Jump to content

Asmaa Abulyazeid

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Asmaa Abulyazeid
Orúkọ àbísọأسماء أبو اليزيد
Ọjọ́ìbíCairo,  Egypt
Orílẹ̀-èdèEgyptian
Ìgbà iṣẹ́2011 - titi di asikoyi

Asma Abulyazeid (èdè lárúbáwá: أسماء أبو اليزيد‎) jẹ́ akorin àti òṣèré tí ó wá

á laìlúiu Egypt ,[1] ó kẹ́kọ̀ọ́ ìtanràn àwòrán ode kó pa nínú eré orí ìtàgé ní Tíátà Hanager ó sì díje fún àmì ẹ̀yẹ Sheikh Sultan Al Qasimi fún eré ìtàgé tí ó dára jùlọ ní ọdún 2016.

Ó fa àkíyèsí sí ara rẹ̀ nítorí ipa tí ó kó nínú jara tẹlifísàn gẹ́gẹ́ bí "Tọka" nínú "This evening" ní ọdún 2016, ó kópa nínú fíìmù oríṣi, ó tún wà pẹ̀lú ẹgbẹ́ orin "Bahjja" ó sì ti ṣe àwọn aṣàmúlò ọ̀rọ̀ orísirísi.[2][3]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Cairo, ní Egypt ni wọ́n bí Asmaa sí. Bàbá rẹ̀ wá láti ìlú Cairo, ìyá rẹ̀ sì wá láti Sharqia. Asmaa ti fẹ́ràn kí ó ma ṣe eré láti ìgbà ọmọdé rẹ̀ sùgbọ́n kò rí eré ṣe nítorí pé kò sí eré ìtàgé ṣíṣe ní ilé-ẹ̀kọ́ ti ó lọ, ṣùgbọ́n lẹ́hìn tí ó dé ilé-ẹ̀kọ́ gíga ó rí ẹgbẹ́ tíátà, ó sì darapọ̀ mọ́ wọn nípasẹ̀ ẹgbẹ́ Tíátà Atelier.

Ní ìgbà tí ó darapọ̀ mọ́"Tíátà Atelier" ó kọ́ iṣẹ́ lọ́wọ́ Olùdárí Shadi Daly ó sì ṣe oríṣiríṣi ìdíje, èyí tí ó ṣe ní gbẹ̀yìn ni "Magic Mix of Happiness" tí ó díje nínú Arab Theater Festival fún àmì ẹ̀yẹ "Sheikh Sultan Al Qasimi" fún ẹgbẹ́ eré ìtàgé Arab ní ọdún 2016.

Eré ìtàgé tí ó kọ́kọ́ ṣe ni èyí tí ó ṣe ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ní abẹ́ àkòrí "Life is Beautiful In Fine Arts", lẹ́hìn ìgbà náà, ó kópa nínú eré orí ìtàgé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ "Antar Stable" ti Bayoumi Fouad ṣe olùdárí rẹ̀.



Ní ọdún 2014, ó kópa nínú jara tẹlifísàn "I Loved" èyí tí Maryam Al Ahmadi ṣùgbọ́n ipa kékeré ni ó kó níbẹ̀.

A yan kalẹ̀ nípasẹ̀ olùdáṣiṣẹ́ Ahmed Medhat Sadeq, tí ó jẹ́ olùdárí Tamer Mohsen, láti ṣe ipa ti "Toka" àti lẹ́hìn tí ó ja gèrè ní àwọn ìdánwò, èyítí ó yọrí sí ipa tí ó gbà. [4]

Ẹ̀rù máa ń bàá láti dúró sí iwájú kámẹ́rà, nítorí kò ní ìgboyà láti kó ipa rẹ̀ nínú eré náà. Ó fẹ́ràn ipa Taqa tí ó kó, nítorí ipa náà jẹ́ titi àláàánú, ṣùgbọ́n ó ní agbára.[5]

Abulyazeid ṣe olùdárí "Melodrama" ní ọdún 2013, ó tún kópa nínú "Habhan", ó tún ṣe olùdárí Shadi Daly nínú eré "Dream Plastic" tí ó kópa nínú. Ó tún ṣe "Made in China" àti The Revolution of the Dead.[6][7][8]

Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀ Àti Àwọn Fíìmù Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
-
  • the Passage (2019)[9]
  • 122 (2019)
  • the Bullet (2018)
  • Al Kowayseen (2018)
  • Talk about the eyebrow (2018)
  • One moment, please (2011)
  • Zodiac (2019)
  • Hogan (2019)
  • Eugenie Nights (2018)
  • This evening (2017)
  • I'm Shahira ... I'm the traitor (2017)
  • I'm in love (2014)
  • Miss Farah

Àwọn Eré Ìtàgé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Melodrama (2013)
  • made in China
  • Revolution of the dead

Àwọn Àmì Ẹ̀yẹ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Òṣèré tí ó dára jùlọ ní "Elia Short Film Festival " ní ọdún 2019.[10]

Àwọn Ìtọ́ka Sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. https://www.elcinema.com/en/person/2084160
  2. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2019-10-11. Retrieved 2020-10-12. 
  3. https://www.albawaba.com/slideshow/asma-abulyazeid-aphrodite-photoshoot-year-1209246
  4. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2019-10-11. Retrieved 2020-10-12. 
  5. https://scoopempire.com/is-it-possible-for-asma-abulyazeid-to-take-a-photo-and-not-look-good/
  6. Elfeqy, Salma (2018-05-28). "The Amazing Galila or Should We Say Asmaa Abulyazeid". Identity Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-10-11. 
  7. القاهرة – "الحياة" (2019-07-21). "أسماء أبو اليزيد تخوض بطولة "شكة دبوس"". Hayat (in Arabic). Archived from the original on 2019-10-11. Retrieved 2019-10-11. 
  8. "أسماء أبو اليزيد: أنا ممثلة.. والرقص والغناء "كماليات" - بوابة الشروق". www.shorouknews.com (in Èdè Árábìkì). Retrieved 2019-10-11. 
  9. https://egyptindependent.com/egyptian-movie-al-mamr-to-air-on-tv-channels-on-occasion-of-october-war/
  10. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2019-10-11. Retrieved 2020-10-12. 

Awọn ọna asopọ ita

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]