Asafotu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ayẹyẹ Asafotu jẹ́ ayẹyẹ tí wọ́n ma ń ṣe àwọn ènìyàn Ga-AdangbeGhana àti Togo ma ń ṣe lọ́dọọdún. Àwọn Ada/Dangbe East náà ma ń ṣe ayẹyẹ Asafotu, wọ́n sì ma ń pè ní 'Asafotufiam'. Ayẹyẹ náà jẹ́ ayẹyẹ àwọn akíkanjú tí àwọn ènìyàn Ga-Dangbe ma ń ṣe láti ọjọ ọjọ́bọ̀ tí ó parí oṣù keje sí ìparí ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ní oṣù kẹjọ. Wọ́n fi ń ṣe ajoyọ̀ àwọn ìṣègùn wọn àwọn bàbà ńlá wọn lójú ogun, àti yẹ́ àwọn tó kú lójú ogun sí. Bí wọ́n bá fẹ́ ṣe ayẹyẹ yìí, àwọn ènìyàn a múra nínú aṣọ ogun, wọ́n á sì jà ìjà ọ̀rẹ́dọ́rẹ̀. Ìgbà yí náà ni wọ́n ma ń fi ojú àwọn ọ̀dọ́ kọ̀kan mọ ogun.

Ayẹyẹ yìí náà ni wọ́n ma ń bẹ̀rẹ̀ kí wọ́n tó ṣe àwọn ayẹyẹ miran tí wọ́n ma ń ṣe ní àárín ìgbà náà.