Jump to content

Aalo Asín, Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Ijapa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́



Ààlọ́ Asín Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Ìjàpá

Apá alo: Ààlo oooo

Elegbe: Ààlọ

Apààlọ: Ààlọ́ mi dá firi gbàgbó, ó dá lori Ìjàpá, Asín àti Ọ̀kẹ́rẹ́.[1]

Ni ayé àtijó, Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Ìjàpá jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ kò-rí-kò- sùn, wón fẹ́ràn ara wọn lópòlọpò. Òwò kan náà ni wọ́n jo ń se, àwo ni wọ́n ń tà, ibi kan náà ni wọ́n sì pa àte sí. Oníṣòwò àwo ni Asin náà, Asín àti okere wọ́n jọ wa ni ẹ̀gbẹ ara wọnní ọjà tí Ìjàpá sì ta kété sí wọn.

Ní ọjọ́ kan, Ọ̀kẹ́rẹ́ pẹ́ lọ s'ọ́jà, Ìjàpá ló ń dúró dè nítorí pé Ìjàpá kò le rìn kánmọ́-kánmọ́. Asín ti ru àwo tiẹ̀ dé ọjà, àwọn oníbaara rè ti ń rà á wìtì-wìtì kí Ọ̀kẹ́rẹ́ tó dé. Ìgbà tí Ọ̀kẹ́rẹ́ dé, ohun náà to'gbá tirẹ̀, ṣùgbọ́n esinsin ní yọ owó imí. Asín ni gbogbo ènìyàn n wó to. Inú bẹ̀rẹ̀ sini bí Ọ̀kẹ́rẹ́, bẹ́ẹ̀ni ni Okere bẹ̀rẹ̀ sini da gbogbo nkan ru, ó ṣì ń kọrin òwe, ó ń sọ oko ọ̀rọ̀ sí Asín, Ásín kò sì dá lóhùn. Asín kò gbin bẹ́ẹ̀ ni kò dún póbó[2].

Ní ìgbà tó yá, omo tí Asín gbé wá sí ọjà, ọmọdé náà ti bẹ̀rẹ̀ sí níí ra, Asín si sọọ kalè nígbà tó ńta jà fún àwọn onibara rè, ọmọ yìí ń rá kiri, ó ń ṣeré. Nígbà tí Ọ̀kẹ́rẹ́ pa àte àwo rẹ̀ kalẹ̀, ọmọdé yìí rá lọ sí ibè ó fi ọwọ́ kan ọkàn nínú àwo, ara ti kan aláwò yìí nígbà tí òun kò ta, ìyá ọmọdé yìí ló ń tà látàárọ̀, tìkanra tìkanra ló fi gbá ọwọ́ ọmọdé yìí, tó já àwo rẹ̀ gbà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní bú ìyá ọmọ yìí ní mẹsan án mẹwa.

Asín gbiyanju láti fún Ọ̀kẹ́rẹ́ ní sùúrù ṣùgbọ́n etí òdì ló fi ń gbọ́ gbogbo àlàyé Asín, báyìí ni Asín pẹ̀lú Ọ̀kẹ́rẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ipórogan. Wón ń bu ara won ní àbójú abomú láìpé àwọn méjèèjì kọlu ara wọn,wọ́n fi ìjà pẹẹ́ta. Asín kò lágbára tó Ọ̀kẹ́rẹ́ tẹ́lẹ̀, èrò pé òun yòò fìyà jẹ Asín ló wà lọ́kàn Ọ̀kẹ́rẹ́ tó fi so ọ̀rọ̀ di ìjàkadì. Àwọn méjéèjì bẹ̀rẹ̀ ìjàkadì. Ẹ̀sẹ̀ ń kù bí òjò, ariwo ń sọ gee, wón fọ àwo ara wọn, àwọn kan ń wòran, àwọn kan ń là ìjà nígbàtí àwọn kan ń dá kún ìjà. Ìròyìn kan Ìjàpá lára pé Asín àti Ọ̀kẹ́rẹ́ ń jà, igi ni Ìjàpá fàyọ, gẹ́gẹ́ bí ati mọ pé ọ̀rẹ́ tímotimo Ìjàpá ni Ọ̀kẹ́rẹ́, tí ó bá na Ọ̀kẹ́rẹ́ ní igi kan, mewaa ni yóò na Asín, nígbà tí Asín rí wípé Ìjàpá kò là wón ní ìjà, ìjà ọ̀rẹ́ rè Ọ̀kẹ́rẹ́ ló ń gbe tí owó rẹ sì le jù Ọ̀kẹ́rẹ́ tí òun ń bá jà lo, Asín fi Ọ̀kẹ́rẹ́ ṣílẹ̀ ó sì toro mó Ìjàpá ó de yín dé ní igi imú, eyín Asín wọlé sinsin, ẹ̀jẹ̀ ń san gburu láti igi imú Ìjàpá. Ìjàpá sọ igi nù, o mé kún ó fi dí igbe. ó ké pe èrò ọjà kí wón gba òun lọ́wọ́ Asín ó f'orin si, ó ń pe;[3]

Asín t'òun t'Ọ̀kẹ́rẹ́

Jóó mi jó

Àwọn ni wọ́n jọ ń jà

Jóó mi jó

Ìjà rèé mo wá là

Jóó mi jó

Asín bù mí nimú jẹ

Jóó mi jó

Ẹ gbà mí lọ́wọ́ rè o

Jóó mi jó

Àwo mi ń bẹ lọ́jà

Jóó mi jó

Ìjàpá àti gbogbo àwọn èrò tí ó wà ní ọjà bẹ̀rẹ̀ sí níí bẹ Asín ,Ọ̀kẹ́rẹ́ gan ń bẹ Asín ṣùgbọ́n tí Asín di ojú pin tí kò sì fi Ìjàpá sílè títí tí imú Ìjàpá fi já mo lénu ,báyìí ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí níí dá Ìjàpá lẹ́bi wípé kò la ìjà náà ní tùbí-ǹ-nùbí, wípé Ìjàpá ńṣe ojúsàájú láàrin won,láti ìgbà náà ni imú Ìjàpá tí kù kánmbo[4].

Ẹ̀kọ Inú Ààlọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ààló yìí kó wa pé kò yẹ kí á máa la ìjà àbòsí, bí onija bá ń jà, otún atosi ló yẹ ká dá lé kun, a ko gbọ́dọ̀ fàdi pọ mọ ẹnìkan ká máa na ẹni kejì o, Ọlọ́run má jẹ́ kí ọ̀ràn ọlọ́ran di tẹni o. Àṣẹ Èdùmàrè.


ÀWON ÌTỌ́KASÍ

  1. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  2. https://ng.loozap.com/ads/akojopo-alo-ijapa-apa-kini/19079098.html[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales
  4. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2023-05-03. Retrieved 2023-05-03.