Alexander Abiodun Adebayo Bada
Alexander Abiodun Adebayo Bada (ọjọ́ ìbí ní ọjọ́ kẹrin osu Kejìlá ọdún 1930- ojọ́ kẹjọ ọdún 2000)[1] jẹ́ Olùsọ́-àgùtàn Kejì tí ilé ìjósìn tí amò sí Celestial Church of Christ, (CCC), tí ó tẹ̀lẹ́ Olùdásílẹ̀ ilé ìjósìn náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Samuel Biléhou Joseph Oschoffa ní Oṣù Kejìlá ọdún 1985.[2]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Bàdà ní ọjọ́ kẹrin osu Kejìlá ọdún 1930. Baba rẹ̀ jẹ́ baálé tí ìlú Àgọ́-Ọba ni agbègbè kàn ní Abeokuta, ó sì jẹ́ Olórí Ìjọ Áfíríkà ní Eréko, ní ìpínlè Èkó àti pé Bada dàgbà nínú ṣọ́ọ̀ṣì yìí. Bàdà losí ilé Alákọ́bẹ̀rẹ̀ Àti John ní Ìlorò ní iléṣà ní 1935 sí 1943, o tún lọsí ilé ẹ̀kọ́ gírámà láti ọdún 1943 sí 1949. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe ní Nigerian Breweries tí wọn ń ṣe ọtí ni ọdún 1950, tí wọ́n sì ní ìgbéga sí alábojútó ìṣàkóso ọjà ní ọdún 1952.[2]
Ìṣe ilé ìjósìn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní àárín ọdún 1952,Ó pàdé Superior Ajíhìnrere S. O. Ajáńlekòkò ti CCC, ẹnití ó ní ipa púpọ̀ lórí rẹ̀. Ó fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ láti ṣẹṣẹ Olúwa kíkún fún ìjọ, ó sì di Àgbààgbà ní 1954, Adarí ní ọdún 1955, tí o sì dì Adarí Àgbà ní oṣù Kejìlá ọdún 1960 àti ajíhìnrere ní ọdún 1964.
Ó di Ajíhìnrere Àgbà ní ọjọ́ kerìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1972, àti pé ní ojú karúndílógbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1980 Ajíhìnrere tí ó ga jùlọ, òun sì ní àkọkọ́ tí ó dé ipò náà, èyí tí ó túmọ sí pé ipò rẹ súńmọ́ Ipò tí Pastor Samuel Ọ̀sọfà wà.[2]
Nígbà tí Osofa kú ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹsán, ọdún 1985 nínú ìṣẹ̀lẹ ìjàmbá ọkọ́ láì sí arópò kan kan tàbí ọmọ tí yóò jogún rẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọlẹyìn rẹ̀ ní en fi dí olórí, èyí tí ó yọrí sí ìjà òfin tí ó wáyé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.
Sibẹsibẹ, Ìgbimọ Alàkóso àti àwọn Olùfọkàntàn kéde pé Bàdà ni Olùsọ́-àgùtàn tuntun àti aṣáájú ẹ̀míi ní àpéjọ ọdọọdún CCC ní ọjọ́ karúdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ọdún 1985. Wøn fí sí orí ipò náà ní ọjọ́ karúdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ọdún 1985 ní orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti CCC ní Ìmẹ̀kọ ní ìpínlè Ògùn, ní orílé èdè Nàìjíríà, ó sì ṣe aṣáájú ìjọ náà fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó tẹ̀ lé e.[2]
Bàdà jáde láyé ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹsán ọdún 2000 ni ilé ìwòsan Greenwich ní London. Lèyìn tí wọn gbé wá sí orílè èdè Nàìjíríà fún ayẹyẹ ìsìnkú ní oṣù kokàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹsàn-án ọdún 2000 ní ìlú Celestial ní Ìmẹ̀kọ.
Gómìnà Olúsẹ́gun Ọ̀sobà ló sojú Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ níbi ayẹyẹ ìsìnkú náà.[3] Àwọn ìyàwó, àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ-ọmọ ní Bàdà filẹ́ lọ.[2] Philip Hunsu Ajose] lọ́ rọ́pò rẹ̀, ẹní tí a yàn sípò aṣáájú Ìjọ ní ọjọ́ Kejì, Oṣù Kẹwàá ọdún 2000.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Adogame, Afe U. (2002). "Bada, Alexander Adebayo Abiodun". In Stanley M. Burgess. The new international dictionary of Pentecostal and charismatic movements. (Rev. and expanded ed.). Grand Rapids, Mich.: Zondervan Pub. House. p. 351. ISBN 0310224810.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 "Revd Alexandra Abiodun Bada". Ilesa Grammar School. Archived from the original on 2011-08-09. Retrieved 2011-06-12. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Celestial signs lighten Bada's burial". The Comet. Celestial Church. October 2, 2000. Archived from the original on 2011-10-01. Retrieved 2011-06-12. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Rt .Rev. P.H. Ajose Biography". Celestial Church. Retrieved 2011-06-12.