Jump to content

Adama Ndiaye

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Adama Ndiaye, tàbí Adama Amanda Ndiaye, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Adama Paris (tí ó tún jẹ́ orúkọ ilé-iṣẹ́ rẹ̀) , ni a bí ní ìlú Kinshasa. Jẹ́ aránṣọ ìgbà-lódé, ọmọ orílẹ̀-èdè Senegal. Àwọn  aṣọ tí ó ń rán ni ó ma ń kó wọlé láti orílẹ̀-èdè Morocco tí a sì lè rí àwọn aṣọ rẹ̀ rà ní àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé gbogbo bí  Parague,  Bahia, Paris, Montreal,London ,New York àti bẹ́ẹ̀ béẹ̀ lọ.

Ìgbésí ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ndiaye ni wọ́n bí nị́ ìlú Kinshasa, Zaire,[1] tí wọ́n sì tọ́ dàgbaà ní Europe, níbi tí àwọn òbí rẹ̀ ti jẹ́ aṣojú ìjọba ìlú wọn.[2] Ó fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ nílé ìfowó-pamọ́ ní Europe láti lọ kọ́ iṣẹ́ aṣọ rírán ní ìlú abí́nibí rẹ̀. Nínú ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó mọ̀ wípé ilẹ̀ Afíríkà ní àwọn àṣà ìránṣọ tó ṣe pàtàkì, àmọ́ tí wọn kò gbajúmọ̀ ní àwọn orílẹ̀ àgbáyé tó kù. kí ó tó rí owó dá ilé-iṣẹ́ aṣọ rírán rẹ̀ sílẹ̀ ṣòro díẹ̀ pẹ̀lú. Ndiaye dá ìdíje Fashion Week sílẹ̀ ní ìlú Dakar láti lè fẹ iṣẹ́ ọnà ìránṣọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ síwájú si.[3] Nígbà tí yóò fi di ọdún 2012, tí ìdíje náà pé ọdún mẹ́wá gbáko, àwón oníṣẹ́ ọnà aránṣọ ọgbọ̀n ni wọ́n ti dara pọ̀ mọ́ Ndiaye ní ilẹ̀ Afíríkà àti Asia, pẹ̀lụ́ àwọn olùkópa míràn kárí ayé. Ilé iṣẹ́ rẹ̀ sì ti ń ṣe ìṣúná tí ó tó CFA 80 milion ( tí ó jẹ́ US$150,000).[4][5] Bákan náà ni ó ti gbé ìdíje yí dé Prague, Czech Republic, àti Bahia, Brazil.[6][7]

Àwọn ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "BIOGRAPHIE "adama paris"". Retrieved June 28, 2012. 
  2. Lasjaunias, Aude (14 June 2012). "La mode africaine ne se limite pas aux pagnes et aux boubous". Le Monde. http://www.lemonde.fr/style/article/2012/06/14/la-mode-africaine-ne-se-limite-pas-aux-pagnes-et-aux-boubous_1718459_1575563.html. Retrieved June 28, 2012. 
  3. Sulmers, Claire (5 September 2011). "Adama Paris: Fashion Without Borders". Vogue Italia. Archived from the original on 9 October 2021. Retrieved June 28, 2012. 
  4. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Lewis
  5. "Dakar Fashion Week: Adama Paris étale ses ambitions". Leral.net. 13 June 2012. Retrieved June 28, 2012. 
  6. Gleye, Fatou (February 2012). "Africa Prague". Afroglam: 36. 
  7. "Dakar capitale de la mode". BBC Afrique. 13 June 2012. Retrieved June 28, 2012.