Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ido-Osi
Agbègbè Ìjoba Ìbílè Ìdó-Òsi jé ìjoba ìbílè ní Ìpínlè Èkìtì tó wà ní Nàìjíríà. Ibùjókò ó rè wà ní ìlú u Ìdó-Òsi.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Ìtókasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ido-Osi | |
---|---|
Country | Nigeria |
State | Ekiti State |
Government | |
• Local Government Chairman and the Head of the Local Government Council | Ayodeji Odutola |
• Local Government Secretary | Akinyemi Ojo |
Time zone | UTC+1 (WAT) |
Ìdó-Òsi wà ní Ìpínlè Èkìtì, l'órílè èdè Nàìjíríà.
Ìjoba ìbílè ná à kún fún àwon ìlú àti ìletò àtètèdáyé tí ó kúndùn-un èkó kíkó, tí wón sì ní ìdáméwà á àkójopò o àwon òmòwé gíga yíká órílè èdè ná à, tó sì tún jé òkan nínú u agbègbè ìjoba Ìpínlè Èkìtì. Ó sún mó àwon agbègbè ìjoba mìíràn bí i Mòbà, Ìjerò, Ìlejeméje àti Adó. Ìjoba Ìbílè yì í ní àwon ìlú wònyì í l'ábé e rè: Àayè, Ìdó, Ùsì, Ayétòrò, Ìlógbò, Òsi, Ìfàkì, Òrìn, Odò-Orà, Òkè-Orà, Ìlógbò, Igbólé, àti àwon ìletò kéréje-kéréje bí i: Ìpólé, Òbajì, Odò Obà-Aládélúsì Òkálàwá, Òkè Esè, Tèmigbolá, Òrìn, Àayè, Ìfisìn, Òrà. Olú ilé işé Ìjoba Ìbílè yì í ni wón fi s'odo si Ìdó Èkìtì, tí ilé ìşàkóso sì wà ní àárín-in ìlú Ìdó àti Ùsì. Láàrín-in àwon akegbé e rè ní Ìpínlè Èkìtì, Ìdó-Òsi ní awon onímò ìwe dunjú l'átàrí i àtètèdá a ìlé ìjosìn àti ilé èkó alákòóbèrè s'ílù ú Ùsì Èkìtì ní kété tí ilé èkó o ti Adó Èkìtì, tí ń şe Olú-Ìlù Ìpínlè ná à, gbin'lè. Lára àwon ènìyàn pàtàkì àti òtòkùnlú ìlú láti Ìjoba Ìbílè ná à lati rí gómìnà Ìpínlè ná à télè rí, [Olúşégun Òní], enití ó wá láti ìlú Ìfàkì.