Akbar Shah Khan Najibabadi
Akbar Shah Khan Najibabadi (1875 – ọjọ kẹwa May 1938) jẹ ónimọ itan sunni ẹ̀lẹsin musulumi ti ilẹ̀ india to kọ Tarikh-e-Islam ni iwọn didun mẹta[1].
Itan Ìgbèsi Àye Akbar Shah Khan Najibabadi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Najibabadi ni wọn bi ni ọdun 1875 ni Najibabad, Bijnor, United Provinces ti British India. Arakunrin naa bẹrẹ iṣẹ̀ òlukọ ni ilè iwè ààrin Najibabad Middle ni ọdun 1897 lẹyin naa lo kọ Persian ni ilè iwè to ga ni Najibabad[2].
Ni ọdun 1906 ati 1914, Akbar duro si Qadian to si darapọmọ ijọ Ahmadi. O sumọ Hakeem Noor-ud-Din, Adèlè fun Mirza Ghulam Ahmad, nibi to ti kọ itan igbesi ayè rẹ pẹ̀lu akọle Mirqat al-Yaqin fi Hayati Nur al-Din ni iwọ didun meji, eyi ti ko ṣè tẹjade to ri iyipada si Sunni ẹsin islam[3]. Ni Qadian, Najibabadi ni superintendent fun Madrasa Nur al-Islam ti Ahmad fun ọdun mààrun.
Lẹyin iku Noor-ud-Din, Najibabadi dojukọ Mirza Basheer-ud-Din Mahmood Ahmad ṣùgbọn ko gbà fun. Ni ààrin ọdun 1915, Najibabadi darapọ mọ ijọ Lahori ti Ahmadi[3].Lẹyin igba diẹ̀, lo yipada si ijọ ti Sunni ẹ̀sin islam.
Ni ọdun 1916, Najibabadi bẹrẹ iwe akọsilẹ óṣoṣu ti akọlè rẹ jẹ Ibrat,olùkópa iwè naa ni Abdul Halim Sharar ati Aslam Jairajpuri. Muhammad Iqbal tẹ iwe órin inu rẹ jade. Arakunrin naa bojutó Zamindar fun ọdun kan nigba ti Zafar Ali Khan wa ni atimọlè[4] to si tun kọwe fun Mansoor, Lahore.
Najibabadi ni aisan inu ni óṣu June ọdun 1937 to do ja si iku rẹ ni ọjọ kẹwa, óṣu May ni ọdun 1938[2].
Awọn Ìṣẹ rẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Tarikh-e-Islam (iwọ didun mẹ̀ta)
- Tarikh-e-Najibabad[5]
- Jang-e-Angura
- Nawab Ameer Khan
- Gaay awr Uski Tarikhi Azmat
- Ved awr Uski Qudamat
- Hindu awr MusalmanoN ka ittefaq
- Aaina Haqeeqat Numa.
Awọn Itọkasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Masood Alam Falahi (in Urdu). Hindustan mai Zat-Pat awr Musalman (May 2007 ed.). New Delhi: Al-Qazi Publishers. p. 162.
- ↑ 2.0 2.1 Akbar Shah Najibabadi. "Biographical sketch by Javed al-Hasan Siddiqi" (in Urdu). Qawl-e-Haq (2016 ed.). New Delhi: Areeb Publications. pp. 15–20.
- ↑ 3.0 3.1 Dr Umar Farooq. "مولانا اکبر شاہ نجیب آبادی کا قادیانیت سے تعلق واِنقطاع" [Akbar Shah Najibabadi's journey of Faith]. ahrar.org.pk (in Urdu). Majlis-e-Ahrar-ul-Islam. Retrieved 24 July 2020.
- ↑ "Maulana Zafar Ali Khan (1873-1956)". Journalism Pakistan. 2021-04-09. Archived from the original on 2018-07-05. Retrieved 2023-09-13.
- ↑ Najeebabadi, Akbar Shah (2015-08-24). "Tareekh E Islam Complete Volume : Akbar Shah Najeebabadi : Free Download, Borrow, and Streaming : Internet Archive". Internet Archive. Retrieved 2023-09-13.