Jump to content

Alloco

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Abọ́ tó kún fún Alloco

Alloco jẹ́ Ìpápánu ilẹ̀ adúláwọ̀ tí a máa ń jẹ pẹ̀lú ata gúngún àti alùbọ́sà ní orílẹ̀-èdè Côte d'Ivoire àti Bọ̀kínà Fasọ̀. Òun náà ni a tún máa n pè ní dòdò, èyí tó gbajúmọ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bákan náà àwọn ará Kamẹrúùnù mọ̀ọ́ sí missolè, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ará Ghánà a máa pèé ní Kelewele. Wọ́n maá n pèlòo rẹ̀ pẹ̀lú díndín ọ̀gèdẹ̀ pẹ̀lu lílo epo pupa tàbí òróró.