Ainehi Edoro

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Ainehi Edoro ni wọ́n bí ní (December 11), Ó jẹ́ ̀ònkọ̀wé ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni olùdásílẹ̀ àti olùgbéjáde ìwé Brittle Paper. Ó tụ́n jẹ́ igbá-kejì ọ̀jọ̀gbọ́n "professor of Global Black literature" ní ilé ẹ̀kọ́ àgbà University of Wisconsin-Madison.[1]

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lásìkò tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ láti gboyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ (Doctorate) ní ilé ẹ̀kọ́ àgbà Duke University, Edoro dá ìwé ọlọsọ̀́ọ̀sẹ̀ Brittle Paper kalẹ̀.[2] Ní́ June 2018, ó tún jẹ igbákejì ọ̀́jọ̀gbọ́n ní ilé ẹ̀kọ́ àgbà Marquette University. Iṣẹ́ àtinúdá Edoro dá lórí àpilẹ̀kọ lítíréṣọ̀ léréfèé ilẹ̀ Adùláwọ̀.[3]

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀  àti àmì ẹ̀yẹ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Edoro dá Brittle Paper sílẹ̀ ní ọdún 2010. Edoro ṣàlàyé wípé: Brittle paper  " Jíjẹ̣́lẹgẹ́ tí ìwé àtẹ̀jáde ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ òun jẹ́ ẹlẹgẹ́ gẹ́gẹ́ bí orụ́kọ rè Brittle ni ó ń ṣàfihàn bí iṣẹ́ ọnà Lít́iréṣọ̀ śe dùn tó tí ó sì ń dáni lára yá sí lórí ẹ̀rọ ayé-lu-jára ... Nígba tí "Brittle Paper" dá lórí àkó-jọ-pọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ tí ó wà lórí àwọn fọ́nrán òrò tó ń lọ lórí aýe-lu-jára."[4] Gẹ́gẹ̣́ bí ó ṣe sọ, ṣíṣe àfihàn àwọn ìmọ̀ àti iṣ̣é ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ òun ni ó ṣokùn fa bi òun ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọ̀rọ̀ to ń ló ní orí ẹ̀rọ ayé-lu-jára, lẹ́yín èyí ni òun ri wípé ó ṣe pàtàkì kí òun ó tún àwọn "àpilẹ̀kọ àti àṣà ilẹ̀ Adúláwọ̀" jí dìde".[5] She was listed as one of the five most influential Nigerian women in 2016 by Guardian.[6]

Awon Itoka si[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]