Jump to content

Aláàfin Ojigi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ojigi fìgbà kan jẹ́ Aláàfin ti ìlú Ọ̀yọ́ láti ọdún 1724 wọ ọdún 1735.[1]

Ìṣèjọba Aláàfin Ojigi ni a lè pè ní àsìkò ti Ọ̀yọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní jagun-ṣẹ́gun. Àsìkò ìjọba rẹ̀ ni ìlú yìí ní ọ̀pọ̀ àṣeyọrí, tí ó sì ní àtilẹ́yìn àwọn olóyè pàtàkì. Ojigi ṣe àfikún àwọn ológun láti dojú-ìjà kọ ìlú Dahomey lẹ́yìn tí ó gba ìrànwọ́ àwọn ìlú mìíràn, èyí ti Ọba Dahomey tí í ṣe Agaja máa ń halẹ̀ mọ́.

Ní ọdún 1730, àwọn ará ìlú Dahomey gbà láti máa ṣan ìṣakọọ́lẹ̀ ọdọọdún fún àwọn ará Ọ̀yọ́, tí í ṣe ọkùnrin ogóji, obìnrin, ìbọn, àti irinwó owó-ẹyọ.[2]

Ojigi kọ̀ láti kọ́ ọmọ rẹ̀, ìyẹn Àrẹ̀mọ sọ́nà tó tọ́, èyí sì mu kí àwọn Ọ̀yọ́ Mèsì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.[3] Lẹ́yìn ikú rẹ̀, Àrẹ̀mọ ní láti pa ara rẹ̀.[4]

Aláàfin Gberu ló jẹ oyè Aláàfin lẹ́yìn Ojigi.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Alaafin Ojigi Archives". GB Journals. 2021-06-22. Retrieved 2024-06-17. 
  2. Robert Smith (1969). Kingdoms of the Yoruba. Methuen & Co. pp. 43, 47, 49. https://archive.org/details/kingdomsofyoruba0000smit. 
  3. Law, R. C. C. (1971). "The constitutional troubles of Ọyọ in the eighteenth century". The Journal of African History 12 (1): 25–44. doi:10.1017/s0021853700000050. ISSN 0021-8537. 
  4. Smith, Robert (1988). Kingdoms of the Yoruba. Currey. ISBN 0852550286. OCLC 813599097.