Jump to content

Atama soup

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Atama soup
Alternative namesAbak Atama
TypeSoup
Region or stateCross River State
Associated national cuisineNigeria
Main ingredientsVegetable, palm nut, atama leaf
Àdàkọ:Wikibooks-inline 

Ọbẹ̀ Atama tàbí Amme-Eddi náà ni a tún ń pè ní Ọbẹ̀ Banga ní píjìnnì Gẹ̀ẹ́sì (Gẹ̀ẹ́sì Nàìjíríà) . Ó jẹ́ ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ èso ọ̀pẹ tí ó ṣẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn Efik people of Cross River state, Urhobo and Isoko people of Delta State ní Gúsù Gúsù Nigeria.[1][2][3] Ó jẹ́ oúnjẹ tó gbajúgbajà láàárín àwọn èèyàn Delta, Cross River àti Akwa Ibom State ti Nàìjíríà. Àwọn èèyàn Urhobo ti ìpínlẹ̀ Delta máa ń pè é ní Amme-edi tàbí ọbẹ̀ Banga (bang jíjẹ́ orúkọ ìperí ti Nàìjíríà - Gẹ̀ẹ́sì)

Ọbẹ̀ náà di ṣíṣe láti ara omi èso ọ̀pẹ tí a rí láti ara èso ọ̀pẹ; omi ọ̀pẹ tí a fà yìí ni ohun èlò pàtàkì fún ọbẹ̀ ọbẹ̀ náà. Atama tàbí ọbẹ̀ Amme-edi(Banga) ki ó sì dúdú ní àwọ̀. Ó sábàá máa ń di ṣíṣe pẹ̀lú àṣàyàn ohun asaralóooore bí ẹran tútù tàbí ẹran gbígbẹ (pàápàá jù lọ ẹran ìgbẹ́), ẹja gbígbẹ, ẹja tútù àti nígbà mìíràn edé(gbígbẹ tàbí tútù), fífi ewéko asaralóooore fún gbígbé adùn rẹ̀ yọ.[1][2][3]

Àwọn ohun èlò: àwọn ohun èlò tó ṣe pàtàkì ni omi ọ̀pẹ láti ara èso ọ̀pẹ, iyọ̀ àti ata àti ohun èlò tí a tún lè fi kún un ni èyí tí ó bá níse pẹ̀lú ìfẹ́ràn ẹni tí ó ń sè é ni àlùbọ́sà, iyọ̀, ata (orísìírísìí ata tí ó níse pẹ̀lú ìnífẹ̀ẹ̀sí) àti orísìírísìí ohun amọ́bẹ̀dùn ni ó lè di fífi sí i dídá lórí ìnífẹ̀ẹ́sí olùsè tàbí adùn. Ọbẹ̀ yìí lè di ṣíṣè sí orísìírísìí adùn dídá lórí ìfẹ́ràn olùsè. Gbogbo ohun èlò tí a bá fi sí i ni ó lè yí adùn oúnjẹ náà padà.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 "Top Exotic Nigerian Dishes You Must Taste This Week" (in en-US). Nigerian Bulletin - Nigeria News Updates. https://www.nigerianbulletin.com/threads/top-exotic-nigerian-dishes-you-must-taste-this-week.188054/. 
  2. 2.0 2.1 "Ikot Ekpene: The Raffia City |". leadership.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2017-02-21. Retrieved 2017-02-21.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. 3.0 3.1 omotolani (2021-05-27). "How to make Akwa Ibom's Abak Atama soup". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-06-27.