Àpíntí
Ìrísí
(Àtúnjúwe láti Apinti (Drum))
Àpíntí:
Ọkan nínú àwọn ìlù ti a nlu nibi aseyẹ ni apinti. Ẹya ìlù mẹta la papọ ti a n pen i àpíntí.
(a) Iya-ìlù: Igi ti a gbẹ ti a si da iho sìnu rẹ la fi nṣe ìya-ìlù. Oju kan ṣoṣo lo ni. Oju kan ṣoṣo yi la n fi awọ bo. Iho ìnu ìgi yi jade si isalẹ rẹ, ko si ni awọ. Iya-ìlù yi ni okun tẹẹrẹ ti a so mọ ara rẹ. Okun náà la fi ngbe e kọpa.
(b) Omele tabi Emele: Igi ni a fi n gbe oun náà, ṣùgbọ́n o kere pupọ̀ ju iya-ìlù lọ.
(d) Agogo: Irìn la fi nṣe agogo ti a n lu si apinti. Awọn alagbẹdẹ lo n see.