Ọdúnladé Adékọ́lá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:DMCÀdàkọ:Merge partner

Ọdúnladé Adékọ́lá (tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ́n oṣù Kejìlá ọdún 1976) jẹ́ òṣèrè sinimá àgbéléwò, ọ̀kọrin, olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ Yorùbá láti Ìpínlẹ̀ Èkìtì lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Àwọn sinimá àgbéléwò tó mú Ọdúnladé Adékọ́lá gbajúmọ̀ ni; Ìṣọ̀lá Dúrójayé, Àṣírí Gómìnà Wa, Adébáyọ̀ Àlàní Abẹ́rẹ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò Yorùbá tó pọ̀ jáǹtirẹrẹ. [1] [2]

Ìgbé-ayé Rẹ̀ Ní Ìbẹ̀rẹ̀ Pẹ̀pẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Abẹ́òkúta ní Ìpínlẹ̀ Ògùn ni Ọdúnladé Adékọ́lá ti ṣe kékeré rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Ekiti ní ìlú Ọ̀tun-Ekiti ni.

Awọn atokọ ti eré rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Ile Afoju (2019)"
  • The Vendor (2018)
  • Alani pamolekun (2015)
  • Asiri Gomina Wa (2003)
  • Mufu Olosa Oko (2013)
  • Kabi O Osi (2014)
  • Oyenusi (2014)
  • Sunday Dagboru (2010)
  • Monday Omo Adugbo(2010)
  • Emi Nire Kan (2009)
  • Eje Tutu (2015)
  • Ma ko fun E (2014)
  • Gbolahan (2015)
  • Oju Eni Mala (2015)
  • Kurukuru (2015)
  • Olosha (2015)
  • Omo Colonel (2015)
  • Aroba(2015)
  • Oro (2015)
  • Baleku (2015)
  • Babatunde Ishola Folorunsho(2015)
  • Adebayo Aremu Abere' (2015)
  • Adajo Agba (2015)
  • Oyun Esin(2015)
  • Taxi Driver: Oko Ashewo (2015)
  • Samu Alajo(2016)
  • Sunday gboku gboku (2016)
  • Abi eri re fo ni (2016)
  • "Igbesemi" (2016)
  • "Lawonloju" (2016)
  • "Pepeye Meje" (2016)
  • Asiri Ikoko (2016)
  • Pate Pate (2017)
  • Adura (2017)
  • Ere Mi (2017)
  • Okan Oloore (2017)
  • Ota (2017)
  • Owiwi (2017)
  • Agbara Emi (2017)
  • Critical Evidence (2017)
  • Olowori (2017)
  • Iku Lokunrin (2017)
  • Eku Meji (2017)
  • Yeye Alara (2018) as Dongari
  • Agbaje Omo Onile 1, 2, 3


Bí Ó Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdúnladé Adékọ́lá lọ sí ilé-ìwé akọ́bẹ̀rẹ̀ St. John Primary School, Abẹ́òkúta, ó tẹ̀síwájú lẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní St. Peter's College ní Abẹ́òkúta bákan náà. Ibẹ̀ ni ó ti gba ìwé - ẹ̀rí West African School Certificate Examination (WAEC), kí ó tó kàwé gboyè ẹ̀rí Diploma ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Moshood Abíọ́lá Polytechnic. Lọ́dún 2018, ó tún kàwé gboyè Bachelors of Business Administration ní Ifáfitì Ìjọba Àpapọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó, University of Lagos.


Àwọn Ìtọ́kasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Odunlade Adekola Biography, Did He Really Marry a Second Wife?". BuzzNigeria - Famous People, Celebrity Bios, Updates and Trendy News. 2018-09-07. Retrieved 2019-10-21. 
  2. "Tọ́mọ bá dára ó yẹ ká wí, ẹ wo Odunlade ọmọ Adekola". BBC News Yorùbá (in Èdè Latini). 2019-09-26. Retrieved 2019-10-21.