Awùjalẹ̀ Tí Ìjẹ̀bú
Ìrísí
Awùjalẹ̀ jẹ́ orúkọ oyè Ọba ti ó nílẹ̀ Ìjẹ̀bú. Ìjẹ̀bú-Òde ni ààfin Ọba Awùjalẹ̀ tèdó sí. Ọba Síkírù Káyọ̀dé Adétọ̀nà Ọ̀gbágbá II ni Awùjalẹ̀ Ìlú Ìjẹ̀bú tí ó wà lórí ìtẹ́ lọ́wọ́́lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí Awùjalẹ̀ tí ilẹ̀ Ìjẹ̀bú pátápátá.[1] Ìdílé ọlọ́ba Aníkìláyà ló ti wá. [2]
Àwọn ìdílé Ọlọ́ba tí wọ́n máa ń jẹ́ Awùjalẹ̀ nílẹ̀ Ìjẹ̀bú.
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gẹ́gẹ́ bí òfin àti ìlànà ìbílẹ̀ tí là á kalẹ̀ lọ́dún 1959, àwọn ìdílé mẹ́rin péré ló ní àṣẹ láti jẹ òye ọba Awùjalẹ̀ tí ilẹ̀ Ìjẹ̀bú. Àwọn ìdílé ọlọ́ba náà ni;
- 1. Ìdílé ọlọ́ba Gbélégbúwà
- 2. Ìdílé ọlọ́ba Aníkìláyà
- 3. Ìdílé ọlọ́ba Fúsẹ̀ngbuwà
- 4. Ìdílé ọlọ́ba ìdípọ̀tẹ̀ [3]
Àtòjọ àwọn Awùjalẹ̀ tí wọ́n ti jẹ rí títí di òní
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ỌBA OLÚ-ÌWÀ
- ỌBA ỌṢÌN
- OBAŃTA – 1430
- ỌBA GÚRÚ – 1445
- ỌBA MÚNIGBÚWÀ – 1455
- OBAŃTA II – 1460
- ỌBA LỌ́JAÀ – 1470
- ỌBA LỌ́FIN – 1482
- ỌBA APASA – 1496
- ỌBA GANJU – 1508
- ỌBA TEWOGBOYE – 1516
- OBA RÚWÀMÚDÀ – 1520
- ỌBA OFINRAN – 1532
- ỌBA LÁPẸ́NGBÚÀ – 1537
- ỌBA ÓTUTÙBÍỌSÙN – 1537
- ỌBA MOKO IDOWA AJÚWÀKALẸ̀ – 1540
- ỌBA ÀDÌSÁ – 1552
- ỌBA JẸ́WỌ́ – 1561
- ỌBA ẸLẸ́WÙ ÌLẸ̀KẸ̀ – 1576
- ỌBA OLÚMISỌ́DÀN ẸLẸ́WÙ ÌLẸ̀KẸ̀ – 1590
- ỌBA MASE – 1620
- ỌBA OLÓTÙṢẸ̀ṢỌ́ – 1625
- ỌBA MOLÀ – 1635
- ỌBA ÀJÀNÀ – 1642
- ỌBA ORE TÀBÍ GADÉGÚN – 1644 (The first female Awujale)
- ỌBA GÚNWÀJÁ – 1655
- ỌBA JADIARA TÀBÍ OLÓWÓJOYÈMÉJÌ – 1660
- ỌBA ṢAPOKUN – 1675
- ỌBA FÁLÓKUN – 1687
- ỌBA MẸ́KÙN – 1692
- ỌBA GBÓDOGI – 1702
- ỌBA OJIGI AMÓYÈGẸ̀ṢỌ́ – 1710
- ỌBA LIYEWE ARỌ̀JÒFÁYÉ – 1730
- ỌBA MOYEGE ỌLỌ́PẸ́ – 1730
- ỌBA Ọ̀JỌRÁ – 1735
- ỌBA FẸ̀SỌ̀JOYÈ – 1745
- ỌBA ORE JẸ́JEẸ́ – 1749 (ỌBABÌNRIN)
- ỌBA SÁPẸ́NNÚWÀ RUBA KOYE – 1750
- ỌBA ORÓDÚDU JOYÈ – 1755
- ỌBA TẸWỌ́GBÙWÀ I – 1758
- ỌBA GBÉLÉGBÚWÀ I – 1760
- ỌBA FÙSẸ́NGBÚWÀ – 1790
- ỌBA SẸ̀TẸ̀JOYÈ – 1820
- ỌBA ANÍKÌLÁYÀ FIGBÀJOYÈ AGBÓÒGÙNSÁ – 1821
- ỌBA AFÌDÍPỌ̀TẸ̀MỌ́LẸ̀ ADÉMÚYÈWÒ – 1850
- ỌBA ATÚNWÀṢE ADÉSÌŃBỌ̀ – 1886
- ỌBA Ọ̀GBÁGBÁ AGBỌ́TẸ̀WỌLẸ̀ I – 1895
- ỌBA FÚSÌGBOYÈ ADÉỌ̀NÀ – 1906
- ỌBA FẸSỌ̀GBADÉ ADÉMÓLÚ – 1916 (Dethroned)
- ỌBA ADÉKỌ̀YÀ ELÉRÚJÀ – 1916
- ỌBA ADÉMÓLÚ FẸSỌ̀GBADÉ – 1917 (Enthroned again)
- ỌBA ADÉNÚGÀ AFỌLÁGBADÉ – 1925
- ỌBA ÒGÚNNÁÌKÈ FIBIWOJÀ – 1929
- ỌBA DANIEL ADEÉSÀNYÀ GBÉLÉGBÚWÀ II – 1933-1959
- ỌBA Dr. SÍKÍRÙ OLÚWAKÁYỌ̀DÉ ADÉTỌ̀NÀ, Ọ̀GBÁGBÁ AGBỌ́TẸ̀WỌLẸ̀ II – 1960–present
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Omonhinmin, Gabriel (2017-01-15). "How I became The Awujale Of Ijebuland - The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Archived from the original on 2020-10-01. Retrieved 2019-12-01.
- ↑ "THE EARLY HISTORY OF IJEBU on JSTOR". JSTOR. Retrieved 2019-12-01.
- ↑ "Awujale - African ruler". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2019-12-01.