Akinsola Olusegun Faluyi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Akinsola Olusegun Faluyi
President of the Nigerian Society of Engineers (NSE)
In office
1985–1986
President of the Council for the Regulation of Engineering (COREN)
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí13 Oṣù Kọkànlá 1934 (1934-11-13) (ọmọ ọdún 89)

Akinsola Olusegun Faluyi (ẹni tí wọ́n bí ní ọjọ́ 13 oṣù kọkànlá ọdún 1934) jẹ́ òṣìṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ààrẹ́ COREN tẹ́lẹ̀ rí ,ikọ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1]

Ìgbésí ayé àti isẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orúkọ mìíràn tí ó ń jẹ́ ni "Olusegun" tí ògbufọ̀ rẹ jẹ́ "God is Victorious" ní èdè Gẹ̀ẹ́sì[2] ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírì Ibadan Boys High School, ìpínlẹ̀Oyo, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní bi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí (WASC) tí ó sì tẹ̀síwájú lọ sí fáfitì ní bi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí fáfitì àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ (B.Eng) in Mechanical engineering (1953-1985).ó dara pọ̀ mọ́ òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn ilé ìwé fáfitì ìlú Ìbàdàn gẹ́gẹ́ bíi onímọ̀ ẹ̀rọ ní ọdún 1960.[3] Ó kúrò ní ilé ìwòsàn lẹ́yìn ọdún méjì gẹ́gẹ́ bíi onímọ̀ ẹ̀rọ ní ilé ìwòsàn, ó dara pọ̀ mọ́ ilé ìwòsàn ìlú Èkó ní ọdún 1962,gẹ́gẹ́ bíi ọ̀gá àgbà onímọ̀ ẹ̀rọ. Ní ọdún 1975 ó ẹ̀yìn tì ní ilé ìwòsàn fáfitì Èkó láti dara pọ̀ mọ́ Edisson Group and partners.[4] Ọ́ di ààrẹ́ àpapọ̀ àwọn onímọọ̀ ẹ̀rọ ní 2985 ó sì sìn wọ́n fún ọdún kan, tí sáà náà parí lẹ́yìn ọdún kan, ṣáá tí ó parí ní ọdún 1986.[5] Ó padà di Ààrẹ COREN.[6] Ó sì sì wọ́n gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ́ Nigerian Academy of Engineering.[7]

Àwọn ẹgbẹ́ tó darapọ̀ mọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Fellow, Nigerian Society of Engineers (NSE)
  • Fellow, Nigerian Academy of Engineering

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Faluyi, A. O. (1993). The Making of an Engineer. https://books.google.com/books?id=OvcaHQAACAAJ. 
  2. "Olusegun". Nigerian Name. 
  3. RapidxHTML. "The Nigeria Academy of Engineering :: promoting excellence in technology and engineering training and practice to ensure the technological growth and economic development of Nigeria". Archived from the original on 2016-12-16. Retrieved 2024-02-08. 
  4. "BiafraNigeriaWorld: The Authority on BiafraNigeria". 
  5. "NSE Membership Portal". Archived from the original on 2014-12-05.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "Reference at allafrica.com". 
  7. "BNW News: BiafraNigeriaWorld News: Biafra Nigeria World is the Authority on BiafraNigeria, Biafra NigeriaWorld".