Jump to content

Ọọ̀ni Adelekan Olubuse I

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Adelekan Olubuse I)

Adelekan Olubuse I ni Ọọ̀ni ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínláàádọ́ta tí Ilé-Ifẹ̀, tó jẹ́ olórí ìbílẹ̀ ti Ilé-Ifẹ̀, tó jẹ́ orírun àwọn ọmọ Yorùbá. Ó gun orí oyè yìí lẹ́yìn tí Ọọ̀ni Derin Ologbenla wàjà, tí Ọọ̀ni Adekola sì jẹ oyè yìí lẹ́yìn tí òun wàjà.[1]

Olubuse ni olùdásílẹ̀ House of Sijuwade, èyí tó jẹ́ ẹ̀ka ilé Ogboru. Olubuse I náà ni bàbá Omo-Oba Adereti Sijuade, àti bàbá-bàbá Oba Okunade Sijuwade, tó jẹ́ Ọọ̀ni àádọ́ta ti Ilé-Ifè.[2][3][4]

Ìṣepàtàkì ìtàn rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adelekan Olubuse I ni Ọọ̀ni àkọ́kọ́ tó máa kúrò lórí oyè láti ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìfi-ọba-jẹ, láti 500 B.C. Ìjọba ìfi-ọba-jẹ yìí ti wà fún ẹgbẹ̀rin ọdún. Lásìkò tí àwọn òyìnbó amúnisìn ń jọba ní ilẹ̀ Yorùbá, Sir William Macgregor tó jẹ́ gómìnà sọ fún Olubuse I kí ó lọ sí ìpínlẹ̀ Èkó, láti parí aáwọ̀ kan, kí ó sì jábọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ náà pẹ̀lú ipò àti àlàáfíà àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọdún 1903.[5][6]

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ìbápàdé àkọ́kọ́ tí Ilé-Ifẹ̀ máa ní pẹ̀lú ìjọba àwọn amúnisìn.[5][7]

Ní àsìkò yìí, gbogbo Ọba ilẹ̀ Yorùbá fi ipò wọn lẹ̀ nígbal tí Ọọ̀ni rin ìrìn-àjò lọ sí Èkó, nítorí àwọn Ọba kékeré yòókù kọ̀ láti di àwọn ipò tó ṣófo mú.[8][9]

Ìṣepàtàkì ẹ̀sìn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nínú ẹ̀sìn Ifá ti àwọn Yorùbá, ni ìlú mímọ́ wà, tí ó sì wà láti ìlú Ifẹ̀ títí dé ààfin Ọọ̀ni fúnra rẹ̀.[10] Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn òrìṣà rọ̀ sí nígbà tí wọ́n wá sí ìsàlú ayé, àti pé ọ̀kan lára àwọn òrìṣà náà tí ń ṣe Ọbàtálá jẹ́ Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ àkọ́kọ́, tí a mọ̀ sí Odùduwà. Gbogbo ọ̀nà ní Ilé-Ifẹ̀ ló já sí ààfin Ọba. Ààfin yìí sì ní ẹ̀sìn wọn forí sọlẹ̀ sí, tí ó sì jẹ́ ibi mímọ́, nítorí Ọọ̀ni gan-an alára jẹ́ òrìṣà tí wọ́n ń bọ. Jacob Olupona fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé gẹ́gẹ́ bí àwọn Gẹ́ẹ̀sì ṣe gbàgbọ́ wí pé Ọlọ́run fi ọ̀run sílẹ̀ wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọbàtálá fi ọ̀run sílẹ̀ láti wa jẹ oyè Ọọ̀ni ní ayé.[11]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Dayo, Ologundudu (2008). The cradle of Yoruba culture. Nigeria: Centre for spoken words. p. 206. ISBN 978-0615220635. https://books.google.com/books?id=Vn8uAQAAIAAJ&q=Ooni+Ojigidiri. Retrieved July 30, 2015. 
  2. "OBITUARY: Oba Okunade Sijuwade (1930-2015), the Ooni who loved Jonathan 'like a son'". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-07-29. Retrieved 2023-06-28. 
  3. Odesola, Tunde (2023-06-15). "Ooni: The public displays of a king (II)". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-28. 
  4. "Okunade Sijuwade Olubuse II (1930-2015)". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-08-19. Retrieved 2023-06-28. 
  5. 5.0 5.1 Olupona, Jacob (2011-12-13). City of 201 Gods. University of California Press. doi:10.1525/9780520948549. ISBN 978-0-520-94854-9. http://dx.doi.org/10.1525/9780520948549. 
  6. "Ile Ife, Nigeria (ca. 500 B.C.E.- ) •" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2011-03-16. Retrieved 2022-10-28. 
  7. "Prince Adedapo Aderemi: A Short but Memorable Life - THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2023-06-28. 
  8. Sanusi, Sola (2018-07-19). "Story of the first Ooni of Ife to travel to Lagos, all Yoruba kings vacated their thrones during his sojourn". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-28. 
  9. Nigeria, Guardian (2019-01-20). "‘In the past, Ooni neither travelled nor spoke in public’". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2023-02-09. Retrieved 2023-06-28. 
  10. Wariboko, Nimi (2014), "The King's Five Bodies", The Charismatic City and the Public Resurgence of Religion, New York: Palgrave Macmillan US, pp. 57–79, ISBN 978-1-349-49674-7, doi:10.1057/9781137463197_4, retrieved 2022-10-28 
  11. Olupona, Jacob (2011-12-13). City of 201 Gods. University of California Press. doi:10.1525/9780520948549. ISBN 978-0-520-94854-9. http://dx.doi.org/10.1525/9780520948549.