Aalo ikun ati ekun
Àlọ́ oooo
Àlọ́ ọọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí Ẹkùn àti Ikùn
Ní ìlú àwọn ẹranko, kìnnìún ni Ọba wọn. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Ọba ẹranko pe gbogbo àwọn ẹranko jọ, ó sọ fún wọn pé òun fẹ́ dá ọjọ́ tí àwọn ẹranko yóò wa ṣe eré fún òun. Ó sọ pé ẹni tí ó bá lu ìlù dáadáa òun yóò da lọ́lá. Nítorí ìdí èyí ó ní kí ẹranko kọ̀ọ̀kan lọ kan ìlù. Gbogbo àwọn ẹranko gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọba, wọ́n dárí lọ sí ilé wọn[1].
Ẹni kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ẹranko ń gbìyànjú à ti kan ìlù. Ṣùgbọ́n dípò kí ẹranko kan tí orúkọ rẹ ń jẹ ikún ó kan ìlù tie, ní ṣe ni ó lọ gbé ìlú ẹkùn níbi tí ẹkùn gbé e sí. Ẹkùn bẹ̀rẹ̀ sí wa ìlú rẹ, ó wàá títí kò ri. Nígbà tí ó di ọjọ́ aré, ẹkùn jí ni kùtùkùtù ó lọ dúró ní ọ̀nà tí ó lọ sí ilé kìnnìún ọba ẹranko. Bí ẹranko kọ̀ọ̀kan bá ti fe kọjá ni ẹkún yóò yọ sí i tí yóò sì sọ pé kí ó lu ìlù rẹ̀ kí òun gbọ́[2]. Orin ni ẹkún fi ń sọ eléyìí fún wọn tí orin náà sì lọ báyì:
Ẹkùn________ Ríkíríkijàn
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ríkíríkijàn
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ aré
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ ayò
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Wọ́n ní á kànlù, mo kànlù
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Mo gbé ìlú mi s'àgbàlá
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọmọ ẹranko gbé e lọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Lùlù rẹ kí n gbọ́
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Lùlù rẹ kí n mọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakúkú rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakùkù rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ìlù mi kọ́ùn ni
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Rékọjá o máa lọ
Agberin_____Àríkijàn
Báyìí ni ẹranko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọjá tí ẹkùn sì ń kọ orin bákan náà. Nígbà tí ó kan ikùn láti kọjá, ẹ̀rù ti bẹ̀rẹ̀ sí bàa. Ẹkùn tún bẹ̀rẹ̀ orin rẹ̀ :
Ẹkùn________ Ríkíríkijàn
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ríkíríkijàn
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ aré
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ ayò
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Wọ́n ní á kànlù, mo kànlù
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Mo gbé ìlú mi s'àgbàlá
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọmọ ẹranko gbé e lọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Lùlù rẹ kí n gbọ́
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Lùlù rẹ kí n mọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakúkú rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakùkù rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ ìlù mi nùnun nì
Agberin_____ Àríkijàn
Bí ikùn tí gbọ́ pé ìlù ẹkùn ni òun gbé lọ́wọ́, pẹ̀ẹ̀ lójú ìlù sílè tí ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Ẹkùn gbá tẹ́lẹ̀e,ṣùgbọ́n bí ẹkùn ṣe ni kí òun ó ki ikùn mọ́lẹ̀ ni ó ṣá wọ inú ihò lọ. Ikùn kò lọ láì f'arapa, èékánná ẹkùn ha ikùn ní ẹ̀gbẹ̀ méjèèjì. Bí ènìyàn bá rí ikùn lónìí, yóò rí pé ilà funfun wà ní ẹ̀gbẹ̀ méjèèjì ikùn di òní olónìí yìí[3].
Ẹ̀KỌ́ INÚ ÀÀLỌ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ààló yìí kọ wa kí a má maa ja, nítorí pé kì í bí ọmọ rere.