Abúlé Abẹ́òkúta Ní Jamaica

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Abúlé Abẹ́òkúta jẹ́ ibi ìgbà fẹ́ tó rẹwà lọ́pọ̀lọpọ̀ ní orílẹ̀-èdè Jamaica. Ó yàtọ̀ sí Abẹ́òkúta tí ó jẹ́ olú-ìlú ìpínlẹ̀ Ògùn, lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1] Ó jẹ́ ibi ìgbafẹ́ tí ó kún fún àwọn ohun Ìgbé-ayé àtijọ́ tí kò lábàwọ́n àwọn ohun-èlò ọ̀làjú ayé òde òní. Wọ́n dá Abúlé Abẹ́òkúta ní ibi tí wọ́n ń pè ní Dean’s Valley Westmoreland ní Jamaica ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ọdún sẹ́yìn nígbà okowò ẹrú. Lọ́jọ́ karùn-ún oṣù kìíní ọdún 2003 ni aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sí Orílẹ̀ èdè Jamaica, Florentina Ukonga wá ṣí ibi ìgbafẹ́ Abúlé Abẹ́òkúta ní Jamaica.[2]

Ìbáṣepọ̀ láàrin ìlú Abẹ́òkúta ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Abúlé Abẹ́òkúta ní Jamaica[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìtàn sọ wípé, àwọn ẹrú àkọ́kọ́ tí wọ́n kó ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ọdún sẹ́yìn láti Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ sí orílẹ̀-èdè Jamaica ní wọ́n kó si oko, ibi tí wọ́n ń pè ní Abúlé Abẹ́òkúta ní Jamaica lónìí. Abúlé Abẹ́òkúta tóbi tó ìwọ̀n-ilẹ̀ ékà mẹ́tàlá. Àwọn òkúta àti òkè Abúlé Abẹ́òkúta ní Jamaica mú un dàbí Abẹ́òkúta ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [3] [4] Òkúta ńlá bí tó fara jọ Òkúta Olúmọ wà ní Abẹ́òkúta ní Jamaica. Ìjọra àgbègbè yìí ní Jamaica pẹ̀lú Abẹ́òkúta pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sọ ọ́ ní Abẹ́òkúta.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "You will want to tell all your friends about this place but, when you have found it, you may want to keep it all for yourself! Abeokuta Jamaica". Jamaicans.com. Retrieved 2019-11-19. 
  2. "Abeokuta". Jamaica Travel and Culture .com. 2007-02-23. Retrieved 2019-11-19. 
  3. Mayne, Marcia (2013-03-20). "Abeokuta Paradise Nature Park". InsideJourneys. Retrieved 2019-11-19. 
  4. "Abeokuta - Location, History, Facts, & Population". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2019-11-19. 
  5. "Diaspora Buzz - ASIRI". ASIRI Magazine. 2014-11-10. Retrieved 2019-11-20.