n sì bo orí wọn pẹ̀lú aṣọ tí ó dá yàtọ̀.

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ènìyàn Talensi ti Tenzug[6] ní agbègbè òkè ìlà oòrùn máa ń ṣe àjọyọ̀ ọ̀kan nínú àwọn ọdún tí kò wọ́pọ̀ ní ìlú Ghana. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọdún kan ṣoṣo tí àwọn olùkópa tí máa ń gbọ́ràn gidi gan-an sí wíwọ irú aṣọ kan ní pàtó. Látàrí ìṣẹ̀dálẹ̀ ìṣe yìí, àwọn olùsèwádìí ń wá ìrísí iṣẹ́-ọnà èyí tí wọ́n fi ṣe aṣọ náà àti ẹ̀sìn wọn tàbí pàtàkì ìlò wọn. Ìwádìí náà lo ìwòye àwọn akópa àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò láti ṣe àkọsílẹ̀ ọdún náà síwájú, ní àkókò àti lẹ́yìn ọdún náà. Àwọn èyí tó ṣe pàtàkì nínú aṣọ náà ni táwẹ́nù oníwọ̀n orísìírísìí àti àwọ̀, ọ̀bẹ oníwọ̀n orísìírísìí àti wíwọ aṣọ ìdáná. Ìwádìí kádìí rẹ̀ pé ìnílò wà fún láti ṣe ìpolówó ọdún náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè Ghana àti ní òkè òkun láti ba à lè sí agbègbè Tengzug sílẹ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò àti oníṣòwò.Àdàkọ:Cn

Ìgbáradì fún ọdún náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nínú oṣù kejì èyí tí ó síwájú àkókò àjọyọ̀ ọdún náà, àwọn ènìyàn àwùjọ máa ń kọ́ àwọn orin tuntun fún ayẹyẹ náà bẹ́ẹ̀ sì ni aṣọ tuntun àti ohun ọ̀sọ́ tuntun máa ń di ṣíṣe tàbí pípèsè. Ọjọ́ fún ayẹyẹ náà máa ń dá lórí yíyọ òṣùpá kẹta ní ọdọọdún. Èyí sì lè yọ ní oṣù kẹta tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹrin. Ní ọdún 2016, òṣùpá tuntun yọ ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹta. Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ nígbà tí òṣùpá yọ, olóyè àti Tindaana bọ́ àwọn aṣọ wọn (pàápàá jù lọ ẹ̀wù àti ṣòkòtò, wọ́n sì wọ regalia ìbílẹ̀ tí ó wà fún àjọyọ̀ náà). Àwọn ènìyàn ní àwùjọ náà bọ́ tiwọn ọjọ́ kan lẹ́yìn tí olóyè àti Tindaana ti ṣe bẹ́ẹ̀. Fún àwọn ará àwùjọ, bíbọ́ náà ni bíbọ́ gbogbo aṣọ tí ó bo òkè ara, bíbọ́ gbogbo ṣòkòtò àti wíwọ àwọ̀tẹ́lẹ̀, pátá àti ṣòkòtò kékeré nìkan lára wọn tí kò ní àpò, tàbí wíwọ kpalang tàbí kpalang peto. Bíbọ́ yìí wá fún àkókò oṣù kan. Láàárín àkókò yìí, kò gbọ́dọ̀ sí ariwo ní ààrin ìlú. Àti sísunkún òkú, bíbo ilé, gbígbọ́ orin tó pariwo láàárín àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn di èèwọ̀ ní àkókò yìí. Àwọn ènìyàn àwùjọ yóò wá bẹ̀rẹ̀ àwọn ètùtù ọdún kéékèèké ní àwọn ìlú tí ó yí òkè Tongo Hills[7] ká èyí tí ó kún fún ijó jíjó àti afẹ́ ṣíṣe. Ní ọjọ́ kẹrìndínlógún tí wọ́n ti bọ́ aṣọ (ní ọdún 2016, ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ kẹrìnlélógún osù kẹta ), gbogbo àwùjọ máa kóra jọ ní Tengzug fún ayẹyẹ ìkádìí ọdún.[8]

Pàtàkì ọdún náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó máa ń di ṣíṣe àjọyọ̀ láti ríi dájú pé “oríire nínú gbogbo oúnjẹ níbi ilé-iṣẹ́, ààbò kúrò níbi ewu, ààrùn àti ikú” (Insoll, et al., 2013). Níbi àjọ̀dún náà, wọ́n máa ń wúre fún òrìṣà Golib èyí tí ojúbọ Nnoo síwájú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Joffroy (2005) ti sọ, ọdún náà wà fún láti ró ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn àwùjọ náà lágbára ní ojúbọ.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Adjei, Daniel; Osei-Sarfo, Frank; Adongo, Georgina (January 2016). "Analysis of the art forms used as costume in the Gologo festival of the people of Tongo in the Upper East region of Ghana". Arts and Design Studies (41). ISSN 2225-059X. https://www.researchgate.net/publication/305769496. 
  2. 2.0 2.1 John-Bunya Klutse, "From January to December: Major Festivals in Ghana" Archived 2018-05-08 at the Wayback Machine., TourAfrica360, 1 March 2016.
  3. 3.0 3.1 "Festivals in Ghana". www.ghanaweb.com. Retrieved 27 December 2011. 
  4. Benjamin Warinsie Kankpeyeng, "The cultural landscape of Tongo-Tenzuk", Trip Down Memory Lane, 22 August 2013.
  5. Benjamin W. Kankpeyeng, Timothy Insoll, and Rachel MacLean, "Identities and Archaeological Heritage Preservation at the Crossroads: Understanding the Challenges of Economic Development at Tengzug, Upper East Region, Ghana", Ghana Soc Sci J. December 2010; 7: 87–102.
  6. atimian. "Tengzug Shrine". atlasobscura.com. 
  7. "Tongo Hills, Bolgatanga". 
  8. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named art_forms2