Adémọ́lá Adébise
Adémọ́lá Adébise | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1966 (ọmọ ọdún 57–58) Ìpínlẹ̀ Èkó, |
Iléẹ̀kọ́ gíga |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1988- dòní |
Gbajúmọ̀ fún | Wema Bank MD/CEO |
Adémọ́lá Adébise ni ó jẹ́ Adarí àgbà àti Olóòtú àgbà yán yán fún ilé-ìfowópamọ́ Wema Bank Plc.[1]
Ìgbà Èwe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Adébísí ní wọ́n bí ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá ọdún 1966 , ní Ìpínlẹ̀ Èkó sínú ẹbí ọ̀gbẹ́ni àti arabìnrin Adégòkè Adébíse. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Baptist Academy tí ó wà ní ìlú Sùúrùlérè ní àárín ọdún 1972 sí ọdún 1978, tí ó sì lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ fìgbà Yunifásitì ti Èkó níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ Kọ̀mpútà láàrín 1983 sí ọdún 1987.
Adébise gba oyè dìgírì kejì nínú ìmọ̀ Business Administration (MBA) ní ilé-ẹ̀kọ́ Lagos Business School tí ó sì ilé-ẹ̀kọ́ Advanced Management Program (AMP) tí ó wà nínú ilé-ẹ̀kọ́ Harvard Business School.
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Adébise ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ Information Technology Company tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí Programmer àti alààyè ìmọ̀ Kọ̀mpútà ní ọdún 1988 ṣáájú kí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣíṣe nílé ìfowó-pamọ́ Stanbic IBTC ní ẹ̀ka ètò ìmọ ẹ̀rọ. Ẹ̀wẹ̀, lára àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó tún ti ṣíṣẹ́ ni:
• Olórí lẹ́ka ẹ̀tò ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ àti Ọ̀gá agbà fún ètò ìṣúná (CFO) ti ilé Ìfowó-pamọ́ Chartered Bank (1989 sí 2000)
• Igbá kejì Adarí àgbà nílé ìfowó-pamọ́ National Bank supervised Risk Management, Treasury and Corporate Banking (2001 - 2005)
• Ọ̀gá àgbà ti ilé ìfowó-pamọ́ ti National Bank (2005).
• Adarí àgbà lẹ́ka ètò ìṣúná àti iṣẹ́ àkànṣe ní ilé-iṣẹ́ Accenture (2005)
• Adarí àti Olóòtú àgbà fún ilé-ìfowó-pamọ́ South Bank, Igbá kejì Adarí àgbà tí ó mójútó ilé ìfowópamọ́ Wema Bank_ (2017). Adébise di Olóòtú àgbà lẹ́yìn tí Adarí àgbà Ọ̀gbẹ́ni Ṣẹ́gun Olóètúyì fẹ̀yìn tí kúrò nile ìfowó-pamọ́ We ma Bank ní ọjọ́ọ́ Kíní oṣù Kẹwàá ọdún 2018 lẹ́yìn tí Ilé Ìfowó-pamọ́ àgbà ilẹ̀ Nàìjíríà ti fọwọ́ si kí ó di ọ̀gá àgbà. [2] Bákan náà ni ó tún ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ olókòwò bí Nigeria Inter-Bank Settlement System Plc (NIBSS), AIICO insurance Plc ati AIICO Pension Managers Limited
Àwọn ibi tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]• Institute of Chartered Accountants of Nigeria
• The Chartered Institute of Taxation of Nigeria
• The Chartered Institute of Bankers of Nigeria
• The Institute of Directors of Nigeria
• The Computer Professionals (Registration Council of Nigeria) CPN
Àwọn àmì-ẹyẹ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Business Day Award for the Top 25 CEOs in Nigeria (2009)
Ìgbé ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Adébise ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú arabìnrin Adéjùmọ̀kẹ́, wọ́n sì bímọ mẹ́ta.
Àwọn Itọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ademola Adebise Now MD/CEO of Wema Bank, Moruf Oseni Appointed Deputy Managing Director". Wemabank. Archived from the original on 2019-08-26. Retrieved 2019-08-26.
- ↑ "Wema Bank confirms Adebise as MD/CEO – Punch Newspapers". punchng.com. Retrieved 2019-08-26.
- Àwọn ọjọ́ìbí ní 1966
- Àwọn ènìyàn alààyè
- University of Lagos alumni
- Harvard Business School Advanced Management Program attendees
- Nigerian chief executives
- Nigerian bankers
- Yoruba bankers
- Baptist Academy alumni
- Pan-Atlantic University alumni
- Businesspeople from Lagos
- 20th-century Nigerian businesspeople
- 21st-century Nigerian businesspeople