Jump to content

Adesuwa Onyenokwe

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Adesuwa Onyenokwe (bíi ni ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹjọ ọdún 1963), jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí telefisionu ni Nàìjíríà.[1] Ò jẹ́ atọkun ètò fún NTA tẹ́lẹ̀ kí ó tó di alatunse fún ìwé ìròyìn tí Todays Woman.[2] Òun ni atọkun ètò Seriously Speaking tí ó jáde ní ọdún 2014.[3][4]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí sì ìlú Ibadan ni ìpínlè Ọ̀yọ́ ni ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹjọ ọdún 1963. Òun ni ọmọ karùn-ún nínú àwọn ọmọ mọ́kànlá tí àwọn òbí rẹ bí.[5] Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Emotan Preparatory school àti Idia college ni ìlú Benin ni ìpínlè Edo. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Obafemi Awolowo University níbi tí ó tí gboyè nínú ẹ̀kọ́ dírámà.[6][7] [8]

Bàbá rẹ̀ fẹ́ kí ó di agbejoro ṣùgbọ́n ó nifẹ si ère ṣíṣe láti ìgbà tí ó wà ní ọmọdé.[9] Ìgbà tí ó ń ṣe agùnbánirọ̀ ni ọdún 1983 ni National Television Authority, ní o ti kọ́kọ́ ni ànfàní láti ṣe agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ni ìpínlè Sokoto. Ó ṣe atọkun fún ètò àwọn ọmọdé lórí telefisionu. Leyin ti o pari ètò àgunbánirọ̀ rẹ ni ọdún 1984, ó kúrò ní Sokoto lọ sí ìpínlè Edo láti di olùkọ́ ni ilé ẹ̀kọ́ tí Akenzua II Grammar School. Ní ọdún 1985, ó padà sí iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ni ile iṣẹ́ Bendel Broadcasting Service tí won wá padà yí orúkọ wọn sì Edo Broadcasting Service.[10] [11] Ó fé Ikechukwu Onyenokwe ni ọdún 1988, ó sì ti bí ọmọ mẹ́fà fún..[12] [13] [14] Lẹ́yìn ìgbéyàwó rẹ, o kúrò ní ìlú Benin lọ sí ìpínlè Èkó. Ó kọ ìwé ifisẹ sílẹ̀ fún Edo Broadcasting Service, ó sì darapọ̀ mọ́ Nigerian Television Authority ni Èkó.[15][16] Ó ti ṣe atọkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò fún NTA. Òun ni atọkun ètò fún News line tẹ́lẹ̀. Ó fi iṣẹ́ NTA sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹẹdogun tí ó ti ń si ṣẹ́ fún wọn.[17] Ní ọdún 2000, ó bẹ́ẹ̀rẹ̀ ètò obìnrin òde òní pẹ̀lú Adesuwa lóri NTA, ó sì ṣe ètò naa fún ọdún Mẹwa. Ní ọdún 2007, Adesuwa gbé ìwé ìròyìn tí Today's Women tí ó ṣọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé àwọn obìnrin.[18] Òun ni atọkun ètò TW Conversations lóri African Magic.[19] Ní oṣù kejì ọdún 2015, ó ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nurọ̀ [20]fún olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà náà, Goodluck Ebele Jonathan. Ó bẹ́ẹ̀rẹ̀ ètò Seriously Speaking lórí Channels TV ni oṣù keje ọdún 2014.[21] [22][23] Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹjọ ọdún 2016, ó gbé ètò VLOG rẹ kalẹ tí ó pè ní Speaking my mind with Adesuwa.[24] [25] Òun ni ó ṣe àntí ni èrè Ultimate Love tí àwọn ilé iṣẹ́ Multichoice gbé kalẹ̀.[26][27] [28][29]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Adesuwa Onyenokwe: Empowering women through the power of the media". The Vanguard. https://www.vanguardngr.com/2015/05/adesuwa-onyenokwe-empowering-women-through-the-power-of-the-media/. Retrieved December 28, 2017. 
  2. "As Nigerian Fashion Booms, Women Lead Its Coverage" (in en). https://www.nytimes.com/2018/11/04/business/media/nigerian-fashion-magazines-women.html. 
  3. "Adesuwa Onyenokwe hits 54". The Guardian. Archived from the original on December 22, 2022. https://web.archive.org/web/20221222052429/https://guardian.ng/saturday-magazine/adesuwa-onyenokwe-hits-54/. Retrieved December 28, 2017. 
  4. "ADESUWA ONYENOKWE returns to the tube with SERIOUSLY SPEAKING". Encomium. http://encomium.ng/adesuwa-onyenokwe-returns-to-the-tube-with-seriously-speaking/. Retrieved December 28, 2017. 
  5. https://punchng.com/my-husband-feels-proud-whenever-men-admire-me-adesuwa-onyenokwe/
  6. https://www.vanguardngr.com/2015/05/adesuwa-onyenokwe-empowering-women-through-the-power-of-the-media/
  7. https://punchng.com/my-husband-feels-proud-whenever-men-admire-me-adesuwa-onyenokwe/
  8. https://mybiohub.com/2016/06/adesuwa-onyenokwe-biography-family-age.html/
  9. https://punchng.com/my-husband-feels-proud-whenever-men-admire-me-adesuwa-onyenokwe/
  10. https://www.vanguardngr.com/2015/05/adesuwa-onyenokwe-empowering-women-through-the-power-of-the-media/
  11. https://punchng.com/my-husband-feels-proud-whenever-men-admire-me-adesuwa-onyenokwe/
  12. https://ynaija.com/7-reasons-adesua-onyenokwe-icon-generation/
  13. <https://mybiohub.com/2016/06/adesuwa-onyenokwe-biography-family-age.html/
  14. https://www.vanguardngr.com/2015/05/adesuwa-onyenokwe-empowering-women-through-the-power-of-the-media/
  15. https://www.vanguardngr.com/2015/05/adesuwa-onyenokwe-empowering-women-through-the-power-of-the-media/
  16. https://punchng.com/my-husband-feels-proud-whenever-men-admire-me-adesuwa-onyenokwe/
  17. https://ynaija.com/7-reasons-adesua-onyenokwe-icon-generation/
  18. https://www.vanguardngr.com/2015/05/adesuwa-onyenokwe-empowering-women-through-the-power-of-the-media/
  19. https://ynaija.com/7-reasons-adesua-onyenokwe-icon-generation/
  20. https://www.vanguardngr.com/2015/05/adesuwa-onyenokwe-empowering-women-through-the-power-of-the-media/
  21. https://www.bellanaija.com/tag/adesuwa-onyenokwe/
  22. http://encomium.ng/tag/adesuwa-onyenokwe/
  23. https://www.vanguardngr.com/2015/05/adesuwa-onyenokwe-empowering-women-through-the-power-of-the-media/
  24. https://leadingladiesafrica.org/adesuwa-onyenokwe-launches-vlog-series-watch/
  25. https://mybiohub.com/2016/06/adesuwa-onyenokwe-biography-family-age.html/
  26. https://theeagleonline.com.ng/adesuwa-onyenokwe-unveiled-as-aunty-on-ultimate-love/
  27. https://stories.showmax.com/5-things-you-should-know-aunty-on-ultimate-love/
  28. https://www.thisdaylive.com/index.php/2020/04/17/adesuwa-onyenokwe-kachis-patience-rosies-honesty-made-them-winners-of-ultimate-love/
  29. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2020-02-11. Retrieved 2020-05-22.