Afeez Ẹniọlá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Afeez Ẹniọlá tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kejìlélógún oṣù kejì jẹ́ òṣeré, olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [1]

Ìgbà èwe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Afeez Ẹniọlá lọ́jọ́ kejìlélógún oṣù kejì (22nd February) ní ìlú ṣómólú ni ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Èkó náà ló ti kàwé. Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà ni, ó fẹ́ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Esther Kálèjayé tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ọmọ jọ yíbò. [2] [3] Afeez dara pọ̀ mọ́ àwọn eléré tíátà fún ìgbà pípẹ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ òṣèrébìnrin kan tí ó ń jẹ́ Bọ́sẹ̀ Olúbọ̀. Lẹ́yìn náà, Afeez tí kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó ti ju ọgọ́rùn-ún lọ

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Author_name (2018-02-22). "Bola Esho's Blog: Biography Of Nollywood Actor, Afeez Eniola". Bola Esho's Blog. Retrieved 2019-12-31. 
  2. "Yoruba movie star, Eniola Afeez celebrates wife as she marks birthday today (photos) - Kemi Filani News". Kemi Filani News. 2016-03-30. Retrieved 2019-12-31. 
  3. "Popular Yoruba actor, Afeez Eniola is a year older today - Nigerian Entertainment Today". Nigerian Entertainment Today. 2016-02-22. Retrieved 2019-12-31.