Aláàfin Àmọ̀dó
Aláàfin Àmọ̀dó jẹ́ ọba Àlááfín Ọ̀yọ́ ní ọdún 1830 sí 1833. [1]. Ọdún mẹ́ta péré ló lò lórí ìtẹ́ ọba. Ní ìbẹ̀rẹ̀, ó jẹ́ ọba tí kò ní akíkanjú, ṣùgbọ́n nígbà tó yá, ó fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọba ọlọ́gbọ́n àti ẹni tí ẹnu rẹ̀ ká ìlú. Ó jọba nígbà tí wàhálà àti ìrúkèrúdò wà ní ìlú. Èyí ni àsìkò tí àwọn Fulani ń dá àlàáfíà ilẹ̀ Yorùbá láàmú. Lásìkò yìí kò sí àwọn ọba tí wọn wà lábẹ́ Ọ̀yọ́ tí wọn bọ̀wọ̀ fún Aláàfin, kódà wọn kò san ìṣákọ́lẹ̀. Ó kàn jẹ́ ọba Ọ̀yọ́ lásán ni nígbà tìrẹ.
Lásìkò rẹ̀ ni àwọn Ìlọrin kógun ja Ọ̀yọ́, ṣùgbọ́n wọn kò pa Ọ̀yọ́ run. Nígbà tí ó ṣe, Amódò parí ìjà láàárín àwọn olóyè Ọ̀yọ́ tí wọ́n ti kẹ̀yìn wọn sí Ọ̀yọ́ nígbà náà. Wọ́n wá parapọ̀ gbé àwọn jagunjagun dìde láti bá Ìlọrin jà ṣùgbọ́n Ẹdun tí Gbọ̀ngán, tí ó jẹ́ Ààrẹ Kakanfò gbàbọ̀dè wọn, wọn lé àwọn jagunjagun wọn lọ. Leyin náà, àwọn Ìlọrin kógun ja Gbọ̀ngán, wọn sì borí Ẹdun. Lẹ́yìn tí wọn jagun borí Kakanfò àti Oníkòyí, tí kò sì sí agbára kankan lọ́wọ́ Àlááfín mọ́, nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun Ilorin gba púpọ̀ nínú ilẹ̀ àwọn Yorùbá ti wọn wà ní apá òkè-oya. Lẹ́yìn èyí, wọn tún dojú ìjà kọ àwọn Ìjẹ̀sà, ṣùgbọ́n àwọn Ìjẹ̀sà kò gbà lẹ́rọ̀ pẹ̀lú wọn. Lásìkò yìí ni iwonba tó kú nínú àwọn ọmọ ogun Ọ̀yọ́ àti Ẹ̀gbá bẹ̀rẹ̀ sí dojú ogun kọ àwọn Ìjẹ̀bú, nítorí ipa tí wọn kó nínú ogun Òwu. Àsìkò yìí ni ogun bẹ̀rẹ̀ sí ní jà káàkiri ilẹ̀ [[Yorùbá [2]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Alaafin of Oyo: Wo Alàáfin 43 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀ ṣáajú Lamide Adeyemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wàjà". BBC News Yorùbá. 2022-04-24. Retrieved 2024-06-18.
- ↑ Akinbode, Ayomide (2022-04-25). "CHRONOLOGICAL HISTORY OF THE ALAAFIN OF OYO EMPIRE (c.1210 to date)". Afro-Global Education Deliveries. Retrieved 2024-06-18.