Ata rodo
Ata rodo (Látìnì: Capsicum chinense) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ewébẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì nínú ohun èlò ìsebẹ̀ jákè-jádò orílẹ̀ àgbáyé. Oríṣiríṣi ata rodo ni ó wà ní wà pàá pàá jùlọ ní àwọn ọjà ilẹ̀ Nàìjíríà. [1]
Ànfàní ata rodo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ata rodo ni ó ní àwọn èròjà aṣara lóore Fítàmì bii : (C, A, B6 àti folate), ó tún ní èròjà (lycopeine àti capsaicin). Àwọn èròjà yí ni wọ́n wúlò fún mímu ìrora kúrò fúni, tí ó sì ma ń jẹ́ kí kẹ̀lẹ̀bẹ̀ ó dúrò ní ihò tàbí káà imú àti káà ọ̀fun. Ata rodo tun ń ṣèkúnlápá fún àwọn ọmọ ogun ara kí wọ́n lè lagbara si. Ti ta ata rodo ni ó tun ma ń jẹ́ kí ẹ̀fọ́rí oun kàtá ó fi àgbàọ́ ara sílẹ̀, kódà tó fi mọ́ àìsàn arọmọléegun, àti àwọn àìsàn mìíràn. [2]
Bí wọ́n ṣe ń jata rodo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ko fi bẹ́ẹ̀ sí ónjẹ kan tí a lè sè láì sí ata rodo.[3]A lè lọ̀ọ́ mọ́ àwọn èròjà ọbẹ̀ tókù, a lè lọ̀ó lásán kí á fi ṣe kurumbúsú, a lè jẹ́ lásán a sì lè fi se ohun k lohun tó bá wùwá. [4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Onyeakagbu, Adaobi (2019-09-06). "The different types of peppers we have in Nigeria". Pulse Nigeria. Retrieved 2020-01-20.
- ↑ "Meaning of Ata Rodo". Nigerian Dictionary. Retrieved 2020-01-20.
- ↑ "Chief S.L Edu Research Grant". Nigerian Conservation Foundation. Archived from the original on 2019-12-29. Retrieved 2020-01-20.
- ↑ Okoye, Ngozi (2019-02-20). "Ata Rodo: The Spicy Chili with many Benefits". Pharmanewsonline. Retrieved 2020-01-20.