Akanu Ibiam

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Sir Francis Akanu Ibiam

Governor of Eastern Region, Nigeria
In office
15 December 1960 – 16 January 1966
AsíwájúSir Robert Stapledon
Arọ́pòChukwuemeka Odumegwu Ojukwu
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí29 November 1906
Unwana, Afikpo North, Ebonyi State, Southern Nigeria Protectorate
(now Nigeria)
Aláìsí1 July 1995 (aged 88)

Alàgbà Francis Akanu Ibiam tí a bí ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 1906, tí ó sì kú ní ọjọ́ kìíní oṣù keje ọdún 1995 jẹ́ ẹni tó ń polongo ìlera pípé tí wọ́n sì yàn gẹ́gẹ́ bíi gómìnà apá ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní oṣù kejìlá ọdún 1960 títí wọ oṣù kìíní ọdún 1966.[1] Láti ọdún 1919 wọ ọdún 1951, Francis Ibiam ni a mọ̀ ọ́ sí àmọ́ ó di Alàgbà Francis Ibiam ní ọdún 1951 títí wọ ọdún 1967.

Ìgbésí ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Ibiam ní ìlú Unwana, ìpínlẹ̀ Ebonyi ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá. Ó jẹ́ ọmọkùnrin kejì tí olóyè Ibiam Aka tí ó jẹ́ adarí ìlú Unwana bí.[2] Ibiam padà di adarí ìlú Unwana, ó di Eze ogo Isiala I ti Ìlú Unwana àti Osuji ti Uburu. Ó lọ sí Hope Waddell Training Institute ní ìpínlẹ̀ Calabar àti King's College ní ìpínlẹ̀ Èkó kí ó tó wá lọ University of St. Andrews, tí ó sì jáde pẹ̀lú ìwé-ẹ̀rí nínú ètò ìlera ní ọdún 1934. A gbà á ṣíṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi apolongo ètò ìlera sínú ilé ìjọsìn tí ìlú Scotland.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Sir Francis Akanu Ibiam (Profile)". Afikpo Online. 1906-11-29. Retrieved 2020-01-13. 
  2. Hughes Oliphant Old (2010). The Reading and Preaching of the Scriptures in the Worship of the Christian Church, Volume 7: Our Own Time. Wm. B. Eerdmans Publishing. pp. 212–213. ISBN 0-8028-1771-8.