Jump to content

Anne Revere

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Anne Revere
Revere in the 1940s
Ọjọ́ìbí(1903-06-25)Oṣù Kẹfà 25, 1903
New York City, U.S.
AláìsíDecember 18, 1990(1990-12-18) (ọmọ ọdún 87)
Locust Valley, New York, U.S.
Resting placeMount Auburn Cemetery
Ẹ̀kọ́Wellesley College
American Laboratory Theatre
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1931–1977
Olólùfẹ́
Samuel Rosen
(m. 1935; died 1984)

Anne Revere (oṣù kẹfà, ọjọ́ márùn-ún-dín-lọ́gbọ̀n-lọ́gbọ̀n, ọdún 1903 sí oṣù Kejìlá ọjọ́ méjì-dín-lógún, ọdún 1990) jẹ́ òṣèré ará Ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ọmọ ẹgbẹ́ tí ń lọ síwájú nínú ìgbìmọ̀ ti Screen Actor's Guild. Ó jẹ́ gbajúmọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ lórí Broadway àti àwọn ipa rẹ̀ bí ìyá nínú àwọn eré ìwòrán lẹ́sẹsẹ tó ní iyì. Àtakò aláríwísí ti Ìgbìmọ̀ House Un-American Activities Committee, orúkọ rẹ̀ hàn ní Red Channels: The Report on Communist Influence ní Rédíò àti lórí tẹlifísàn ní odún 1950.

Revere gba Ààmì Eye Akádẹ́mì fún ipa àtìlẹ́yìn rẹ̀ nínú fíìmù National Velvet (ọdún 1945). Wọ́n sì yàn án ní ẹ̀ka kan náà fún "The Song of Bernadette" (ní ọdún 1943) àti Gentleman's Agreement (ní ọdún 1947). Ó gba àwọ́ọ̀dù Tony fún iṣẹ́ rẹ̀ nínú Lilian Hellman's play toys in the Attic ní ọdún 1960.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bíi ní Ilẹ̀ New York, Revere jẹ́ ọmọ tààrà ti akọni Ìyíká Amẹ́ríkà Paul Revere. [1] Bàbá rẹ̀, Clinton, jẹ́ alágbàátà ọjà, [2] àti pé ó dàgbà ní Upper West Side àti ní Westfield, New Jersey. Ní ọdún 1926, ó parí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Wellesley. Láìbíkítà àwọn ìgbìyànjú rẹ̀ tí kò ní àṣeyọrí láti darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ ìyàlẹ́nu ní ilé-ìwé gíga àti (ní ìbẹ̀rẹ̀) kọlẹẹjì, ó padà ṣe àṣeyọrí ní Wellesley tí ó sì kọ ẹ̀kọ́ eré ṣíṣe ìyàlẹ́nu níbẹ̀. [3] Ó tẹ̀síwájú láti f'orúkọ sílẹ̀ ní Ilé-ìwé American Laboratory School láti kọ́ eré ṣíṣe pẹ̀lú Maria Ouspenskaya àti Richard Boleslavsky.[2]

Àwọn Ìtọ́ka Sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Robertson, Patrick, The Guinness Book of Almost Everything You Didn't Need to Know About the Movies. Guinness Superlatives Ltd. 1986. ISBN 0-85112-481-X, p. 34
  2. 2.0 2.1 Peter B. Flint (December 19, 1990). "Anne Revere, 87, Actress, Dies; Was Movie Mother of Many Stars". The New York Times. https://www.nytimes.com/1990/12/19/obituaries/anne-revere-87-actress-dies-was-movie-mother-of-many-stars.html. 
  3. Coons, Robin (April 13, 1944). "Anne Revere Already Has A Job". Big Spring Daily Herald (Big Spring, Texas): p. 4. https://www.newspapers.com/clip/4670936/big_spring_daily_herald/.  open access publication - free to read