Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ní Nàìjíríà


Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ní Nàìjíríà jẹ́ iṣẹ́ kan pàtàkì láàrín àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ẹ̀ka yí sì jẹ́ igun pàtàkì nínú ètò ọrọ̀-ajé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó kò ìdá márùndínlógójì tí ó pawó wọlé sí àpò Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí àbọ̀ ìwádí nínú ètò ọrọ̀-ajé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ọdún 2020. [1][2] Àjọ FAO,[3] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé iṣẹ́ àgbẹ̀ ni orísun àti ìpìlẹ̀ ọrọ̀-ajé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí ṣáájú kí epo rọ̀bì ó tó rọ́pò rẹ̀, síbẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ó ń fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ní iṣẹ́ àti ounjẹ tí ó sì ń pawó rẹpẹtẹ sápò ìjọba.[1][4][5][6][6] Iṣẹ́ àgbẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni a lè pín sí orígun mẹ́rin , àwọn ni: àgbẹ̀ ọlọ́gbìn, àgbẹ̀ ọlọ́sìn ẹran, igi gbígbìn, àti àgbẹ̀ ọ́sìn ẹja. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní saare ilẹ̀ tí ó tó mẹ́jọléláàdọ́rin mílíọ́nù tí eọ́n lè fi ṣe ọ̀gbìn,[3] ní èyí tí mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n mílíọ́nù nínú ilẹ̀ yí jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára púpọ̀ fún ohun ọ̀gbìn èyíkéyí. ,[7] ìdá mẹ́fà ó lé marùn mílíọ́nù ninu ilẹ̀ (6.5 million) náà ni wọ́n ń lò fún àwọn ohun ọ̀gbìn tó ma ń hù fúnra wọn nígbà tí ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ̀n mílíọ́nù ilẹ̀ tó kù kàn ń hu koríko lásán ni.[8]
Àwọn ohun ọ̀gbìn tí wọ́n saábà ma ń gbìn ju ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni àgbàdo, ẹ̀gẹ́, ọkà bàbà, ẹ̀pà, ẹ̀wà ,iṣu àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Iye ìdílé tí wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ ni wọ́n tó ìdá àádóje nínú ọgọ́rùn ni wọ́n ń ṣe àgbẹ̀ ọ̀gbìn ohun jíjẹ. Ní apá ìlà Oòrùn, iye mọ́lèbí tí wọ́n yanṣẹ́ àgbẹ̀ esin ẹja láàyò ni wọ́n jẹ́ ìdá mẹ́tàlélógóje nínú ọgọ́rùn un, nígbà tí ìdá mọ́kàndíláàdójé ó lé mẹ́t mọ̀lẹ́bí láti apá aríwá yan iṣẹ́ àgbẹ̀ ọ̀sìn ẹran láàyò.[9]
Ẹ̀ka iṣẹ́ àgbẹ̀ gbèrú gidi ni ọdún 2019 pẹ̀lú ìdá 14.88% ṣáájú ajàkálẹ̀ àrùn COVID-19 tó wọlé tí iṣẹ́ àgbẹ̀ sì pawó tí ó tó ìdá 29.25% nínú gbogbo owó tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pa wọlé. [10] Bákan náà ni ó tún rí ní áàárín oṣù kínní sí oṣù kẹta ọdún 2021.[3][11][12][13][14] Ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn iṣẹ́ àgbẹ̀ ń la àwọn àtúntò àti àtúnṣe oríṣiríṣi kọjá pẹ́lú bí ìjọba ṣe ń ṣe ìkúnpá fún àwọn àgbẹ̀ aládàá ńlá, àti àwọn àgbẹ̀ kékèké gbogbo.[15] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wipé ẹsẹ̀ ló ń dààmú Ọlọ́huntóówò, Ọlọ́hntóówò kìí ṣe ajákájá; àwọn ohun tí ó lè mú ìfàsẹ́yìn bá ìdàgbà-sókè àti ìgbèrú iṣuẹ́ àgbẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà:
- àìrọ̀ òjò déédé,
- àìmú oko àkùrọ̀ lọ́kùnkúndùn,
- àìsí ìrànwọ́ owó fún àwọn àgbẹ̀ bí ó ti yẹ.
- àìtó àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba àti àjọ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ìwádí nípa ohun ọ̀gbìn.
- àìsí ìpèsè ajílẹ̀ tó jííre tàbí àìlè pín in dọ́gba láàrín àwọn àgbẹ̀,
- Àìsí ojú ọ̀nà tó jà geere dé inú ìgbẹ́ tí wọ́n ti ń dáko.
- ọ̀wọ́n gógó owó epo àti bbl.
- àìtó oògùn apakòkòrò ú yányán tó fún àwọn àgbẹ̀.
Bákan náà ni àyípadà ojú-ọjọ́, tí ó ń mú kí òjò rọ̀ láraọ̀jù tàbí kí ó má rọ̀ lásìkò ń ṣe ìpalára fún iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ìgbèrú rẹ̀ pẹ̀lú.[16] [17]
Ìsọ̀rí iṣẹ́ àgbẹ̀ ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àgbẹ̀ ọlọ́sìn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Èyí jẹ́ ọ̀nà iṣẹ́ àgbẹ̀ tí an ṣe láti fi sin àwọn ẹranko tí wọ́n lè bami gbélé, yálà ẹrako abìyẹ́ ni tàbí òmíràn fún ìpèsè iṣẹ́ òjòọ́ àti ohun jíjẹ bí ẹran àti wàrà.

