Afreen Fatima
Afreen Fatima | |
---|---|
Orílẹ̀-èdè | Indian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Jawaharlal Nehru University |
Iṣẹ́ | Student leader |
Organization | Fraternity Movement |
Gbajúmọ̀ fún | Anti-CAA protests, activism for representation and identity assertion |
Title | National Secretary |
Political party | Fraternity Movement |
Afreen Fatima jẹ́ ọkan nínú àwọn olórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní India. Ó sì jẹ́ Akọ̀wé àgbà ẹgbẹ́ Fraternity Movement ti gbogbo orílẹ-èdè náà. Ó jẹ́ mùsùlùmí tí ó gbajúmọ̀ fún ipa takaun-takun tí ó ń kó nínú ṣíṣe àtakò fún àwọn òfin ìjọba India tí ó ń kó ìpalára bá àwọn mùsùlùmí.[1][2]
Eto ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]O kọ ẹkọ gboyè MA nipa imọ-ede ni JNU. Ó tún ṣe ìránṣẹ́ ti ìgbìmọ̀ tí a yàn ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ JNU 2019-20 láti ẹ̀ka ilé-ẹ̀kọ́ ti Èdè, Lítíréṣọ̀ àti Àwọn Ìkẹ́kọ Àṣà. Gẹ́gẹ́ bí olùdíje láti Ẹgbẹ́ Fraternity - Alliance BAPSA,[3] ó fún ìpè ti “iṣọkan ti àwọn tí a ń nilára” l'ókun ó sì gbé àwọn ọ̀rọ̀ nípa ṣíṣojú, ìya-ara-ẹni-sọ́tọ̀ àti ìdánilójú ìdánimọ̀ dìde.[4] Ní ìṣáájú, wọ́n ti dìbò yán-án gẹ́gẹ́ bí ààrẹ fun Ẹgbẹ àwọn obìnrin ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tí àwọn mùsùlùmí, Aligarh fún sàá 2018-19.[5]
Wọ́n mọ̀ ọ́ fún ipa ribiribi tí ó ń kó nínú ṣíṣe àwọn ìfẹ̀honúhàn lórí àtakò CAA tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2019.[6] Ó kojú ọ̀pọ̀ ìbéèrè láti ọ̀dọ̀ àwọn oníròyìn fún ọ̀jọ́ tí ó pẹ́ nitori apákan ọ̀rọ̀ ìtara tí ó sọ dí kíkọ jáde sórí ayélujára x láti ọwọ́ agbẹnusọ àgbà fún BJP, Sambit Patra.
Ní oṣù kẹfá àwọn adarí ní Prayag Ran wó ilé rẹ̀ lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀, Jawed Muhammad, àgbà nínú ẹgbẹ́ Welfare ní India dá ìfẹ̀honúhàn sílẹ̀ tí ò níí ṣe pẹ̀lú sisọ òkò àti àwọn ohun tí ó lè gbaná (àwọn fídíò rẹ̀ wà ní orí ayélujára) nítorípé Nupur Sharma sọ̀rọ̀ burúkú sí Jaweed Muhammad.[7]
Àwọ́n Atọ́ka
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Afreen Fatima" (in en). Time. 5 July 2022. https://time.com/author/afreen-fatima/. Retrieved 2022-08-03.
- ↑ Aafaq, Zafar (13 June 2022). "India activist Afreen Fatima says her house bulldozed 'illegally'". Al Jazeera. https://www.aljazeera.com/news/2022/6/13/act-of-vendetta-afreen-fatima-on-her-house-bulldozed-in-india. Retrieved 10 December 2022.
- ↑ Ghosh, Shaunak (13 September 2019). "Tectonic Shift: BAPSA-Fraternity Alliance in the JNU elections". Newslaundry. Retrieved 2022-08-02.
- ↑ "Why JNU's Afreen Fatima can't be cowed down by Left or Right". OnManorama. Retrieved 2022-08-02.
- ↑ "AMUSU Election 2018: Women's College Students' Union results declared, Afreen Fatima elected president". Newsd.in (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 4 November 2018. Retrieved 2022-08-02.
- ↑ "कौन हैं आफ़रीन फातिमा, जिनके वायरल वीडियो को संबित पात्रा ने 'ज़हर की खेती' कहा है?". LallanTop - News with most viral and Social Sharing Indian content on the web in Hindi (in Èdè Híńdì). Retrieved 2022-08-02.
- ↑ "CAA stir: Student leaders from Delhi, Uttar Pradesh to be part of 'Inquilab Morcha'". The New Indian Express. 27 December 2019. Retrieved 2022-08-02.
- Pages containing cite templates with deprecated parameters
- CS1 Èdè Gẹ̀ẹ́sì-language sources (en)
- CS1 Èdè Híńdì-language sources (hi)
- Living people
- Indian Muslim activists
- Jawaharlal Nehru University alumni
- Jawaharlal Nehru University Students' Union
- Aligarh Muslim University alumni
- Year of birth missing (living people)