Ada Ehi
Ada | |
---|---|
Ada Ehi live in Douala, Cameroon, February 2020 | |
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Ada Ogochukwu Ehi |
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | Ada Ehi |
Ọjọ́ìbí | 18 Oṣù Kẹ̀sán 1987 |
Irú orin | |
Occupation(s) | Singer-songwriter, recording artist |
Instruments | Vocals |
Years active | 2009–present |
Labels |
|
Website | adaehi.com |
Ada Ogochukwu Ehi tí wọ́n bí lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1987 (18 September 1987), simply known by her stage name jẹ́ akọrin ajíyìnrere, oǹkọ̀wé orin àti Òṣèrébìnrin ọmọ Nàìjíríà.[1] Nígbà tí ó wà lọ́mọdún mẹ́wàá ló ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ̀ nígbà tí ó gbe orin fún akọrin ọmọdé ẹgbẹ́ rẹ̀, Tosin Jegede. Láti ìgbà tí ó ti ń korin lábẹ́ ilé orin, Loveworld Records lọ́dún 2009, ló ti di gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká olórin.[2][3]
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìgbésí ayé rẹ̀ àti àti ìgbéyàwó
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Ada sí idiley Victor àti Mabel Ndukauba, òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ mẹta jọ dàgbà sí ìdílé ìgbàgbọ́ pẹ̀lú gbígbọ́ orin ìgbàgbọ́. Ó jẹ́ ọmọ Ìpínlẹ̀ Imo ní Nàìjíríà. [4] Nígbà tó wà lọ́mọ̀ ọdún mẹ́wàá, Wọ́n yàn án pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó wà nínú ikọ̀ agberin fún gbajúmọ̀ ọmọdé olórin Tósìn Jẹ́gẹ́dẹ́.
Ó kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ olóró (Chemical & Polymer Engineering) ní Lagos State University, ní àkókò náà, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìsìn Believers Loveworld Campus Fellowship.[5]Lẹ́yìn náà, ó dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin Christy Embassy, tí ó sìn darapọ̀ mọ Loveworld Records lọ́dún 2009.[6]
Ó pàdé ọkọ rẹ̀, Moses Ehi, ní ìjọ Christ Embassy church nínú ẹgbẹ́ akọrin. Wọ́n fẹ́ ara wọn lọ́dún 2008,wọ́n sìn bímọ méjì fún ara wọn.[7][8][9]
Iṣẹ́ orin
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Láti ìgbà tí ó ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin ìjọ Christ Embassy, ó ti bá wọn kópa nínú oríṣiríṣi ètò káàkiri Nàìjíríà àti ní àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé .[10] Àwo orin rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó pè ní Undenied ló gbé jáde lọ́dún 2009, tí ó sìn gbé ìkejì jáde lọ́dún 2013 èyí tí ó pè ní Lifted & So Fly.[11][12][13][14] Àwo orin rẹ̀ ìkẹta tí ó pè ní Future Now, jáde lọ́dún 2017, ó sìn di orin gbajúmọ̀ àkọ́kọ́ ní ìkànnì iTunes Nigeria lọ́jọ́ tó jáde gangan.[15]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ada Ehi biography". UzomediaTV- YouTube. August 1, 2017. Retrieved July 10, 2017.
- ↑ Jayne Augoye (July 8, 2017). "Gospel music singer, Ada Ehi, raises the bar with 'Overcame' video". Premiumtimes Nigeria. Retrieved July 10, 2017.
- ↑ Daniel Anazia (July 8, 2017). "Ada reaches new height with Overcame". Guardian NG. Archived from the original on July 8, 2017. Retrieved July 10, 2017.
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on September 20, 2022. Retrieved November 13, 2020.
- ↑ Chinyere Abiaziem (July 17, 2017). "'You Do Not Have To Be Naked to Look Good' – Ada". Independent NG. Retrieved July 17, 2017.
- ↑ https://www.busytape.com/ada-ehi-biography/
- ↑ https://africachurches.com/profile-and-biography-of-ada-ogochukwu-ehi/
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on September 20, 2022. Retrieved November 13, 2020.
- ↑ https://www.busytape.com/ada-ehi-biography/
- ↑ Uche Atuma (July 16, 2017). "WHAT I LEARNT FROM PASTOR CHRIS OYAKHILOME – Ada Ehi, International Gospel Music Minister". Sunnewsonline. Retrieved July 20, 2017.
- ↑ Francisca Kadiri (February 26, 2016). "Ada Ehi". Online Nigeria. Retrieved July 10, 2017.
- ↑ ThisDay (August 29, 2009). "Nigeria: The Emergence of Love World Records". channelstv. Retrieved July 21, 2017.
- ↑ nigeriatribune (June 11, 2017). "My music saved a woman from suicide —Ada Ehi". Nigeriatribune. Retrieved July 10, 2017.
- ↑ Alex Amos (August 31, 2013). "UPCLOSE: "I ROAR IN TONGUES" – "I’M RICH" CROONER ADA EHI IS ON FIRE! TALKS SPIRITUALITY, UPCOMING ALBUM, LOVE, FASHION AND MORE". selahafrik. Retrieved July 10, 2017.
- ↑ "Ada's New Album "Future Now" races to No. 1 Spot on iTunes Nigeria Same Day of Release – BellaNaija". BellaNaija. Retrieved October 25, 2017.