Jump to content

Afro Candy

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Afro Candy
Ọjọ́ìbíJudith Chichi Okpara
12 osu keje, 1971
Iṣẹ́
  • Osere itage
  • Oludari
  • Awose
  • Olugberejade
  • Akorin
  • Akowe orin
Olólùfẹ́Bolton Elumelu Mazagwu (div. 2007)
Àwọn ọmọ2
Websitehttps://afrocanetwork.com/

Afro Candy (tí a tún kọ ní Afrocandy), jẹ́ òṣèré fiimu tí Ìlu Nàìjíríà, olùdarí eré, akọrin, afẹwàṣiṣẹ́ àti òṣèré oníhòhò.[1] Ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àti alákòso ti àwọn Invisible Twins Productions LLC.[2][3]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Afro Candy ní a bí ní Umuduruebo Ugiri-ike, ìjọba agbègbè Ikeduru ti Ìpínlẹ̀ Ímò. Nígbà tó wà lọ́mọdé ní ilé-ìwé ẹlẹ́kọ mẹ́wa, ó ní ẹ̀mí ìṣe fún eré ìtàgé ṣiṣ́e ṣùgbọ́n ó pàdánù rẹ̀ lẹ́hìn títẹ iilé-ìwé gíga. [2] Ó gba oyè-ẹ̀kọ́ ní ìṣàkóso Ọ́fíìsì àti oyè-ẹ̀kọ́ tí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ní ìṣàkóso òwò. Ní àfikún, ó kọ́ ẹ̀kọ́ bi òṣìṣẹ́ ààbò.[4]

Nígbà tí Afrocandy dàwárí nípasẹ̀ ilé-iṣẹ́ afẹwàṣiṣẹ́ King George Models, wọ́n gba níyànjú láti lépa iṣẹ́ òṣèré. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi afẹwàṣiṣẹ́, ó sì farahàn ní àwọn ìkéde fún àwọn ilé-iṣẹ́ bíi Coca-Cola, Nixoderm àti Liberia GSM. Ó tẹ̀ sí tẹlifíṣọ́nù, níbitì ó ti kó àwọn ipa kékeré. Ní ọdún 2004, ó kó àkọ́kọ́ ipa pàtàkì nínu fiimu gẹ́gẹ́ bi Susan nínu fiimu Dangerous Sisters tí Obi Obinali ṣe ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Àwọn ipa rẹ̀ mííràn tún ní Nneoma, ọmọbìrin abúlé kan nínu fiimu End of the game àti Jezebel nínu fiimu Dwelling in Darkness and Sorrow [5]

Ní ọdún 2005, o darapọ̀ mọ́ ọkọ rẹ̀ ní Amẹ́ríkà, eni tí ó ní ọmọ méjì pẹ̀lú. Lẹ́hìn àwọn ọdún méjì tí ó fi gbé níbẹ̀ papọ̀, òun àti ọkọ pínyà. Mazagwu tún ti hàn ní àwọn fiimu bíi Destructive Instinct, How Did I Get Here, Ordeal in Paradise, The Goose That Lays The Golden Eggs àti pé ó ti ṣe àwọn ipa kékeré ní orísirísi sinimá Hollywood.[2] Gẹ́gẹ́bí akọrin, àkọ́kọ́ orin àdákọ rẹ “Somebody Help Me” jẹ́ gbígbé jáde ní ọdún 2009 tí àtẹ̀lé rẹ̀ jẹ́ àkọ́kọ́ àkójọpọ̀ orin rẹ̀, èyítí o ṣe àgbéjáde gbajúgbajà orin aláseyorí rẹ̀ kan "Ikebe Na Moni". Pàápàá ní ọdún 2011, ó ṣe àgbéjáde orin adakọ "Voodoo-Juju Woman".[6]

Yàtọ̀ sí eré ṣíṣe àti orin, Mazagwu n ṣiṣẹ́ bi alámọ̀já koodu.[7][8]

  • Dwelling in Darkness and Sorrow
  • Dangerous Sisters (2004)
  • The Real Player
  • End Of The Game (2004)
  • Between Love
  • Heaven Must Shake
  • My Experience
  • Ghetto Crime
  • Beyond Green Pastures
  • Destructive Instinct
  • Queen of Zamunda

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Polycarp Nwafor (23 April 2017). "Afrocandy turns hardcore porn star". Vanguard. http://www.vanguardngr.com/2017/04/afrocandy-turns-hardcore-porn-star/. Retrieved 14 July 2017. 
  2. 2.0 2.1 2.2 "Maheeda VS Afrocandy: Who is Nigeria’s Queen of Porn?". The Sun. 13 September 2013. http://sunnewsonline.com/new/?p=81512.  ()
  3. Ebirim, Juliet; Aina, Iyabo (26 July 2014). "Every man wants to sleep with me- Afrocandy". Vanguard. Retrieved 3 February 2015. 
  4. "Buzz About Nothing by Judith ‘Afrocandy’ Mazagwu". Nigeriafilms.com. 16 May 2010. Archived from the original on 4 February 2015. Retrieved 3 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "Judith Opara Mazagwu Chichi". Digital Dream Studios. Archived from the original on 4 February 2015. Retrieved 3 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "Afrocandy, Nigeria's Lady Gaga". Thisday. 8 December 2013. Archived from the original on 16 January 2014. https://web.archive.org/web/20140116012616/http://www.thisdaylive.com/articles/afrocandy-nigeria-s-lady-gaga/166132.  ()
  7. "My problem with porn star, Afrocandy – Uche Ogbodo". The Punch. 3 August 2013. Archived from the original on 3 August 2013. https://web.archive.org/web/20130803020822/http://www.punchng.com/feature/my-problem-with-porn-star-afrocandy-uche-ogbodo/.  ()
  8. "Porn Star Afrocandy Says Nigerians Are Fooling". Spyghana. 9 August 2013. Archived from the original on 7 March 2016. Retrieved 3 February 2015.