Àgbẹ̀ ọláọ́sìn jẹ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ tí ó gbámú gidi ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mu gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 2017, iye àwọn tí wọ́n ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọláọ́sìn adìyẹ ni wọ́n ju ọgọ́rin mílíọ́nù ènìyàn lọ nígbà tí àwọn ọláọ́sìn ewúrẹ́ jẹ́ mílíọ́nù mẹ́tàlélógójì ó lé ẹ̀sún mẹ́rin, bákan náà ni àwọn tí wọ́n ń sin àgùtan jẹ́ mílíọ́nù méjìdínlógún ó lé ẹ̀sún mẹ́rin, àwọn tí wọ́n ń si màlúù jẹ́ mílíọ́nù méje ó lé ẹ̀sún márùn un, àwọn tí wọ́n ń sin ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ mílíọ́nù kan ó lé ẹ̀sún mẹ́rin. [18] Livestock farming is about 5% of Nigeria's gross domestic product and 17% of its agricultural gross domestic product.[19] Iṣẹ́ àgbẹ̀ ọ́lọ́sìn ẹran ni ó bójúto ìpèsè ẹran fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó sì ń pèsè iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú.[2] Iṣẹ́ àgbẹ̀ ẹran sínsìn ni ìyàtọ̀ àti àyípadà ti dé bá látàrí ìgbèrú tí ó ń déba ilé kíkọ́ àti ìdàgbà-sókè ilé-iṣẹ́ ńlá ńlá lóríṣirí .[20][21]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Iwena, O. A. (Ed.) (2017). Essential Agricultural Science for Senior Secondary School. Tonad Publishers.
- ↑ 1.0 1.1 "10 Roles of Agriculture in Nigeria Economic Development". InfoGuideNigeria.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-12-06. Retrieved 2022-12-17.
- ↑ 2.0 2.1 "Employment in agriculture (% of total employment) (modelled ILO estimate) - Nigeria". Work Bank Data. World Bank. 2020. Retrieved 24 November 2020.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 "Nigeria at a glance". www.fao.org. Retrieved 2020-11-24.
- ↑ "Nigeria: agriculture sector share in employment". Statista (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-17.
- ↑ Adeite, Adedotun (2022-04-14). "Agriculture in Nigeria: 7 Interesting Facts & Statistics". Babban Gona (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-16.
- ↑ 6.0 6.1 jlukmon (2022-11-18). "List 10 Importance of Agriculture in Nigeria.". About Nigerians (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-16.
- ↑ "Topic: Agriculture in Nigeria". Statista (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-17.
- ↑ cycles, This text provides general information Statista assumes no liability for the information given being complete or correct Due to varying update; Text, Statistics Can Display More up-to-Date Data Than Referenced in the. "Topic: Agriculture in Nigeria". Statista (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-07-30.
- ↑ "Topic: Agriculture in Nigeria". Statista (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-08-12.
- ↑ Nigerian Gross Domestic Product Report Q3 2019, National Bureau of Statistics. https://www.nigerianstat.gov.ng/pdfuploads/GDP_Report_Q3_2019.pdf
- ↑ "Agriculture contributes 23% to GDP in 2022 – Minister". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-09-15. Archived from the original on 2022-12-16. Retrieved 2022-12-16.
- ↑ Isaac, Nkechi (2022-09-16). "Agriculture Contributed 23.3% To National GDP In Q2 – Abubakar". Science Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-16.
- ↑ "Agriculture contributes 23% to GDP in 2022 — Minister". NewsWireNGR (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-09-15. Retrieved 2022-12-16.
- ↑ Ukpe, William (2022-08-26). "GDP: Nigeria's Agriculture sector grows by 1.20% in Q2 2022". Nairametrics (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-16.
- ↑ Olomola Ade S. (2007) “Strategies for Managing the Opportunities and Challenges of the Current Agricultural Commodity Booms in SSA” in Seminar Papers on Managing Commodity Booms in Sub-Saharan (:Africa: A Publication of the AERC Senior Policy Seminar IX. African Economic Research Consortium (AERC), Nairobi, Kenya
- ↑ Kurukulasuriya, Pradeep (2013). "Climate Change and Agriculture: A Review of Impacts and Adaptations". Climate Change Series 91 Environment Department Papers, World Bank, Washington, D.C.
- ↑ Olayide, Olawale Emmanuel; Tetteh, Isaac Kow; Popoola, Labode (December 2016). "Differential impacts of rainfall and irrigation on agricultural production in Nigeria: Any lessons for climate-smart agriculture?". Agricultural Water Management 178: 30–36. Bibcode 2016AgWM..178...30O. doi:10.1016/j.agwat.2016.08.034. ISSN 0378-3774.
- ↑ "Livestock Production in Nigeria - A thriving Industry". One Health and Development Initiative (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-10-07. Retrieved 2023-08-24.
- ↑ "Nigeria". www.ilri.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-08-07. Retrieved 2023-08-24.
- ↑ Amadou, Hamadoun; Dossa, Luc Hippolyte; Lompo, Désiré Jean-Pascal; Abdulkadir, Aisha; Schlecht, Eva (2012-03-20). "A comparison between urban livestock production strategies in Burkina Faso, Mali and Nigeria in West Africa". Tropical Animal Health and Production 44 (7): 1631–1642. doi:10.1007/s11250-012-0118-0. ISSN 0049-4747. PMC 3433665. PMID 22430479. http://dx.doi.org/10.1007/s11250-012-0118-0.
- ↑ Aribido, S O; Bolorunduro, B I (2004-12-13). "Implications of Ecological Changes on Sustainable Livestock Production in the Lake Chad Basin of Nigeria". Tropical Journal of Animal Science 6 (2). doi:10.4314/tjas.v6i2.31080. ISSN 1119-4308. http://dx.doi.org/10.4314/tjas.v6i2.31080.