Jump to content

Èdè Arméníà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Armenian language)
Àwòrán àkọsílẹ̀ ní èdè Armenia ti ọdún 5-6 AD
Armenian
Հայերեն Hayeren
Sísọ níArmenia, Russia, Iran, France, Lebanon, Syria, Georgia, Canada, United States
Nagorno-Karabakh (not recognized internationally)
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀6.7 million [1]
Èdè ìbátan
Indo-European
  • Armenian
Sístẹ́mù ìkọArmenian alphabet
Lílò bíi oníbiṣẹ́
Èdè oníbiṣẹ́ ní Armenia
 Nagorno-Karabakh Republic
(internationally unrecognised)
Minority language:[2]
Àdàkọ:CYP
Àkóso lọ́wọ́National Academy of Sciences of Armenia
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè
ISO 639-1hy
ISO 639-2arm (B)
hye (T)
ISO 639-3variously:
hye – Modern Armenian
xcl – Classical Armenian
axm – Middle Armenian

Èdè Arméníà jẹ́ ọ̀kan lára èdè Indo-European (Indo-Ùrópóàànù) kan ni eléyìí. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíònù méje. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ ní orílẹ̀-èdè Armenia jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (3.6 million). Wọ́n tún ń sọ ọ́ ní Turkish Armenia. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní Europe (Úróòpù), Àmẹ́ríkà (USA) àti ààrin gbungbun ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East) náà ń sọ èdè náà.

Èdè Armenia àtijọ́ (Classical Armenian tí wọ́n ń pè ní Grabar ni wọ́n kọ́kọ́ fi kọ lítíréṣọ̀ sílẹ̀ ní gbogbo àgbáyé. Wọ́n kọ ọ́ ní nǹkan bíi sẹ́ńtúrì karùn-ún lẹ́yìn ikú Jésù Kírísítì Èdè Grabar yìí ni wọ́n ń lò gẹ́gẹ́ bí èdè ẹ̀sìn fún àwọn ijọ ilẹ̀ Armenia òde òní,

Lẹ́tà álúfábẹ́ẹ̀tì méjìdínlógòjì ni wọ́n fi ń kọ èdè yìí sílẹ̀. St Mesrop ni ó ṣẹ̀dá álúfábẹ́ẹ̀tì yìí.

Oríṣìí méjì ni ẹ̀yà èdè yìí ni ayé òde òní. Ọ̀kan nit i apá Ìlà oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní, ìpínlẹ̀ Yeravan. Òun ni wọ́n ń lò ní orílẹ̀-èdè Armenia. Èkejì nit i Ìwọ̀-oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní Islanbul. Eléyìí ni wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Turkey.