Aderonke Apata
Aderonke Apata | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | January 20, 1967 Nigeria |
Gbajúmọ̀ fún | Being an LGBT activist and former asylum seeker |
Aderonke Apata (tí a bí ní ogúnjọ́ oṣù kínní ọdún 1967) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ń jà fitafita nípa LGBT, àti ẹni tí ó tí n wá ibi ààbò tẹ́lẹ̀. Àwọn media káàkiri ni wọ́n mọ Aderonke nítorí ọ̀ràn ibí ààbò rẹ ní ilé gèésì United Kingdom.[1][2]
Apata ni olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ aláànú kan tí wọ́n ń pè ní African Rainbow Family.[3]
Ìgbésíayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Aderonke Apata ni a bí ní ogúnjọ́ oṣù kínní ọdún 1967 ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[4] Nígbàtí Àpáta wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni ó kọ́kọ́ mọ̀ pé alákọméjì ni òun. Nítorípé àwọn ẹbí Àpáta ti ń fura pé alákọméjì ni Àpáta, àti wípé àwọn ẹbí ọkọ rẹ̀ bákannáà ń fura síi pé alákọméjì ni àti pé ó má n ní àjọṣepọ̀, ni o ṣe di ẹni tí olópàá ń mú léyìn tí wón ti ríi wípé ó ń lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ akọsákọ tàbí abosábo nínú ilé rẹ. Wọ́n mú Àpáta lọ sí ilé-ẹjọ́ Sharia níbití wọ́n ti dá ẹjọ́ ikú fún un nípa sísọ ọ́ ní òkúta pa fún ṣíṣe àgbèrè àti àjẹ́.[5][6] Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n fagilé ẹjọ́ yìí nígbàtí ẹnití ó dúró bíi agbẹjọ́rò rẹ toka sí òfin pàtàkì kan láti tako ìdájọ́ yìí. Kí ó tó di wípé wọ́n gbe e lọ sí ilé-ẹjọ́, wọ́n mú u lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n níbití wọ́n tí fii sí túbú ojútáyé pẹlú àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn.
Àpáta sá kúrò ní orílè-èdè Nàìjíríà lọ sí ìlú Londonu, ilẹ́ gẹ̀ẹ̀sì níbití ó tí kọ́kọ́ béèrè fún ààbò lábẹ́ ẹ ẹ̀sìn ní ọdún 2004 nítorí pé ó wá láti ìdílé onígbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé ọkùnrin mùsùlùmí kan ni ó ti kọ́kọ́ fẹ́ ní ọ̀nà tí kòtọ́. Ó ṣe eléyìí ní ìgbìyànjú láti pé kí ó lè bọ ìbáṣepọ̀ ọlọ́jọ́-pípẹ́ tí ó wà láàrín òun àti ọmọbìnrin mìíràn mọ́lẹ̀. Lẹ́hìn tí ó ti kọ́kọ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀meji fún ibi ààbò tí wọ́n sì ti kọ jálẹ̀ fun un, ó di kí ó máa gbé ní àwọn òpópónà ní Manchester láti pé kí wọ́n mà le dáapadà sí orílè-èdè Nàìjíríà. Ní oṣù kẹwàá ọdún 2012, Ó lo oṣù kan ní àhámọ́ tí òun nìkan dáwà ní Yari's Wood Immigration Removal Centre gégé bíi ìjìyà fún dídarí ẹ̀rọ́nú alálàláfíà ní agbègbè náà.
Ní ọdún 2012, lẹ́hìn tí wọn mú Àpáta pé ó ń ṣe iṣẹ́ gégé bíi alàkóso olùtọ́jú pẹ̀lú ayédèrú físà, ó tún gbìyànjú láti bèèrè fún ibi ààbò nítorí pé ó ń bẹ̀rù láti padà wá sí orílè-èdè Nàìjíríà níbití wọ́n ti lè ṣe inúnibíni síi nípa fífi ẹ̀sùn kan án nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ rẹ. Ibi ààbò tí ó béèrè fún yí àti ibi ààbò mìíràn tí ó béèrè fún ni wọ́n kọ̀ jálẹ̀ fun un ní ọdún 2014 àti ní ọjọ́ kìnní oṣù kẹrin ọdún 2015 ní tẹ̀léntẹ̀lé nítorí pé ilé-iṣẹ́, èyí tíí ṣe ẹ̀ẹ̀ka kan lábẹ́ ìgbìmọ̀ mínísítà ní ilé gèésì kò gbàgbọ́ pé alákọméjì ni Àpáta nitori pé ó ti ní àjọṣepọ̀ pẹlú ọkùnrin kan tẹ́lẹ̀ tí ó sì ti bí àwọn ọmọ fún okùnrin náà.[7][8][9] Ní ọdún 2014, Apata sọ wípé òun yóò fi fídíò tí yíò hàn gbángba láti jẹ́rìsí ìbálòpọ̀ òun ránṣẹ́ sí Home Office yìí. Èyí ló mú kí bíbéèrè fún ibi ààbò rẹ yìí gba àtìlẹ́yìn káàkiri, pẹ̀lú bí àwọn ènìyàn ṣe fèsì nípa kíkọ àwọn ìwé ẹ̀bẹ̀ èyítí wọ́n gbà ọgọọ́gọ́rùn ún ẹgbẹ̀rún àwọn ìbuwọ́lù lápapọ̀. Léhìn náà, ó ku díẹ̀ kí wọ́n dá Apata padà wá sí orílè-èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un nígbàtí ó wa ọkọ̀ dé pápákọ̀ òfurufú na wípé wọ́n ti fagilé ìrìn-àjò ọkọ̀ òfurufú rẹ sí orílè-èdè Nàìjíríà.
Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹjọ ọdún 2017, léhìn ọdún mẹ́tàlá tí ìpẹ̀jọ́ ti ń wáyé àti léhìn fífi ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tuntun tí Apata pè sí òpin oṣù keje, Home Office fún un ní ààyè ní ilẹ̀ gèésì gégé bíi ẹni tí ó sá àsálà. Iyọ̀ọ̀dà ibi ààbò tí wọ́n fún Apata ni ó parí ní ọdún márún ún, ṣùgbọ́n léhìn náà ó ní ànfàní láti bèèrè fún gbígbé ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì títílaí.[10]
Ìgbésí ayé ara ẹni
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Léhìn tí Apata kọ́ ẹ̀kọ́ jáde ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó ní ọ̀rẹ́bìnrin kan tí wọ́n jọ gbé papọ̀ ní ìyẹ̀wù kànnà.
Ní ọdún 2005, àyẹ̀wò fi hàn pé Apata ní àrùn tí wọ́n ń pè ní Post-traumatoc stress disorder (PTSD). Apata gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ nígbàtí ó wà nínú túbú tí ó ńkojú ẹjọ́ ìdápadà sí orílè-èdè rẹ. Ní ọdún 2012, wọ́n pa alágbàṣepọ̀ rẹ obìnrin tẹ́lẹ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ojú-lalákàn-finṣọ́rí kan. Arákùnrin Apata àti ọmọ ọdun mẹ́ta ni wọ́n tún pa nínú àwọn ìṣẹlẹ ojú-lalákàn-fínṣọ́rí.
Láti ọdún 2015 ni Apata àti Happiness Agboro, ẹni tí wọ́n tí fún ní àṣẹ láti gbé ìlú lábẹ́ ẹ pé ó ńsá àsálà fún èmí rẹ̀ ní ilẹ̀ gèésì èyí tí ó dá lórí ìbálòpọ̀ rẹ, ti gbà láti fẹ́ ara wọ́n. Láti bíi ọdún 2017 ni Apata tí ń gbé ilẹ̀ gèésì.
Àwọn àmì ẹ̀yẹ àti ìyìn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- LGBT Positive Role Model Award from the 3rd National Diversity Awards (2014).[11]
- Activist of the Year from the 24th Sexual Freedom Awards (2018).[12]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Taylor, Diane (2017-08-14). "Nigerian gay rights activist wins UK asylum claim after 13-year battle". the Guardian. Retrieved 2021-09-22.
- ↑ "Why the Home Office rejects so many LGBTQ asylum claims". City, University of London. 2020-09-23. Retrieved 2021-09-22.
- ↑ "Nigerian LGBTQ activist granted asylum in UK after 13-year legal battle". NBC News. 2017-08-14. Retrieved 2021-09-22.
- ↑ "Aderonke APATA - Personal Appointments (free information from Compani…". archive.ph. 2021-01-10. Retrieved 2021-09-22.
- ↑ Dugan, Emily (2014-06-09). "Gay Nigerian asylum-seeker in fight to stay in the UK". The Independent. Retrieved 2021-09-22.
- ↑ Dunt, Ian (2015-12-27). "Can you prove you're gay? Last minute legal battle for lesbian fighting deportation to Nigeria - Home Affairs". politics.co.uk. Archived from the original on 2015-12-27. Retrieved 2021-09-22. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Ashton, Jack (2017-08-14). "Gay rights activist who judge accused of 'faking' her sexuality wins 13-year legal battle for asylum in UK". The Independent. Retrieved 2021-09-22.
- ↑ Dugan, Emily (2015-04-03). "A High Court judge just told a Nigerian gay rights activist she is not a proper lesbian". The Independent. Retrieved 2021-09-22.
- ↑ "Lesbian Nigerian woman told: 'Prove you're gay to stay in Britain' - …". archive.ph. 2015-04-22. Retrieved 2021-09-22.
- ↑ Hornall, Thomas; Association, Press (2017-08-14). "Nigerian Lesbian Granted Asylum After 13-Year Battle Against Deportation". HuffPost UK. Retrieved 2021-09-22.
- ↑ "National Diversity Awards". Wikipedia. 2014-01-29. Retrieved 2021-09-22.
- ↑ "2018 Finalists". Sexual Freedom Awards. 2018-11-15. Retrieved 2021-09-22.