Aṣọ Ẹbí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Aṣọ Ẹbí nílẹ̀ Yorùbá jẹ́ aṣọ́ ẹgbẹ́jọdá tí wọ́n ń lò nígbà ayẹyẹ tàbí ọdún . Wọ́n máa ń lo aṣọ ẹbí fún oríṣiríṣi ayẹyẹ bíi ; ìsìnkú àgbà, ìkọ̀mọjáde, ìṣílé, ìgbọ̀mìnira lẹ́nu isẹ tàbí onírúurú ayẹyẹ mìíràn. [1]

Àsìkò tí a lè dá aṣọ ẹbí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gbogbo ọjọ́ ayẹyẹ tàbí ìgbà ọdún ni a lè dá aṣọ ẹbí. Àwọn orísirísi ayẹyẹ tàbí ọdún tí a lè dá aṣọ ẹbí nìwọ̀nyí; ayẹyẹ òkú àgbà, ìkọ̀mọjáde, ìgbéyàwó, ìṣílé tuntun, ìgbọ̀mìnira, ayẹyẹ àbọ̀dé Mẹ̀ká, ayẹyẹ òyè jíjẹ, ayẹyẹ Wòlímọ̀. Bákan náà, Yorùbá á máa lo aṣọ ẹbí nígbà onírúurú ọdún.

Pataki aṣọ ẹbí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Aṣọ ẹbí máa ń jẹ́ ọ̀nà láti fìfẹ́ àti ìṣọ̀kan hàn nígbà ayẹyẹ tàbí ọdún tí wọ́n dáṣọ ẹbí.[2]

Irú aṣọ tí a lè lò fún aṣọ ẹbí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láyé àtijó, aṣọ bíi ofì, sányán, kàm̀pálà, àrán, kenté àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n máa ń dá gẹ́gẹ́ bí aṣọ ẹbí. Ṣùgbọ́n lo de oni,

oríṣiríṣi aṣọ àsìkò ni a tún lè dá gẹ́gẹ́ bí aṣọ ẹbí. Àwọn aṣọ àsìkò bíi, àǹkàrá, léèsì lóríṣiríṣi, àtíkù, gínnì, sàtínnì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. òní

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Àṣà ìbálé lálẹ́ ìgbeyàwó ń dọdẹ àwọn obìnrin òde òní". BBC News Yorùbá (in Èdè Latini). 2019-06-15. Retrieved 2019-11-12. 
  2. "The Difference Between Aṣọ-ẹbí & Aṣọ-ẹgbẹ́jọdá". Yoruba Site | Home Of Latest Update... (in Èdè Latini). Archived from the original on 2019-11-12. Retrieved 2019-11-12.