Aalo Ìjàpá àti àná re
Ìjàpá àti Àna Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àlọ́ ooo
Àlọ́ ọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí Ìjàpá àti àna rẹ[1]
Gbogbo wa ni a ti mọ Ìjàpátìrókò ọkọ Yánníbo gẹ́gẹ́ bíi ọlọ́gbọ́nẹ̀wẹ́ àti ọ̀kánjúà tí ó sì tún jẹ́ Tìfunlọ̀ràn.
Ní ọjọ́ kan Ìjàpá gba ilé àna rẹ̀ lọ láti lọ kí wọn. Nígbà tí ó dé ilé àna rẹ̀, wọ́n ṣe àpọ́nlé rẹ̀ dáadáa. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe ṣe aájò Ìjàpá tó, ìwà rẹ̀ kò padà. Ìjàpá rí pé àwọn àna òun ń ṣe ẹ̀wà lórí iná. Ìjàpá ń rò nínú ara rẹ̀ ọ̀nà tí yíò fi bu díè nínú ẹ̀wà náà lọ sí ilé rẹ̀. Dípò kí Ìjàpá tọrọ ẹ̀wà lọ́wọ́ àna rẹ̀, ṣe ni ó ń rò bí yíò ṣe jí nínú ẹ̀wà náà.
Ìjàpá wo yányànyán kò rí ẹnìkankan ni ó bá rápálá lọ sí ibi tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀wà tí ó sì ń hooru yèèè. Ìjàpá bu díè nínú ẹ̀wà gbígbóná sí inú fìlà rẹ̀, ó sì dée m'órí. Nígbà tí ó ṣe, ẹ̀wà bẹ̀rẹ̀ sí jó Ìjàpá lórí ni ó bá sọ fún àna rẹ̀ pé òun ń lọ sí ilé òun. Àna Ìjàpá sì pinnu láti sìnín sí ojú ọ̀nà Ìjàpá rọ àna rẹ̀ títí kí ó má sin òun ṣùgbọ́n àna rẹ̀ kọ̀ jálẹ̀ pé òun ni lati paá lẹ́sẹ̀ dà.
Bí wọ́n ṣe rìn díè ni ooru ẹ̀wà bẹ̀rẹ̀ sí jó Ìjàpá ní orí. Nígbà tí kò le f'ara dàá mọ́ ni ó bá ti orin bọnu báyìí pé;[2]
ORIN ÀÀLỌ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìjàpá:__________Àna mi mo ní o padà lẹ́yìn mi
Ègbè:__________Ooru ẹ̀wà ń jó mí lórí foofáá
Ìjàpá:__________Àna mi mo ní o padà lẹ́yìn mi
Ègbè:__________Ooru ẹ̀wà ń jó mí lórí foofáá
Ìjàpá:__________Àna mi mo ní o padà lẹ́yìn mi
Ègbè:__________Ooru ẹ̀wà ń jó mí lórí foofáá
Nígbà tí Ìjàpá rí i pé òun kò le mú mọ́ra mọ́ ni ó bá sí fìlà lórí tí ẹ̀wà gbígbóná sì dà sílè fún ìyàlẹ́nu àna Ìjàpá. Ki Ìjàpá tó sí fìlà ooru ẹ̀wà tí bó Ìjàpá lórí. Ojú tí Ìjàpá púpọ̀ ní ọjọ́ yìí.
Èyí ló sì mú kí orí Ìjàpá ó pá títí di òní yìí[3][4].
Ẹ̀kọ́ Inú Ààlọ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìtàn yìí kọ́ wa wípé ojú kòkòrò kò dára.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales
- ↑ https://yorubafolktales.wordpress.com/
- ↑ https://ng.loozap.com/ads/akojopo-alo-ijapa-apa-kini/19079098.html[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2023-05-03. Retrieved 2023-05-04.