Arese Ugwu
Arese Ugwu (tí wón bí ní March 19, 1986) jẹ́ Olùkọ̀wé àti olùṣe filmu ọmọ orílè-èdè Nàìjíríà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ Arese sí Smart money Arese, orúkọ tí wọ́n fun nítorí filmu rẹ̀; Smart money woman àti ilé-isé rẹ̀; Smart Money Africa.[1]
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Arese sí inú ìdílé Victor àti Funke Ogiemwonyi ní ìlú Benin, ìpínlè Edo, Nàìjíríà.[2] O gba àmì ẹyẹ Bachelor's degree nínú ìmò ìsòwò nínú ilé ìwé ìsòwò Aston, àti àmì ẹyẹ master degree nínú ìmò Economics Development ní ilé ìwé college Yunifásitì ti London. Ó tún kàwé ní ilé ìwé ìsòwò ìpínlè Eko(Lagos business school) àti London business school.[3]
Isẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nínú akitiyan rẹ̀ láti ran àwọn ọmọbìnrin lọ́wọ́ nínú ètò ìsúná wọn, Arese Ugwu dá Smart Money Africa sílè.[4] Ègbé náà jé ẹgbẹ́ tí ó ran àwọn ọmọbìnrin lọ́wọ́ láti kó nípa ètò ìsúná ní ọ̀nà tí ó rọrùn. Ète Arese ni láti yí ìtàn àìní ní Afrika padà nípa kíkó àwọn ènìyàn nípa ètò ìsúná. Arese ma ń lo orisirisi ìtàn láti fi kó àwọn ọmọ Afrika nípa ètò isuna,ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà sì ni ó ma ń lọ àwọn oríṣi itakun ayélujára. Arese tún ni oludasile Smart Money Travel
Ní ọdún 2016, ó ko ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ 'The Smart Money Woman - an African girl journey to financial freedom'. Ní ọdún 2020 ṣe filmu kan lórí ìwé rẹ̀.[5]
Arese ma ń ṣẹ ètò kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Your life, Your money" lórí Guardian's TV.
Àwọn Ìtókasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "The Smart Money Woman (TV Series 2020– )". IMDb. November 30, 2020. Retrieved October 23, 2022.
- ↑ "Arese Ugwu". Trybe City Wiki. January 7, 2022. Archived from the original on October 23, 2022. Retrieved October 23, 2022.
- ↑ everipedia.org https://everipedia.org/wiki/lang_en/arese-ugwu. Retrieved October 23, 2022. Missing or empty
|title=
(help) - ↑ "Meet the Crew: Arese Ugwu". Smart Money Africa. October 21, 2021. Archived from the original on October 23, 2022. Retrieved October 23, 2022.
- ↑ Okonkwo, Chukkie (July 30, 2021). "Netflix picks up Arese Ugwu's 'The Smart Money Woman' series". eelive. Retrieved October 23, 2022.