Al-Kifah
Al-Kifah (Lárúbáwá: Àdàkọ:Nq) jẹ́ ìwé èdè Lárúbáwá tí wọ́n tẹ̀ jáde lóṣooṣù tí ó sì jẹ́ agbẹnu sọ fún Jamiat Ulema-e-Hind.[1] Lẹ́yìn àkókò òmìnira, àwọn adarí ti Jamiat Ulema-i-Hind pinnu láti ṣe àgbéjáde ìwé náà fún ìdàgbàsókè ìfọkànsìn àti ìfojúsùn ti Jamiat ní àwọn orílẹ̀ èdè Gulf. Fún ìdí yìí, ìwé olóójú mẹ́jọ ni wọ́n tẹ̀ jáde ní Delhi ni oṣù kìíní ọdún 1973; Altafur Rahman Azmi ni ó ṣe olóótù.[2] Wahiduzzaman Kairanawi kó ipá tó ṣe pàtàkì nínú àtéjáde ìwé náà. Fún ìdí kan, ní oṣù Kejìlá, ọdún 1987 ni ìgbà tó kẹ́yìn tí wọ́n tẹ ìwé náà jáde, ṣùgbọ́n ó kó ipá tó ṣe pàtàkì nínú ìdàgbàsókè èdè Lárúbáwá ní orílẹ̀ èdè India.[3] Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn olóótù Al-Da'i ni olóótù Al-Kifah, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Darul Uloom Deoband kò ní ọ̀rọ̀ àjọ́sọ kankan tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.[4]
Àwọn Ìfọkànsìn àti Àfojúsùn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ìfọkànsìn àti àfojúsùn:[5]
- Láti ṣe àfihàn àwọn ìfọkànsìn ti Jamiat-e-Ulama-e-Hind ní orílẹ̀ èdè àwọn Lárúbáwá.
- Láti ṣe àtẹ́jáde àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wáyé níbi láti ojú-ìwòye ti Jamiat.
- Láti ṣe àtẹ́jáde àwọn ìwé lórí ẹ̀sìn Mùsùlùmí.
- Fún ìgbìyànjú láti gbé èdè Lárúbáwá àti lítíréṣọ̀ orílẹ̀ èdè India sókè.
Àwọn Ìtọ́kási
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn Àlàyé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Àdàkọ:Cite thesis
- ↑ Ayub Nadwi, Dr. (1998) (in en). Origin and Development of Arabic Journalism in India. J&K, India: Darul Hijrah. pp. 175–176.
- ↑ Khan, Salimur Rahman (2007) (in en). Evolution & History of Islamic Journalism in India. New Delhi, India: Kitab Bhawan. pp. 398.
- ↑ Àdàkọ:Cite thesis
- ↑ Àdàkọ:Cite thesis