Jump to content

Agege stadium

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Pápá-ìṣeré ti Agege
Pápá-ìṣeré Agege, ní ìpínlẹ̀ Èkó

Agege Stadium jẹ́ pápá-ìṣeré gbogbo nìṣe tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó, ní oríllẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ó ní ààyè láti gba ènìyàn ẹgbàajì.[2] Ó jẹ́ ilé fún àwọn egbé agbábọ́ọ̀lù MFM, ẹgbé agbábọ́ọ̀lù ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọjọ-orí wọn ò ju métadínlógún lọ, àti ẹgbé agbábọ́ọ̀lù ọ̀dọ́mọbìnrin ti Dreamstar.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó sọ ọ́ di mímọ̀ pé wọ́n ń ṣe akitiyan láti parí kíkọ́ pápá-ìṣeré náà ní oṣù kejì, ọdún 2022, gẹ́gẹ́ bí ìlwé ìròyìn ṣe fìdíi rẹ̀ lélẹ̀.[1]

Ó jẹ́ ilé fún ẹgbé agbábọ́ọ̀lù ti Nigeria Women Premier League club, ẹgbé agbábọ́ọ̀lù àwọn ọdọ́mọbìrin DreamStar F.C. Ladies, àti ẹgbé agbábọ́ọ̀lù Nigeria Premier League Club MFM, tí ó ṣoju orílẹ̀-èdè náà ní eré-ìfẹsẹ̀wọnsè ti CAF ní ọdún 2017 pẹ̀lú Plateau United.[3]

Àwọn ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]