Jump to content

Agbassa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Agbassa ni oruko okan ninu awon ijoba Urhobo meji to wa ni ijoba ibile Warri South, Delta State Nàìjíríà, ekeji ni Okere-Urhobo[1]. Orukọ 'Agbassa' jẹ ti Ilu Brítánì ti o wa lati orukọ atilẹba rẹ 'AGBARHA', eyiti o tun wa ni lilo. Ọba ti o wa lọwọ ni H.R.M Orhifi Ememoh II.[2]

Agbegbe meje lo wa ti o jẹ ijọba Agbarha (Agbassa):

  1. Otovwodo
  2. Igbudu
  3. Edjeba
  4. Ogunu
  5. Okurode
  6. Oteghele
  7. Ukpokiti

Ni Agbassa, ajọdun Iyerin ni a nṣe lọdọọdun, bakannaa pẹlu Esemor ati Iniemor. Ayeye miran ti a mo si Idju ni won maa n se ni gbogbo odun meji ni gbogbo agbegbe Agbassa ati Okere-Urhobo. Ayeye yii ni won n pe ni Idju Owhurie Festival, ti gbogbo eniyan mo si Agbassa Juju,[3] ti o si da lori ijosin Owurhie, orisa Urhobo.

  1. "Delta : Agbarha Warri set to celebrate ‘Agbassa Juju Festival’". Platinum Post News. 2021-04-03. Retrieved 2022-02-15. 
  2. "Delta CP lauds Agbarha monarch on peace, Edion Hall". Vanguard News. 2016-08-17. Retrieved 2022-02-15. 
  3. "Agbarha people celebrate Agbassa juju festival with eminent personalities in attendance". GbaramatuVoice Newspaper. 2021-04-21. Retrieved 2022-02-15.