Anna M. Louw

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Anna M. Louw
Ọjọ́ ìbí31 December 1913
Ọjọ́ aláìsí12 June 2003
Iṣẹ́Novelist
ÈdèAfrikaans
Ọmọ orílẹ̀-èdèSouth African
Notable awards

Anna M. Louw ( A bí ni ọjọ́ kọkanlelọgbọn oṣu ọpẹ́ ọdun 1913 – sí ọjó Kejìlá oṣù okundu ọdún 2003) O jẹ́ òǹkọ̀wé ilẹ̀ South Africa. Ìlú Calvinia ni wọ́n bi sí. Bàbá rẹ̀ jẹ́ àgbẹ̀ tó máa ń sin àgùntàn lẹ́bàá ọ̀nà Calvinia ní orí oko Soetwater. Ìyá rẹ̀ sì jẹ́ olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ kan lórí ọkọ náà. O wà

ní ìbátan pẹ̀lú àwọn òǹkọ̀wé ilẹ̀ South Africa kan, tí orúkọ wọn ń jẹ́ authors NP van Wyk Louw, WEG Louw, George Louw, Peter Louw, Rona Rupert, Charles Fryer, Willem Steenkamp, Johnita le Roux, Nico Louw àti Pieter Strauss.

Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, Afrikaans, Dutch, German, French, Psychology àti Ethics ní Ifáfitì tí Stellenbosch, ó sì tún tèsíwájú láti gba oyè ẹ̀kọ́ ní Ifáfitì tí Cape Town.

Louw ṣe ìgbéyàwó ní ẹ̀ẹ̀mejì. Àwọn ọmọ tó bí fún Lewis Hurst tó jẹ́ ọkọ àkọ́kọ́ rẹ̀ ní Wendy, Nicholas àti Elizabeth. Ó sì bí àwọn ìbejì rẹ̀, ìyẹn Christina àti Editha fún ọkọ kejì rẹ̀, ìyẹn Gerhard Bassel.

Ní ọdún 1975 Anna gbà láti jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ Cape committee ti ìgbìmọ̀ atẹ̀wéjáde, àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fi òǹtẹ̀ lu ìwé ìtàn-àròsọ ti Etienne Leroux, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ ''Magersfontein, o Magersfontein!'' ní ọdún 1977, ó dẹ́kun láti jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ náà. Ìdí ni pé ó ri àìlèdá òǹtẹ̀ tí wọ́n gbé lé ìwé yẹn bí i àbùkùn.

Àwọn ìwé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Die onverdeelde uur, 1956
  • Die koms van die komeet, 1957
  • Agter my 'n Albatros, ('n reisjoenaal) 1959
  • Die voortreflike familie Smit, 1962
  • Twenty Days That Autumn; 21st March – 9th April 1960; a novel, 1963
  • Die banneling: die lyfwag, 1964
  • Oom Kolie gee raad, (drie dramas) 1965
  • Díe wat met die fluite loop, 1967
  • Die groot gryse, 1968
  • Gesëende dag, 1969
  • Kroniek van Perdepoort, 1975
  • Die derde tempel, 1978
  • Op die rug van die tier, 1981
  • Die loop van die rivier, 1986
  • Wolftyd, 1991
  • Die donker kind, 1996
  • Vos, 1999

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]