Àwọn Ẹ̀ka-èdè Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Awon Eka-ede Yoruba)
Jump to navigation Jump to search

Awon Eka-ede Yoruba

Tèmítọ́pẹ́ Olúmúyìwá (1994), Àwọn Ẹ̀ka-Èdè Yorùbá 1Akúrẹ́: Ìbàdàn, Montem Paperbacks. ISBN 978-3297-3-3. Ojú-ìwé = 58.

Ọ̀RỌ̀-ÌṢÁÁJÚ

Èdè Yorùbá àjùmọ̀lò ni ó pa gbogbo ẹ̀yà Yorùbá pọ. Ṣùgbọ́n ẹ̀ka-èdè tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ń sọ yàtọ̀ láti ilú kan sí èkeji. Ìyàtọ́ yìí le hàn ketekete tàbí kí ó farasin. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìwádii ni àwọn onímọ̀-èdè ti ṣe lórí àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá wọ̀nyí. Púpọ̀ nínú àbájáde ìwádìí wọn ni kò sí ní àrọ́wọ́tó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá. Níbi ti irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ bá jàjà bọ́ sí ọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́, èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọn fi ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ yóò mú ìfàsẹ́yìn bá iṣẹ́ wọn nítorí wọ́n ní láti kọ́kọ́ túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Yorùbá kí wọn tó le ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹ̀ka-èdè bẹ́ẹ̀ finnífínní.

Títí di bi mo ṣe ń sọ yìí, kò sí ìwé kankan nípa àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá lórí àtẹ. Ohun àsọmórọ̀ ni àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá jẹ́ nínú àwọn ìwé gírámà Yorùbá tí ó wà lórí àtẹ. Púpọ̀ àbájáde ìwádìí àwọn onímọ̀-èdè tí ó wà ní àrọ́wọ́tó ni ó dálé ìpín-sí-ìsọ̀rí àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Ohun tí ó jẹ àwọn aṣèwádìí mìíràn lógún ni ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ẹ̀ka-èdè ìlú kan tí wọ́n yàn láàyò. Ṣùgbọ́n nínú ìwé yìí mo ṣe àyẹ̀wò púpọ̀ àwọn ẹ̀ka-ède Yorùbá léte àti pe àkíyèsí sí fonẹ́tíìkì àti fonọ́lọ́jì ẹ̀ka-èdè wọ̀nyí. Ìwé yìí yóò wúlò púpọ̀ fún àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti wọ́n ń kọ́ nípa àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Yóò si ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọnolùkọ̀ọ́ pẹ̀lú. Bákan náà ni ìwé yìío yóò jẹ́ ìpèníjà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ onímọ̀-èdè Yorùbá láti túbọ̀ kọ ibi ara sí àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ wọ̀nyí tí wọ́n tẹ̀ mí nífá ẹ̀ka-èdè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò fojú rí púpọ̀ nínú wọn rí. Àwọn ni Ọ̀mọ̀wé Jíbọ́lá Abíọ́dún, Ọ̀gọ̀gbọ́n Ọládélé Awóbùlúyì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Oyèlárán, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Bámgbóṣé, Ọ̀mọ̀wé Adétùgbọ́, Ọ̀mọ̀wé Akínkúgbé àti Ọ̀mọ̀wé Olúrẹ̀mi Bámiṣilẹ̀.

Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀mọ̀wé Olúyẹ́misí Adébọ̀wálé àti Ọ̀mọ̀wé Jíbọ́lá Abíọ́dún tí wọ́n fu àkókò sílẹ̀ láti bá mi ka ìwé yìí pẹ̀lú àtúnṣe tí ó yẹ nígbà tí mo fí ọwọ́ kọ ọ́ tán. ìmọ̀ràn wọn ni àwọn ohun tí ó dára nínú ìwé yìí, èmi ni mo ni gbogbo àléébù ibẹ́. Mo gbé òṣùbà ọpẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí fún ìrànlọ́wọ́ wọn. Àwọn ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Bísí Ògúnṣíná, Arábìnrin Comfort Ògúnmọ́lá, Arábìnrin Àrìnpé Adéjùmọ̀, Olóyè Olúfẹ́mi Afọlábí, Arábìnrin Ọláyinká Afọlábí, Lékan Agboọlá, Ọjádélé Àjàyí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí mo kọ́ ní àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá láàárín ọdún 1991-1994 àti àwọn aláṣẹ ilé-iṣẹ́ aṣèwétà Montem Paperbacks. Ní ìparí, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Arábìnrin Tèmítọ́pẹ́ Olúmúyìwá, ìyàwó mi àpé àti Mòńjọlá, ọmọ mi, fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn lásìkò ti mo kọ́ ìwé yìí.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, bi Ọlọ́run kò bá kọ́ ilé náà, àwọn ti ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán. Ìdí nìyí tí mo fi yíkàá níwájú Ọlọ́run ayérayé.