Jump to content

Allen Onyema

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Allen Ifechukwu Onyema (tí wọ́n bí ní ọdún 1964) jẹ́ olùṣòwò àti agbẹjọ́rọ̀ ọmọ ìpínlẹ̀ Anambra lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni Alága àti olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ ọkọ̀ Òfurufú tí wọ́n ń pè ni Air Peace airlines. Ilé ìṣe ọkọ̀ òfuurufú rẹ̀ ló ṣètò gbígbé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́fẹ̀ẹ́ láti South Africa padà sí ilé nígbà tí àwọn ọmọ South Africa bẹ̀rẹ̀ sí ní pa wọ́n látàrí ija-aòfájòjì lórílẹ̀ èdè náà. [1]

Ìgbà èwe àti aáyán ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lóòótọ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Anambra ni Allen Onyema ṣùgbọ́n wọ́n bí i sí ìlú Benin ní ìpínlẹ̀ Edó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ àkọ́bí ọmọ nínú àwọn ọmọ mẹ́sàn-án fún àwọn òbí rẹ̀. Orúkọ wọn ní Michael àti Helen Omyema. Ní ìlú Bíní àti Warri ni ó kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀. Ó tẹ̀ síwájú ní ilé ìwé gírámà ní Orhobo College, St. Anthony Secondary school, Azia, Effurum àti Government College, Ughelli. Ó kàwé gboyè dìgírì lórí ìmọ̀ òfin ní Ifáfitì ìjọba àpapò ní ìpínlẹ̀ ní ìlú Ìbàdàn (University of Ìbàdàn lọ́dún 1987 kí ó tó lọ sí ilé ìwé ìmò òfin (law school) tí ó sì pegedé gẹ́gẹ́ bí amọ̀fin lọ́dún 1989.Aáyan rẹ̀ láti láti dẹni ara rẹ̀ kò jẹ́ kó ṣíṣe agbẹjọ́rọ̀ tí ó kàwé gboyè rẹ̀ kí ó tó bẹ̀rẹ̀ okowò. Èyí ló sì sọ ó di ènìyàn ńlá lónìí. [2]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "15 things you should know about Onyema Allen Air Peace boss". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2019-09-13. Retrieved 2019-11-25. 
  2. "15 facts about the Air Peace boss, Allen Onyema". P.M. News. 2019-09-15. Retrieved 2019-11-25.